Àwọn òbí banújẹ́ báwọn ọmọ tó ti kú ṣe ń sọ̀rọ̀ bíi alàyè lórí TikTok láti sọ ohun tó pa wọ́n

Oríṣun àwòrán, TikTok
- Author, By Ed Main
- Role, BBC Trending
Awọn obi kan ti wọn ti padanu ọmọ wọn ti fi aidunu wọn lede lori bi awọn eeyan ṣe n lo aworan awọn ọmọ kekere ti wọn ṣekupa lati maa sọrọ bii alaye loju opo TikTok.
Awọn fidio naa ṣafihan awọn oloogbe ọhun, ti wọn n sọrọ nipa bi iku wọn ṣe waye, lai gba aṣẹ lọwọ awọn mọlebi oloogbe.
Lati inu oṣu Kẹrin ọdun yii ni awọn fidio ti wọn lo ẹrọ AI lati pilẹ rẹ ti n gbajumọ loju opo TikTok, bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ oju opo naa ti fofin de awọn fidio ọmọde.
Amọ ṣa, iwadii BBC fi han pe o ṣeeṣe ki awọn kan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ma mọ kulẹkulẹ ofin to so ileeṣẹ naa ro.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ TikTok kan sọ fun BBC pe lẹyin oṣu mẹrin ti wọn fofin de lilo aworan ọmọde pẹlu AI, ileeṣẹ ọhun ko bun oun gbọ.

Oríṣun àwòrán, UK Parliament
"Nnkan ibanujẹ ni ki obi maa wo fidio ọmọ rẹ to ti ku, ko maa sọrọ nipa bi wọn ṣe pa a"
Awọn ẹbi kan to n ṣọfọ ọmọ wọn to di oloogbe ti sọrọ soke nipa fidio AI lori ọmọ wọn to wa lori ayelujara.
Baroness Beeban Kidron, to jẹ ọkan lara awọn aṣofin ilẹ Gẹẹsi sọ pe nnkan ibanujẹ ni ki obi maa wo fidio ọmọ rẹ to ti ku ko maa sọrọ nipa bi wọn ṣe pa a.
O ni “Ti o ba jẹ ọkan lara awọn mọlẹbi tabi obi irufẹ ọmọ bẹẹ, ibanujẹ nla gbaa ni awọn fidio ọhun yoo jẹ fun ọ.”
“O jẹ ohun to buru jai”
Ko pẹ ti awọn fidio naa bẹrẹ si n jade ti awọn mọlẹbi awọn oloogbe ọhun bẹrẹ si n fọhun.
Lara irufẹ obi bẹẹ ni obinrin ọmọ orilẹ-ede Canada kan, Amélie Lemieux.

Inu oṣu Keje, ọdun 2020 ni ọkọ Amélie Lemieux ṣekupa ọmọ wọn meji Romy ati Norah, ko to gbẹmi ara rẹ.
Iyalẹnu nla lo jẹ fun arabinrin Lemieux nigba to ri fidio AI ti awọn oloogbe naa ti n sọrọ nipa iku wọn loju opo TikTok.
Lemieux ni “o ba inu mi jẹ to bẹẹ ti mi o le ṣalaye.”
“Fidio ọhun da omi tutu si mi lọkan to bẹẹ ti mi o le wo o de ipari, bẹẹ naa ni aburo mi ọkunrin to wa pẹlu mi ko le wo tan.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ominu n kọ lori pe awọn mọlẹbi oun mii to jẹ ọmọde naa le ri awọn fidio ọhun lori TikTok.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn mọlẹbi ti ọrọ naa kan lo fi to ileeṣẹ TikTok leti, awọn fidio naa ṣi wa lori ayelujara.
Imọ ẹrọ tuntun
Ẹrọ AI ti mu ko rọrun lati maa gbe awọn fidio jade pẹlu irọrun laye ode oni.
O ti ṣeeṣe bayii ki eeyan po fidio pọ pẹlu aworan lasan laarin iṣẹju perete.
Lootọ ni pe lara awọn aworan naa ko jọ ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si, amọ pupọ ninu rẹ lo jọ eeyan nitori aworan ẹni naa ti wọn lo.
Pupọ ninu awọn to n ṣe irufẹ fidio ọhun lo n gbe ara wọn pamọ, amọ BBC ṣawari ọkan lara wọn, ti orukọ rẹ n jẹ Ritul.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Lara awọn fidio awọn ọmọde naa ni wọn ti ṣe ẹda rẹ ni oniruru ede bii Portuguese, Spanish, French, German, Italian ati Polish.
Fun apẹrẹ, oniruru fidio bii 170 ni BBC ṣawari nipa James Bulger, ọmọ ọdun meji ti awọn ọmọde mii ṣekupa ni Merseyside, ni England, lọdun 1993.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ohun ti TikTok sọ
Lẹyin ti iya James, Denise Fergus sọ fun ileeṣẹ iroyin kan loṣu Keje pe awọn fidio ọmọ oun mu ibanujẹ de ba oun, TikTok sọrọ soke ninu atẹjade kan.
TikTok ni “A ko faye gba irufẹ awọn fidio bayii loju opo wa.”
“Gbogbo igba ni a si maa n fa irufẹ awọn fidio bẹẹ yọ ti a ba ti ṣawari wọn.”
Wayi o, TikTok ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko faramọ awọn fidio bẹẹ, yoo ṣoro fun awọn lati ṣawari gbogbo rẹ.











