Ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní Gabon dùn mọ́ mi nínú- Fayose

Aworan Gomina Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ni inu oun dun pupọ pẹlu bi iditẹgbajọba ṣe waye lorilẹede Gabon.

Fayose jẹ ki eyi di mimọ lasiko to n ba ileeṣẹ tẹlifisan Channels sọrọ lọsẹ to kọja.

O ni oun ko se atilẹyin fun pe ki ologun gba ijọba sugbọn oun o gbagbọ pe bi nnkan ṣe n lọ ni Ilẹ Afrika lo fa nnkan to waye yii.

“Inu mi dunb pẹlu nnkan to waye ni Gabon. N ko nifẹ si pe ki ologun da si oṣelu.”

Lọjọru ọsẹ to kọja ni awọn ologun ni orilẹede Gabon gba ijọba lọwọ Aarẹ Ali Bongo, ẹni to ti jẹ Aarẹ fun ọdun mọkanla, lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo to waye lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun 2023.

Fayose jẹ ko di mimọ pe irufẹ iditẹgbajọba yii ko le waye lorilẹede Naijiria pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lọwọ orilẹede naa.

“Ẹ ranti pe, bayii ni Naijiria, a mọ pe lẹyin ọdun mẹrin, eto idibo yoo waye. Naijria ti kuro ni ẹgbẹ oṣelu kan si ọpọlọpọ ẹgbẹ oṣelu.

“Sugbọn ni orilẹede ni bi ọkunrin kan ti lo ogbọn ọdun, ogun ọdun, ogoji ọdun, wọn gbọdọ le kuro ni ibẹ. Nitori eyi ni mo fi ni o yatọ si orilẹede Naijira.

“O kole lo ju ọdun to yẹ ko lo lọ , ẹ ma fi we orilẹede Naijiria . N ko ni nnkan o le sẹlẹ.”