Ìròyìn àwọn “Ajẹ́ tó n mu ẹ́jẹ́ ènìyàn dá ìbẹ̀rù sílẹ̀ ní Kano, Ọlọ́pàá dá síi

Ẹwọn irin lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Kano ti kede pe awọn ti fi panpẹ mu awọn kan ni ipinlẹ naa to jẹ pe wọn fẹrẹẹ gba ẹmi awọn alejo kan ni agbegbe wọn lẹyin ti awọn eeyan fura pe “ajẹ ni wọn ti wọ́n si wa mu ẹjẹ”.

Lọsẹ to kọja ni iroyin ajarayin kan bẹrẹ si ni tan kaakiri awọn ipinlẹ ẹkun Ariwa orilẹede Naijiria pe awọn ajoji obinrin kan n lọ kaakiri ile awọn eeyan lati tọrọ omi mimu lẹyin eyi ti wọn n fa ẹjẹ awọn eeyan to n gbe ile naa mu.

Iroyin ajarayin yii to bẹrẹ bi ere bi ere ba bẹrẹ si korajọ sii ni opin ọsẹ ti nnkan si n daru sii lẹyin ti awọn eeyan kan ni Kano bẹrẹ si ni sọ pe awọn obinrin naa to le ni ọgọrun lo wọ inu ipinlẹ ọhun lati ipinlẹ agbegbe wọn, Katsina.

Nigba ti wọn ko ẹjọ ro fun Ọlọpaa, ki lo ṣẹlẹ?

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa ninu atẹjade kan sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni na ọwọ ofin jade ti wọn si ti mu eeyan mẹjọ jakejado ipinlẹ naa fun ẹsun pe wọn n tan iroyin ofege naa ka leyi to fẹrẹ fa ikorajọ pa awọn eeyan kan.

“Iroyin ofege ati irọ ni ohun to gba ilẹ kan pe awọn kan ti wọ ipinlẹ Kano bẹẹ si ni wọn n tọ ojule si ojule kaakiri lati lọ mu ẹjẹ awọn ti wọn ba ri eleyii to ti fẹrẹ fa iku awọn eniyan kan”.

“Iroyin ajarayin yii fẹrẹ ja si gbigba ẹmi awọn eeyan kan ni agbegbe Kwana Hudu, Hotoro ati Zango eyi lo mu ki awọn oṣiṣẹ wa tara ṣaṣa si iṣẹ ti wọn si fi ofin mu eeyan mẹjọ bayii.”

Ni ilu Kwana Hudu

Awọn ọlọpaa sọ pe iṣẹlẹ eyi to waye ni pe awọn eeyan kan lo kan wa si ile kan nibi ti wọn ti bẹbẹ pe ki awọn lee fi ina ẹlẹtiriiki gba ina sara ẹrọ ibanisọrọ wọn ti ọkan lara wọn si bẹbẹ lati lo ile igbọnsẹ wọn lati ibẹ ni iyawo ile naa ti bẹrẹ si ni pariwo pe “ajẹ, ajẹ” eyi si mu ki awọn eeyan sare wọle lati fẹ dawọjọ pa awọn alejo naa.

Awọn ọlọpaa ni awọn ṣi n wa ki awọn fi panpẹ ọba mu awọn eeyan mii sii to n gbe iroyin naa kiri ti wọn si n da ibẹru ohun ipaya si ọkan awọn eniyan.

Bakan naa ni wọn kilọ fawọn eniyan ki wọn dawọ fifi ọwọ ara wọn gbe ofin nija duro.

“Ibẹru ko jẹ ki n ṣilẹkun ile mi fun èèyàn fun odidi ọjọ mẹrin bayii”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni bii ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja ni awọn fidio ati fọto kan bẹrẹ si ni tan ka ori ayelujara to n ṣafihan awọn obinrin kan ti awọn eniyan n na tori wọn ni pe ajẹ ni wọn.

Awọn obinrin to wa ninu fidio naa ṣe awọn ijẹwọ kan ninu ibẹru eyi si jẹ ki awọn eeyan kan maa gbe iroyin kiri wipe “bi o ba ni alejo kankan tabi oju ti o ko mọ ni ile rẹ, o lee jẹ pe awọn ajẹ yẹ ni”.

Lati fihan bi iroyin naa ṣe sare tan ka, awọn araalu kan lawọn ipinlẹ kọọkan ni Ariwa Naijria sọ pe ninu ibẹru bojo ni awọn wa fun ọjọ melo kan bayii.

Usman Isah to n gbe ni Kano sọ pe kikan ilẹkun ti awọn ba gbọ lara ilẹkun ile oun lati Ọjọbọ ọsẹ, pẹlu ibẹru ni oun fi n ṣi i.

“Lati igba ti ọrẹ mi nibi iṣẹ ti sọ fun mi nipa awọn ajẹ naa to si ni wọn n lọ kaakiri ile pe pẹlu ibẹru ni oun fi n ṣilẹkun.

“Ẹnikẹni to ba kan ilẹkun bayii, maa kọkọ sọ pe ‘waye’ (ta ni yẹn), bi ẹni naa ko ba darukọ rẹ, mi o ki n ṣi i.”

Bakan naa, Adamu Kankia ni ipinlẹ Katsina naa sọ pe iṣẹlẹ naa buru ju ni agbegbe ti wọn gẹgẹ bi awọn eeyan ko tilẹ ṣe gba ẹnikẹni gbọ mọ koda titi kan awọn eeyan ti wọn mọ nitori ibẹru pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ.

“Ni Katsina nibi, ọrọ naa buru gan tori bi awọn eeyan kan ko ṣe tilẹ gba alejo mọ ni ile wọn nitori ibẹru awọn ajẹ”.

Iru iroyin ibẹru yii kan naa lo wa ni Zamfara, Sokoto ati Kaduna ati titi de ipinlẹ Jigawa ṣugbọn awọn ọlọpaa n gbiyanju lati fi ọkan awọn eeyan balẹ tori ki wọn le maa ba ohun gbogbo lọ bo ṣe wa tẹlẹ lai bẹru.