Obìnrin tó kun Nọ́ọ̀sì olóyún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, tó tún ń ta ẹ̀yà ara èèyàn fáwọn Babaláwo, wọ gàù ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, SP Tochukwu Ikenga
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan to lọwọ ninu iku arabinrin nọọsi to loyun, ti wọn ṣawari oku rẹ ti wọn kun, tun ge wẹlẹwẹlẹ.
Ọlọpaa ni awọn ri ẹya ara obinrin Nọọsi naa gba lọwọ Babalawo kan ni ile orisa rẹ, ti igbiyanju si n lọ lọwọ lati ṣawari awọn yoku.
Iṣẹlẹ yii waye ni agbegbe Ogbunike, ni ijọba ibilẹ Oyi nipinlẹ Anambra.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra, SP Tochukwu Ikenga, ni ọwọ tẹ obinrin kan, ẹni ọdun mẹrindinlogun ni ọjọ kẹẹdọgbọn osu keje ọdun 2025.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni obinrin naa jẹ ọkan lara awọn afurasi naa ti wọn lọwọ ninu iku nọọsi oloyun ti wọn ṣekupa.
"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra pẹlu iranlọwọ awọn araalu Umueri ni Ogbunike mu obinrin kan to jẹ afurasi, ẹni ọdun mẹrinlelogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa tẹsiwaju pe awọn ọdaran yii ti ge ẹya ara obinrin oloyun naa, ti wọn to ju si ile igbẹ."
'Wọn n ta ẹya ara eeyan fun awọn Babalawo'
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn awọn iroyin ti yoo ṣe anfani fun iwadii wọn lasiko ti wọn ba afurasi sọrọ lori iṣẹlẹ naa.
Ọlọpaa ni afurasi ọhun jẹwọ pe oun jẹ ọrẹbinrin fun eeyan to ṣekupa nọọsi oloyun naa, ti wọn si pe wa ko wa palẹ ara oloogbe naa mọ.
Bakan naa ni ọlọpaa ni afurasi ọhun sọ fun wọn pe ṣe ni awọn ma n ta ẹya ara yii fun awọn Babalawo ni agbegbe naa.
"Lasiko ifọrọwerọ, afurasi jẹwọ pe oun ni ọrẹbinrin fun ọkan ninu awọn afurasi to ṣekupa nọọsi oloyun, to ti fẹ sẹ fẹ.
"O ni wọn ransẹ pe oun ki oun wa fọ ẹjẹ lẹyin ti wọn ṣekupa oloogbe naa.
Bakan naa lo ṣalaye bi wọn ṣe maa n ta orisirisi ẹya ara fun awọn Babalawo ni agbegbe naa."
Ohun ta ri gbọ ni pe, awọn afurasi yii ni wọn ransẹ pe nọọsi oloyun yii pe, ara wọn ko ya, ti wọn si nilo oogun.
Kete ti nọọsi naa de si ile wọn, ni wọn ṣekupa.
Ọlọpaa yawọ ile orisa, ṣawari ẹya eeyan ninu apo
Lasiko iwadii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra ni awọn yawọ ile orisa kan ni abule naa, ti wọn si ṣawari ẹya eeyan ninu apo.
Ẹka iwadi ọtẹlẹmuyẹ, State Criminal Investigation Department (SCID) ni ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu kejeni awọn ṣawari ẹya eeyan naa.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn si n wa awọn afurasi to fẹsẹ fẹ ati awọn Babalawo ti wọn jọ n sisẹ papọ.
Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Ikioye Orutugu bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ naa.
O ṣapejuwe iwa naa gẹgẹ iwa ọdaran, ti o si rọ araalu lati kun wọn lọwọ lati ṣawari awọn afurasi to ṣa lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo dabobo ẹnikẹni to ba pese iroyin nipa awọn afurasi naa fun ileeṣẹ ọlọpaa, lati ṣawari wọn.











