Àwọn òbí tí ọmọ wọn kú torí òògùn ikọ́ aṣekúpani ṣì ń dúró de ìdájọ́ fọ́jọ́ pípẹ́

Ọmọ ọdun mẹta ni Anirudh nigba ti wọn ya fidio rẹ kẹyin nile iwosan, nibi to ti sun silẹ gbalaja lori ibusun, ti wọn si so waya mọ lara, nimu ati lẹnu.
Iya rẹ lo n ja fitafita lati fun ni ounjẹ, to si n sọ fun ọmọ rẹ nipa awọn ere idaraya ti yoo se lẹyin ti ara rẹ ba ya tan.
Lẹyin ọjọ mẹta, lọjọ mẹwa osu Kinni ọdun 2020, se ni ọmọ naa ku nile iwosan.
Fun bi ọjọ mẹta ko to ku ni ọmọ naa ti n yagbẹ ọrin, to si tun n bi, bẹẹ ni ko le tọ rara.
Awọn obi rẹ ni awọn apẹrẹ aisan naa lo n fara han lẹyin ti awọn fun ni oogun ikọ olomi - eyi ti wọn ra lọwọ ologun kan labẹle lagbegbe Ramnagar, tii se ilu kekere kan lẹkun ariwa orilẹede India n- nibi ti wọn n gbe.
Awọn dokita nile iwosan ti wọn gbe Anirudh lọ sọ pe ẹdọforo ọmọ naa ti bajẹ.
Awọn obi rẹ ṣalaye pe oogun ikọ olomi ti ọmọ naa lo lo ṣokunfa iku rẹ.
Bakan naa lawọn oṣiṣẹ ajọ to n ṣakoso oogun lilo sọ pe oogun ikọ olomi ọhun ni eroja kan to lo ṣe akoba fun ẹdọforo, ati pe o le la iku lọ.
Veena Kumari sọ fun BBC pe ọmọ naa ko le jẹun, bẹẹ ni ko le la oju rẹ ati pe niṣe ni gbogbo ara rẹ wu.
Ọmọde mejila laarin ọdun 2019 si 2020 ti wọn ko ju ọdun marun un lọ ni akọsilẹ fidi rẹ mulẹ pe wọn jẹ Ọlọrun nipe niluu Ramnagar, latari lilo oogun ikọ olomi yii.
Ẹwẹ, Parshottam Goyal to ni ileeṣẹ ipoogun Digital Vision to ṣe oogun ikọ olomi naa ti sọ pe oogun yii kọ lo pa awọn ọmọ naa.
O ni oogun ni ileeṣẹ oun n po, kii ṣe majele.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti iroyin kan tun jade lorilẹede Gambia and Uzbekistan pe oogun ikọ olomi ṣekupa awọn ọmọde kan nibẹ ni awọn obi awọn ọmọ to ku ni ilu Ramagar ri pe o yẹ kawọn beere beere fun idajọ ododo lori iku to pa awọn ọmọde naa.
Ọpọ ninu awọn obi yii lo ṣalaye pe awọn apẹrẹ tawọn ri lara awọn ọmọ awọn wa ni ibamu pẹlu ohun to ṣe awọn ọmọde to ku ni Gambia ati Uzbekistan naa.
Bo tilẹ jẹ pe orilẹede India ni akọkọ ninu awọn orilẹede to n ta oogun sawọn orilẹede agbaye, amọ, iku awọn ọmọde ni Gambia ati Uzbekistan ti jẹ kawọn eeyan maa beere bo ya ayederu lawọn oogun kan to n jade lati India.
Amọ, awọn ajọ to n ṣagbatẹru oogun lilọ ni India ti sọ pe sababi lasan ni iku awọn ọmọde to ku ni ilu Ramnagar.
Udaya Bhaskar to jẹ ọga awọn oṣiṣẹ ajọ to n bojuto oogun lilo ati tita oogun silẹ okere ni India ṣalaye pe o ṣoro lati fidi rẹ mulẹ pe gbogbo ileeṣẹ ipoogun lorilẹede India ko maa ṣe daadaa.
Ajọ naa ṣalaye siwaju sii pe oogun ikọ olomi mẹrin ti iroyin gbe wi pe o ṣekupa awọn ọmọde lorilẹede Gambia ni ijọba ṣe ayẹwo rẹ eleyii ti ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO naa mọ nipa rẹ.
Bakan naa ni o ṣalaye wi pe ijọba India fagile iwe ẹri ileeṣẹ to ṣe oogun ikọ olomi to ṣekupa awọn ọmọde ni Uzbekistan.

O to ọdun marun un ki ileeṣẹ ọlọpaa to fẹsun kan eeyan marun un niluu Ramnagar to fi mọ ẹni to n ta oogun atawọn oṣiṣẹ mẹta ileeṣẹ ipoogun Digital Vision.
Oṣu mẹfa ni ileeṣẹ ipoogun Digital Vision to wa ni Ramnagar fi wa ni titi pa lọdun 2020 ki ileẹjọ to paṣẹ pe ko di ṣiṣi pada.
Awọn obi ni awọn n fẹ idajọ ododo lori gbogbo awọn to lọwọ ninu iku awọn ọmọ awọn.
Murfa Biwi, ọkan lara awọn obi naa eyi ti ọmọ rẹ ku lẹyin ọjọ mẹwaa ti o loogun ikọ olomi naa sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku awọn ọmọ awọn gbọdọ jiya ẹsẹ wọn.
Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto ilera ti onimọ nipa itọju awọn agbalagba, Bhavneet Bharati jẹ olori wọn ṣe iṣẹ iwadii lori iku to pa awọn ọmọde naa.
Abọ iwadii wọn ni pe eroja oloro to wa ninu oogun ikọ naa daṣẹ silẹ ninu ẹdọforo awọn ọmọ yii, bakan naa lo ṣe akoba fun ọpọlọ, ẹdọ ati fuku wọn.
Bharati ọpọ awọn ọmọ ni wọn lo ẹrọ lati mi, nigba ti awọn kan ku ti awọn mii si di alaabọ ara.
Pawan Kumar wa lara awọn ọmọ ti ko ku lẹyin ti wọn loogun naa.
Ọmọ oṣu mẹẹdogun ni i ṣe nigba ti o lo oogun ikọ olomi yii.
Oṣu mẹta ni Kumar lo nile iwosan ki o to jade lọ tẹsiwaju itọju ara rẹ nile.
Ko riran kedere mọ, bẹẹ ni ko gbọran daadaa mọ, koda o tun ni ẹjẹ ruru, gẹgẹ bi alaye ti baba rẹ ṣe.
Awọn obi awọn yii n fẹ iranwọ owo lati ọdọ ijọba ki wọn le ṣe itọju awọn wọn daadaa.















