Ooru ọmọ Nàíjíríà ń mú wa, ìwà ọ̀daràn, òwò nàbí àti ìjínigbé níṣẹ́ wọn - Àwọn ọmọ Ghana yarí

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ariwo ti sọ ni orilẹede Ghana nigba ti awọn eeyan kan tu sita, lati se iwọde tako awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹede naa.
Awọn eeyan yii lo fi oniruuru ẹsun kan awọn ọmọ Naijiria to n gbe pẹlu wọn, ti wọn si taku wọnle pe o di dandan ki alejo wọn maa lọ.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni Ghana ni pe wọn n se owo Nabi, ti wọn si tun n fawọn eeyan se etutu ọla.
Fidio kan to lu ori ayelujara pe lo n safihan bi iwọde naa se waye, nibi tawọn oluwọde naa ti gbe oniruuru akọle lọwọ.

Oríṣun àwòrán, screenshot
"O di dandan ki awọn ọmọ Naijiria fi orilẹede wa silẹ nitori iwa ọdaran ati owo nabi ti wọn n ṣe"
Lara ohun ti wọn kọ sara awọn akọle naa ni pe "A fẹ fopin si iwa idigunjale ati ikọlu ọdaran, ilera wa wa ninu ewu tori owo nabi ọlọpọ ero"
Bakan naa ni wọn tun kọ ọ pe "Ta ni yoo daabo bo ẹtọ ati ominira awọn ọmọ ilẹ Ghana, awọn ọmọ Naijiria n ji wa gbe, wọn n fi wa se etutu ọla, ojoojumọ ni awọn ọmọ wa n sọnu tori ẹya Igbo.
Ko tan sibẹ o, fidio naa tun se afihan aworan ọkunrin kan ti wọn fẹsun kan awọn ọmọ Naijiria to wa lagbegbe Accra, pe awọn lo pa a.
Obinrin kan to sọrọ ninu fidio ifẹhonuhan naa salaye pe o di dandan ki awọn ọmọ Naijiria fi orilẹede awọn silẹ nitori iwa aibikita ti wọn n hu lorilẹede naa.
Yatọ si eyi, oluwọde miran tun ni awọn ọmọ Naijiria ti gbakoso awọn ọja wọn gbogbo, ti wọn si n huwa oniruuru laabi kaakiri orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
"Awọn ọmọ Naijiria n sisẹ ibi kaakiri orilẹede wa, wọn n fi tipa gba awọn ilẹ wa, amọ, a maa gba ilẹ wa pada"
Gẹgẹ bi wọn se salaye "awọn ẹya Igbo yii ni wọn wa kaakiri orilẹede yii, ti wọn si n fẹju mọ awọn ọja wa lati gba mọ wa lọwọ.
Koda, yatọ si ẹya Igbo, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni wọn wa kaakiri awọn abule wa, ti ofin wa ko si gba ki awọn ajeji maa da si ohun to se koko.
Awọn ọmọ Naijiria yii n sisẹ ibi kaakiri orilẹede yii, koda, wọn ni ọba Igbo ni orilẹede Ghana.
Wọn n fi tipa gba awọn ilẹ wa, amọ, fun igba diẹ ni, a maa bori wọn, ti a si gba ilẹ wa pada."

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ijọba Naijiria fesi lori iwọde lile awọn ọmọ Naijiria kuro nilẹ Ghana
Wayi o, ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, (The Nigerians in Diaspora Commission) (NiDCOM) ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati se suuru lori iwọde tawọn ọmọ orilẹede Ghana gun le lati le awọn ọmọ Naijiria lorilẹede wọn.
Atẹjade kan ti alaga fun ajọ NiDCOM, Abike Dabiri-Erewa, fisita ni owurọ oni ọjọru lo sisọ loju ọrọ yii, to si se apejuwe iwọde naa pe wọn sọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria ni orukọ buruku bii ọdaran lai yọ awọn kanda ninu irẹsi.
"Awa ọmọ Naijiria kii se ọdaran, asoju rere ni a jẹ nibikibi ti wọn ba waz, amọ o yẹ ki wọn sawari awọn kanda ninu irẹsi to ba wa laarin wọn lati foju wina ofin fun ẹsẹ wọn."
Atẹjade naa, ti osisẹ alarina fun ajọ NiDCOM, Abdur-Rahman Balogun fọwọsi fikun pe "orilẹede Ghana ati Nigeria da bii ibeji ni.
Ọmọ iya kan naa ni wa, ẹmi ajọ ECOWAS ati ajọsepọ ẹlẹkunjẹkun ti a dijọ n se si gbọdọ tẹsiwaju, ki a le maa gbe pọ bii tọmọ-tiya."
Itan "Ghana Must Go" tun ara rẹ kọ lẹyin mejilelogoji, o di "Nigeria Must Go"
Isẹlẹ iwọde yii lo dabi pe o n tun itan miran kọ nipa ajọsepọ to wa laarin orilẹede Naijiria ati Ghana.
Irufẹ isẹlẹ yii si ti waye ri nigba ti awọn ọmọ Naijiria se iwọde pe kawọn ọmọ orilẹede Ghana kuro nilẹ yii, ki wọn pada si orilẹede wọn.
Ọdun 1983 ni isẹlẹ waye eyit ti wọn pe ni "Ghana Must Go", bakan naa, awọn ọmọ Ghana ti da a pada fawọn ọmọ Naijiria, ti wọn si ni "Nigeria Must Go" lọtẹ yii.
Lasiko ti isẹlẹ Ghana must go waye, Alhaji Shehu Shagari ni aarẹ orilẹede yii, to si sofin pe kawọn ajeji ti ko ni iwe igbelu, ko ẹru wọn kuro ni orilẹede yii.
Ọpọ awọn ajeji ti ko si ni iwe igbelu naa si lo to miliiọnu meji, o si le ni idaji wọn to jẹ ọmọ orilẹede Ghana.
Ofin ọhun ni "Awọn ajeji ti ko niwe igbelu, ti ko ba kuro nilẹ yii, ni yoo foju wina ofin, ti wọn yoo si fi sọko pada sile.
Se lawọn ọmọ ilẹ Ghana nigba naa si ko ẹru wọn, ti wọn di sinu apo kan eyi tawọn ọmọ Naijiria sọ ni "Ghana Must Go"

Oríṣun àwòrán, screenshot















