Kòkòrò Amoeba tó ń jẹ ọpọlọ ṣekúpa olùgbé Florida

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olugbe Florida kan ti ri oku he lẹyin to lugbadi arun kokoro Amoeba kan to n jẹ ọpọlọ.
Awọn onimọ nipa ilera ni Chalotte County ni guusu ila oorun Florida ni oloogbe na lugbadi aarun naa nitori o fi omi fọ imu.
Naegleria fowleri n se akoba fun ọpọlọ lati inu imu. Awọn osisẹ ilera ni mumu oni ko le fa kokoro naa.
Gẹgẹ bi Ajẹ to n ri si sise idabobo fun aarun ni ijamba to wa ninui lulugbadi Aarun yii buru pupọ.
Lọjọ kẹtalalogun oṣu keji, ẹka ilera Florida ni o ṣeeṣe ko jẹ pe oloogbe lugbadi aarun ni bi to ti n fi omi fọ imu rẹ pẹlu omi ẹrọ.
Lọjọbọ, Agbẹnusọ ẹka ilera Florida fidi rẹ mulẹ pe olugbe naa jade laye.
Awọn osisẹ kaakiri ẹka ijọba ti bẹrẹ iwadi lori aarun se waye ati ọna miiran to fi n waye, agbẹnusọ Jae Williams salaye.
O fikun pe awọn osisẹ ilera n sisẹ pọ pẹlu awọn ẹka ilera abẹle lati se iwadi nipa kokoro yii ati ọna lati dẹkun rẹ.
Kokoro Amoeba ni iwadi ni o ma u gbe ni omi to ba lọwẹrẹ ni adagun omi.
O ma fa ọpọlọpọ aisan lagbo ara eeyan to ba wọle lati inu imu sugbọn ko ni ipalara to ba ti ẹnu wọle nitori oru iku yoo sekupa.
Awọn eeyan to ba lugbadi aarun yii ni an pe ni Meningoencephalitis.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn apẹẹrẹ ti eeyan yo ma ri nipa kokoro yii ni ori fifọ, iba, ebi, aile duro daada ati awọn nnkan mii.
Gẹgẹ CDC ṣe sọ, eeyan mẹta lorilẹede Amẹrika ni o n lugbadi aarun lọdọdun, ti wọn si ku ni ọna ti ko da.
Lati ọdun 1962 si ọdun 2021, eeyan mẹrin pere lo ye ninu eeyan mẹrinlelaadọjọ to lugbadi aarun naa lorilẹede Amẹrika.
Ijọba ati ẹka ilera ti wa gba awọn araalu ni imọran lati fi omi si mu wọn lasiko ti wọn ba ninui omi adagun.












