Ẹbí kan fọnmú lórí ìyànsípò Soun Ogbomoso tuntun, wọ́n ní ẹni tí ìlú mọ̀ làwọn ń fẹ́

Oríṣun àwòrán, Prince Afolabi Olaoye Ghandi/Facebook
Awọn ọmọ idile oye kan ti yari lori iyansipo Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun, wọn ni ẹni ti ilu damọ ni awọn n fẹ
O ti n fi ara jọ wi pe ọrọ fẹ bẹyin yọ lori ikede ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe wi pe Ọmọọba Afolabi Ghandi Olaoye ni Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun.
Awọn olori ẹbi ti Ṣọun tuntun ti jade wa lo pe ipade oniroyin lati fi aidun inu wọn han lori ẹni ti ijọba yan sipo, gẹgẹ bi wọn ṣe n ke si Gomina ipinlẹ Ọyọ lati yi ipinnu rẹ pada.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ nilu Ogbomọṣọ, ẹni ti o jẹ olori ẹbi awọn Baalẹ nilu Ogbomoso, Alhaji Garuba Tẹwọgbọla ṣe alaye wi pe bo tilẹ jẹ wi pe ojulowo ọmọ Laoye ni Ọmọọba Afọlabi ti ijọba kede gẹgẹ bii Ṣọun tuntun, o ni ọpọlọpọ eeyan ni ko daa mọ.
Alhaji Tẹwọgbọla ṣe alaye siwaju wi pe ọrọ lori ẹni ti yoo jẹ oye Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ gan ṣi wa nile ẹjọ ki ijọba to ṣe ikede.

Oríṣun àwòrán, Others
"Ghandi yii naa nigba to de, a beere pe nibo ni ile yin, o ni ile kan lẹgbẹ odo ọlọkọ ni, ko mọ orukọ ile wọn."
Olori awọn Baalẹ naa tun fi ẹsun kan wi pe Ọmọọba Afọlabi ko mọ agboole wọn nilu Ogbomọṣọ.
O ni baba Afọlabi naa ti du oye ri, ṣugbọn ko ja mọọ lọwọ nitori ko mọ agboole wọn.
O ni, "Baba rẹ gan ti du oye ri ti ko rii jẹ. Wọn beere lọwọ baba rẹ pe baba to bi baba rẹ, nibo ni Kaa wọn? Wọn ko rii yanju.
Ghandi yii naa nigba to de, a beere pe nibo ni ile yin, o ni ile kan lẹgbẹ odo ọlọkọ ni, ko mọ orukọ ile wọn."
Ẹni ti o jẹ alukoro fun mọlebi Laoye, Ọmọọba Tajudeen Olapade naa kin ọrọ olori ẹbi lẹyin pẹlu alaye wi pe awọn Afọbajẹ kuna ninu ojuṣe wọn. O ni iyalẹnu lo jẹ bi awọn ṣe dede gbọ ikede wi pe Ọmọọba Afọlabi Ghandi Laoye ni Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun.

Oríṣun àwòrán, Others
Soun Ogbomoso tuntun ti fipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Pasitọ lati gun ori itẹ ọba
Ariwo ti mọlẹbi naa mu bọ ẹnu ni wi pe ki ijọba ipinlẹ Ọyọ yii ipinnu ati ikede naa pada.
Lati igba ti Ṣọun Ogbomọṣọ ana, Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III ti waja ni ijijadu ti bẹrẹ lori idile ti o kan lati fa Ṣọun tuntun kalẹ.
Awuyewuye ti o rọ mọ ipo ọba Ogbomọṣọ yii lo si mu ki ọrọ oye de ile ẹjọ.
Awọn eeyan ilu gan fi idi rẹ mulẹ wi pe ọrọ to wa ni ile ẹjọ ko tii fi bẹẹ ni iyanju ki ijọba ipinlẹ Ọyọ to kede Ọmọọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye gẹgẹ bii Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun.
Ọmọọba Afọlabi ti o jẹ Oluṣọ Aguntan fun ẹka ijọ irapada (RCCG, Jesus House, Washington DC) lorilẹede Amẹrika ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii adari ijọ naa ọjọ Aiku, ni igbaradi fun oye tuntun to n bọ wa jẹ ni Naijiria gẹgẹ bii Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ.
Awọn ẹlẹsin musulumi ki Afolabi Ghandi Olaoye ku oriire iyansipo rẹ gẹgẹ bi Soun Ogbomoso tuntun
Yoruba bọ, wọn ni ẹkọ ẹlẹkọ ni ẹgba ẹlẹgba.
Nibi ti awọn mọlẹbi Olaoye kan ti n fọnmu wi pe awọn o fẹ ẹ lori oye gẹgẹ bi Soun tuntun lawọn ẹgbẹ musulumi ilu Ogbomoso ti n ki i ku oriire iyansipo rẹ.
Imaamu ilu Ogbomoso, Teliat Yunus Olushina Ayilara Keji, ni orukọ gbogbo musulumi ilu Ogbomoso ranṣẹ ikini ku oriire yii si Olaoye ninu atẹjade kan to fi sita.
Imaamu Ayilara ṣalaye ninu atẹjade naa pe alaafia jọba niluu Ogbomoso fun bii aadọta ọdun.
Amọ, ilu Ogbomoso to n ṣọfọ lati bi ọdun meji bayii ti Soun ana, Oba Jimoh Oladunni Oyewumi Ajagungbade Kẹta ti waja.
O ṣalaye siwaju sii pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọọ, ati pe igba ọtun ti de l’Ogbomoso pẹlu iyansipo Ghandi gẹgẹ bi Soun tuntun.
Imaamu Ayilara sọ pe ilọsiwaju yoo ba ilu Ogbomoso bayii pẹlu ikede ọba tuntun.
O wa rọ gbogbo ọmọ Ogbomoso nile ati lẹyin odi pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu Soun tuntun fun alaafia ati itẹsiwaju ilu Ogbomoso.
Imaamu Ogbomoso wa gbadura fun ọgbọn, imọ, ilera to peye ati ẹmi gigun fun Olaoye bi o ti fẹ gori itẹ awọn babanla rẹ.

Oríṣun àwòrán, Imaamu Ogbomoso
Mi ò gbèrò láti jẹ Soun Ogbomoso rárá, àmọ̀ ìdí rèé tí mo ṣe gbà - Olaoye

Oríṣun àwòrán, Twitter/The Insight
Ayanmọ ko gboogun, ori lẹlẹjọ, bakan naa, ori to ba maa dade, ko ni ṣe alai dade.
Bayii ni ọrọ Afolabi Ghandi Olaoye ti yoo gori oye gẹgẹ bi Soun Ogbomoso tuntun ṣe ri gan an.
Ninu fidio kan ti Olaoye ti bawọn ọmọ ijọ RCCG ti o ti jẹ pasitọ sọrọ niluu Washington, l’Amẹrika ni o ti sọrọ pe oun ko nifẹ si ati jọba rara.
Olaoye ni ‘’mo wa ni Naijiria lasiko ti Soun ana, Oba Jimoh Oyewumi Ajagungbade kẹta waja.
Ninu idile marun un to n jẹ Soun Ogbomoso, idile Olaoye to jẹ idile ti mo ti wa lo kan lati jọba lẹyin idile Oba Oyewumi Ajagungbade to waja.
Ṣugbọn mi o tiẹ ri ro rara nitori mo ti gba ọna miiran lọ laye, ati pe baba mi ko figba kan sọ fun mi pe mo le jẹ ọba lọjọ iwaju ti mo ba fẹ."
"Mi o tiẹ ro lati jẹ ọba rara, ohun to wa lọkan mi ni lati maa rinrin ajo kaakiri gbogbo aye"
Ọmọọba Laoye tẹsiwaju pe "Ohun ti mo mọ ni pe baba mi gbiyanju lati jẹ Soun Ogbomoso lọdun 1940, amọ ko ri oye naa jẹ tori Ọlọrun ni ero mii fun un.’’
Bo tilẹ jẹ pe Ghandi ko gbero lati jẹ ọba, ọpọ eeyan bẹrẹ si ni pe e wi pe oun ni oye naa tọọ si.
‘’Amọ, mo dawọn lohun pe n ko nifẹ si ati jẹ Soun tori mo n ti gbero lati fẹhinti lẹnu iṣẹ tẹlẹ.
Mo pinu lati fẹhinti tori mo ti pe ọgọta ọdun, bo tilẹ jẹ pe iyẹn ko ni ki n fi iṣẹ Oluwa silẹ.
Mi o tiẹ ro nipa ati jẹ ọba rara, ohun to wa lọkan mi ni lati maa rinrin ajo kaakiri gbogbo aye.
Mo fẹran lati maa rinrin gan an, bo wa nitori inu ọkọ ni wọn bi mi si ni,’’ Olaoye lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Collage
"Pasitọ Adeboye ni ki n ma sọ pe n ko jẹ ọba tori ati ọrun ni mo ti mu ori oye waye"
Olaoye pe baba rẹ ninu Oluwa, Pasitọ Enoch Adeboye, lori ọrọ naa.
‘’Mo sọ fun wọn pe awọn eeyan fẹ ki n wa jẹ ọba ni Ogbomoṣo, amọ kii ṣe pe o wu mi lati jẹ.
Pasitọ Adeboye ni ki n ma sọ pe n ko nifẹ si ati jẹ ọba tori ati ọrun ni mo ti mu iru nkan bayii waye.
Pasitọ Adeboye ni ki n lọ gbadura ati aawẹ lori ọrọ naa.
Ṣugbọn n ko gbadura, bẹẹ ni mi o ko gbaawẹ kankan tori kii ṣe ohun ti ọkan mi fẹ lati sẹ.
Baba Adeboye sọ fun mi pe oun gan an ko fẹ di oludari ijọ ṣugbọn Ọlọrun mọ eto rẹ fun ẹnikẹni.
Nigba naa ni o sọ fun mi pe ki n tẹ siwaju lati lọ jẹ ọba naa,’’ Olaoye ṣalaye.
Lẹyin ọ rẹyin, ‘’lọjọ ti mo fẹ sọ fun gbogbo awọn eeyan to n pe mi pe ki n lọ jọba gan an ni mo beere lọwọ Ọlọrun fun ra mi pe ki ni ki n ṣe.
Lẹyin naa ni mo gbọ ohun Ọlọrun pe idi ti mo fi waye gan an ni lati jọba.
Ohun ti mo gbọ niyẹn, bo tilẹ jẹ wi pe ohun ti mo fẹ gbọ kọ niyẹn rara.
Ohun ti mo sọ fun Ọlọrun pada ni pe, ti Oluwa ko lọwọ sii ati jọba mi, ki ọrọ naa maa ni iyanju.’’
Ni opin ọsẹ to lọ ni gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti buwọlu Ọmọba Afolabi Ghadi Olaoye gẹgẹ bii Soun ilu Ogbomoso.
















