Wo ìgbà mẹ́fà tí Tinubu gba owóyàá láti ìgbà tó ti ń darí ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu èròǹgbà ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinibu láti yá owó tó lé ní bílíọ́nù mọ́kànlélógún dọ́là ($21bn) láti fi di àwọn àlàfo tó wà nínú àbá ìsúná ọdún 2025.
Ìjọba Nàìjíríà ní àwọn máa lo owó náà láti fi ṣe àwọn ètò ìdàgbàsókè ní ẹ̀ka ìlera, ètò ẹ̀kọ́, ààbò àti àyíká.
Bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là ($3bn) nínú owó náà ni ìjọba ní àwọn fi máa ṣe àtúnṣe ètò ìrìnnà ojú irin ní ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Èyí ní àkójó ìgbà mẹ́fà tí Ààrẹ Bola Tinubu ti gbà láti ìgbà tó ti gba ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà.
- Ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Keje, 2025
Ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu ìbéèrè ìjọba àpapọ̀ láti yá owó tó lé ní $21bn nílẹ̀ òkèèrè láti fi ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ láàárín ọdún 2025 sí 2026.
- Ọjọ́ Kẹfà, oṣù Karùn-ún, 2025
Ìjọba àpapọ̀ buwọ́lu yíyá owó $652m ní ilé ìfowópamọ́ Exim Bank ti orílẹ̀ èdè China láti fi ṣe ọ̀nà tó so ibùdókọ̀ ojú omi Lekki Seaports pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ìfopọ bẹntiróòlù.
- Ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá, 2024
Ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu ìbéèrè ẹ̀yáwó $2.21bn láti ilẹ̀ òkèèrè láti fi ṣe àmúṣẹ àbá ìsúná ọdún 2024.
- Ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹfà, 2024
Nàìjíríà rí ẹ̀yáwó $2.25bn gbà láti ilé ìfowópamọ́ àgbáyé, World Bank lójúnà àti mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé àti láti fi ṣe àtìlẹyìn fáwọn aláìní.
- Ọjọ́ Kìíní, oṣù Karùn-ún, 2024
Ìjọba àpapọ̀ rí àtìlẹyìn ilé aṣòfin àgbà láti yá $500m láti fi ṣe ọ̀pọ̀ mítà iná mọ̀nàmọ́ná fáwọn èèyàn èyí tó wà lára èròńgbà ẹ̀yáwó $7.94bn fún ọdún 2022 sí 2024.
- Ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kejìlá 2023
Ilé aṣòfin àgbà ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba àpapọ̀ láti yá $7.4bn àti €100m ní àmúṣẹ èròǹgbà láti yá owó àpapọ̀ $7.94bn láàárín ọdún 2022 sí 2024.
Nígbà tó fi máa di ìparí oṣù Kẹta, ọdún 2025, gbèsè tí Nàìjíríà jẹ ti wọ ₦149.39trn.
Èyí ló jẹ́ àlékún ₦27.7trn sí iye gbèsè tí Nàìjíríà jẹ ní oṣù Kejìlá ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó gbèsè Nàìjíríà ìyẹn National Debt Monitoring Office ṣe sọ.
Àlékún gbèsè yìí ló ń wáyé bí Nàìjíríà ṣe ń gba ẹ̀yáwó tuntun láti ilẹ̀ òkèèrè àti bí owó Náírà ṣe ń já wálẹ̀.















