Àwọn olórí l‘Áfíríkà péjọ láti wá ojútùú sí àkóbá tí àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣe

Aworan Aarẹ Kenya

Oríṣun àwòrán, Kenya State House

Awọn olori orilẹede ilẹ Afirika n fori kori niluu Nairobi lorilẹede Kenya lati wa ojutu si iyipada oju ọjọ to n ṣakoba fawọn eeyan.

Nibi ipade yii to jẹ akọkọ rẹ lawọn olori orilẹede ilẹ Afirika yoo ti fẹnu ko lori ohun ti wọn fẹ sọ fawọn olori orilẹede agbaye nibi ipade ajọ UN lori iyipada oju ọjọ, COP 28 laipẹ yii.

Fun ọjọ mẹta bẹrẹ lati oni ọjọ Aje lawọn olori orilẹede ilẹ Afirika yoo fi jiroro lori ọna tuntun ti wọn fẹ gba wa ojutu si eefin ọkọ atawọn ileeṣẹ nla nla to n tu sinu afẹfẹ eleyii to n ṣakoba fun agọ ara.

Ẹwẹ, Aarẹ William Ruto orilẹede Kenya sọ pe Afirika gbọdọ wa lara awọn ti yoo wa ojutu si iyipada oju ọjọ eyi to n mu ilẹ gbona.

Aarẹ Ruto ni ‘’o ti pẹ ti n koju iṣoro yii ṣugbọn a gbọdọ wa ojutu si ọrọ naa bayii.

Bakan naa ni ọpọ anfaani wa, tori naa, a o peju sibi lati maa sọ nipa iṣoro to n koju wa nikan.

A pejọ lati wa ọna abayọ si awọn ipenija to n koju wa ni.

Ipa to kere lawọn orilẹede Afirika n ko lori ati wa ojutu si iyipada oju ọjọ to ṣakoba, bo tilẹ jẹ pe awọn lo n pa lara julọ.’’