Ọ̀nà láti rí owó àti ṣíṣe àfọ̀mọ́ ìwà ìbàjẹ́ ní àwújọ ló mú mi máa ṣe àwàdà lórí ayélujára - Alfa Kekere

Àkọlé fídíò, Ọ̀nà láti rí owó àti ṣíṣe àfọ̀mọ́ ìwà ìbàjẹ́ ní àwújọ ló mú mi máa ṣe àwàdà lórí ayélujára - Alfa Kekere
Ọ̀nà láti rí owó àti ṣíṣe àfọ̀mọ́ ìwà ìbàjẹ́ ní àwújọ ló mú mi máa ṣe àwàdà lórí ayélujára - Alfa Kekere

Babatunde Muhammad, ti gbogbo eeyan mọ si Alfa Kekere, jẹ apanilẹrin ọmọ kekere lori ayelujara.

Ilu Ilorin si lo wa nibi to ti n pa awọn eeyan lẹrin lori ayelujara amọ o ti di gbajumọ ilumọọka nidi isẹ naa.

Awada yii lo fi n safihan iwa tawọn Alfa maa n hu eyi to fi n pa awọn eeyan lẹrin.

Yatọ si awada sise, Alfa Kekere tun maa n lo eto rẹ naa lati tọka si ọpọ iwa aitọ to n lọ ni awujọ wa, eyi to fi n se idanilẹkọ fawọn ololufẹ rẹ.

BBC Yoruba wa nilu Ilorin lati ba Alfa Kekere ati ọga rẹ sọrọ, fidio okey ii si lo se akojọpọ ohun ti wọn ba wa sọ.

Alfa Kekere ati Alfa Lakuli

"Ọjọ ti inu mi dun julọ lẹnu isẹ yii ni ọjọ ti isẹ yii gbe mi pade gomina ipinlẹ Kwara, to bọ mi lọwọ"

Nigba ti oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, Babatunde Muhammad ti ọpọ eeyan mọ si Alfa Kekere ni Alfa Lakuli ati Brọda Sola ni oun ri, ti wọn n se awada lori ayelujara, lo mu oun.

"Mo lọ ba Alfa Lakuli pe emi naa fẹ maa se Kọmẹdi pẹlu erongba pe emi naa yoo maa ri owo nidi rẹ.

Ọjọ keji t imo lọ ba wọn naa ni wọn lo mi.

Ọjọ ti inu mi dun julọ lẹnu isẹ yii ni ọjọ ti isẹ yii gbe mi pade gomina ipinlẹ Kwara, mo fẹ sa ọwọ gomina, amọ gomina sare gbe ọwọ rẹ.

Amọ a bọ ara wa lọwọ.

Alfa Kekere

Ti mo ba ni baba Alfa Kekere ni mo jẹ, deede ni, ti mo ba si ni ọga rẹ ni mi, deedee naa ni tori ọmọ ẹgbọn ẹni, ọmọ ẹni nii se - Alfa Lakuli

Soliu Sulaiman Omotoso to n jẹ Alfa Lakuli , tii se ọga fun Alfa Kekere, nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, salaye pe ọmọ ẹgbọn oun ni Alfa Kekere.

"Ti mo ba ni baba rẹ ni mo jẹ, deede ni, ti mo ba si ni ọga rẹ ni mi, deedee naa ni tori ọmọ ẹgbọn ẹni, ọmọ ẹni nii se.

A ko ri owo rara lẹnu isẹ yii, ti n ko ba ni parọ tan yin jẹ, tori kii se isẹ ti a n se pẹlu aniyan pe ka le ri owo nidi rẹ.

A bẹrẹ awada ori ayelujara naa tori nnkan to wu wa pe ki awa naa maa se niyi ni, a ko ri owo nidi rẹ.

Amọ a mọ pe pẹlu alubarika ni ọdọ Ọlọrun ati daadaa ti awọn ara iwaju se nidi rẹ, awa naa yoo se e, a si ri daada nidi ere awada naa."

Alfa Lakuli

"A lọ si lokesan ere awada lori ayelujara ni, a gbe ọkada ti a ngun lati fi sere kalẹ, se ni wọn ji gbe salọ"

Nigba to n salaye ọjọ manigbagbe fun lẹnu isẹ awada sise naa, Alfa Lakuli ni ọjọ ti inu oun bajẹ julọ ni ọjọ ti wọn ji ọkada ti wọn gun lati lọ fi se awada ori ayelujara lọ.

"A lọ si lokesan ti a ti fẹ sere awada ori ayelujara ni, a gbe ọkada ti a ngun lati fi sere kalẹ, se ni wọn tun ji gbe.

Ọjọ yii gangan ni inu mi bajẹ julọ.

Mo wa n rọ gbogbo awọn akẹẹgbẹ mi ti a dijọ n gbe eto jade lori ayelujara pe igbagbọ ninu Ọlọrun ati adura gbigba se koko.

To ba ti jẹ pe eto ti a n gbe jade sori ayelujara ko tako ofin ẹsin ati ofin ilu, ẹ jẹ ka nigbagbọ lori rẹ pe yoo dara.

Ka si maa se adura pe ki Ọlọrun fi alubarika si."

Ẹ wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ alaye.