Èèyàn 22 jáde láyé, 1,200 di èrò àtìmọ́lé níbi ìwọ́de èlé owó epo tó ń wáyé ní Angola

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, Israel Campos
- Role, in Luanda
- Author, Natasha Booty
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀ èdè Angola ti sọ pé èèyàn méjìlélógún tó fi mọ́ ọlọ́pàá kan ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìwọ́de kan tó wáyé ní Luanda, olú ìlú orílẹ̀ èdè náà.
Bákan náà ni èèyàn tó ní ẹgbẹ̀fà ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá látàrí ìwọ́de náà.
Ohun tó bẹ̀rẹ̀ bíi ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́ta táwọn awakọ̀ gùnlé látàrí àlékún tó bá owó epo bẹntiróòlù ló ti lágbára di ohun tó ń fa wàhálà ní Angola.
Ìwọ́de ọ̀hún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé ni ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ará ìlú darapọ̀ mọ́, tó sì di ohun tí wọ́n gbégi dínà, ba ọ̀pọ̀ ọkọ̀ jẹ́, jíjá ṣọ́ọ̀bù àti ìkọlù láàárín àwọn ọlọ́pàá àtàwọn olùwọ́de.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn olùwọ́de náà tún gbìyànjú láti jalè ní ẹkùn Icolo e Bengo àti Huambo èyí tí wọ́n ní àwọn ti kápá rẹ̀ báyìí.
Ìwọ́de náà ló tún tẹ̀síwájú ní Luanda lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, tí ìkọlù sì tún wáyé láàárín àwọn olùwọ́de àtàwọn ọlọ́pàá èyí tó ṣokùnfà kí ìró ìbọn máa dún lákọlákọ ní àwọn agbègbè kan ní Luanda.
Kí ló ṣokùnfà ìwọ́de náà?
"Àlékún owó epo yìí ló jẹ́ kí ìjọba sún àwọn aráàlú kan ògiri…ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sú.
Eebi ti di tọ́rọ́ fọ́nka sílé, ara ń ni àwọn tálákà," olùwọ́de kan, Laura Macedo sọ fún BBC.
Àwọn awakọ̀ èrò ló bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì látàrí bí ìjọba ṣe mú àlékún bá owó epo bẹntiróòlú pẹ̀lú ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33%), ìgbésẹ̀ tí ìjọba bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Keje.
Èyí jẹ́ lára èròńgbà láti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.
Yàtọ̀ sí pé ìgbésẹ̀ náà ti mú àlékún bá owó ọkọ̀, ó ti mú àlékún bá owó oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì.
Ṣùgbọ́n ààrẹ João Lourenço sọ pé àwọn èèyàn náà ń ṣe ìwọ́de ọ̀hún láti tako ìjọba òun.
"Lkyìn àlékún náà, $40 ni wọ́n ṣì ń ta lítà dísù kan ní Angola, orílẹ̀ èdè tí owó epo ti wálẹ̀ báyìí kò pọ̀ káàkiri àgbáyé," João Lourenço sọ fún CNN Portugal nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan.
70,000 kwanzas ní owó oṣù tó kéré jùlọ táwọn èèyàn ń gbà ní Angola tí ìlérí ìjọba láti sọ ọ́ di 100,000 kwanzas kò ì tíì wá sí ìmúṣẹ.
Ní ọjọ́ Ajé ni àwọn olùfẹ̀hónúhàn ya wọ àwọn òpópónà ní Luanda tí wọ́n sì ń kọrin tako àlékún owó epo náà, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀hónú wọn hàn sí ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú MPLA tó ti ń ṣe ṣèjọba ní orílẹ̀ èdè náà bíi àádọ́ta ọdún sẹ́yìn.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn tó jẹ́ ti ìjọba ni wọ́n ti ń bu ẹnu àtẹ́ lù fún bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ètò wọn lọ láì gbé ìwọ́de tó ń wáyé náà.

Oríṣun àwòrán, Luamba Muinga
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé ni ẹgbẹ́ òṣèlú MPLA ṣèkìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ láti má kópa níbi ìwọ́de náà àtàwọn ìwà bíba nǹkan ìní ìjọba jẹ́.
Wọ́n ní ìwọ́de náà ń wáyé láti ba ayẹyẹ àádọ́ta ọdún tí Angola gba òmìnira tí wọ́n fẹ́ ṣe jẹ́ ni.
Àwọn aláṣẹ ní Luanda lọ́jọ́ Ajé nínú àtẹ̀jáde kan kọminú lórí bí wọ́n ṣe ń ba nǹkan ìní ìjọba jẹ́, tí wọ́n sì ní ìyanṣẹ́lódì táwọn ọlọ́kọ̀ kọ́kọ́ gùnlé ni wọ́n ti ṣẹ́wẹ́lé lẹ́yìn tí wọ́n ti jíròrò pẹ̀lú ìjọba.
Ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ kan ní Angola, Anata, ni àwọn kò lọ́wọ́ nínú làásìgbò tó wáyé náà àmọ́ tí wọ́n ní àwọn ṣì máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìyanṣẹ́lódì àwọn nítorí ó jẹ́ ohun àwọn èèyàn Angola.
Títí di ọ̀sán ọjọ́rú, ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìtajà, ilé ìfowópamọ́ àtàwọn iléeṣẹ́ ló wà ní títìpa. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti padà sí ẹnu iṣẹ́ wọn, nígbà tí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ fún iléeṣẹ́ aládàni kò lọ síbi iṣẹ́ látàrí ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn yóò máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwọ́de lójúnà àti ri pé àlááfíà jọba ní gbogbo agbègbè.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images















