Wo iye ìgbà tí àwọn eléré ìdárayá gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ààrẹ àti ẹ̀bùn tí wọn gbà

Rasheedat Ajibade gbé ife ẹ̀yẹ lé ààrẹ Bola Tinubu lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Àkọlé àwòrán, Rasheedat Ajibade gbé ife ẹ̀yẹ lé ààrẹ Bola Tinubu lọ́wọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Láti ìgbà tí ààrẹ ti kéde àwọn ẹ̀bùn yìí ni awuyewuye ti ń wáyé táwọn ọmọ Nàìjíríà sì ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ ààrẹ yìí.

Bí àwọn kan ṣe ń kan sáárá sí Tinubu pẹ̀lú bó ṣe fún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó tabua náà ni àwọn míì ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú pé owó náà ti pọ̀jù.

Ohun tí àwọn kan ń sọ ni pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún le tó ṣe nǹkan fún Nàìjíríà pàápàá fáwọn tálákà tí wọn kò rí ọwọ́ họrí.

Ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó sọ̀rọ̀ ní Wemzo Emmanuel tó wòye pé $100,000 pọ̀ púpọ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù náà nígbà tí ìṣẹ́ àti òṣì ń bá ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà fínra.

Emmanuel ní ọ̀pọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ni wọ́n ti ní owó púpọ̀ tẹ́lẹ̀.

Otolorin Hakeem ní "àwọn èèyàn sì ń jìyà ní Nàìjíríà, Ọlọ́run ń bẹ ṣá."

Fún Mufuliat Musa "Erikkk kosi owo lorilede wa yi rära, yin osise ijoba elo ni owo osu yin mo fe binu san."

Bákan náà ni àwọn mìíràn tún bu ẹnu àtẹ́ lu bí ààrẹ ṣe kéde ẹ̀bùn owó náà pẹ̀lú owó ilẹ̀ òkèèrè.

Ohun táwọn èèyàn náà ń sọ ni pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ gbígbé owó ilẹ̀ òkèèrè lárugẹ ju owó náírà lọ.

Àmọ́ báwọn kan ṣe ń sọ pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ni àwọn míì ń sọ pé owó náà kò pọ̀ jù àti pé àwọn agbábọ́ọ̀lù náà yẹ láti jèèrè iṣẹ́ wọn.

Tinubu, aya ààrẹ, Rasheedat Ajibade àti Chiamaka Nnadozie

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons ti ṣiṣẹ́ takuntakun, èrè iṣẹ́ wọn ni wọ́n ń jẹ - Mutiu Adepoju

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí kan ní Nàìjíríà Mutiu Adepoju sọ fún BBC News Yorùbá pé àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons ti ṣiṣẹ́ takuntakun, tó sì jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí ààrẹ Tinubu fún wọn náà ni wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí.

"Àwọn ọmọbìnrin yìí ti gbìyànjú, wọ́n ti gbé orílẹ̀ èdè wa lárugẹ.

"Èmi lérò pé ó yẹ ká kan sáárá sí ààrẹ Nàìjíríà fún ìgbésẹ̀ yìí àti pé wọ́n ṣe irú nǹkan báyìí."

Adepoju ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ìjọba tó ti fún àwọn agbábọ́ọ̀lù kankan ní owó tó pọ̀ bí èyí rí, ó ní ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìjọba yóò máa ṣe kóríyá fáwọn agbábọ́ọ̀lù.

Ó tẹ̀síwájú pé àrà ọ̀tọ̀ ní ìgbésẹ̀ ààrẹ Tinubu yìí àti pé yóò jẹ́ ìwúrí fáwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lẹ́yìn pé tí àwọn bá ṣe dáadáa nínú ìdíje, àwọn máa rí ẹ̀bùn tó jọjú gbà nílé.

Bákan náà ni agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, Bayo Onanuga nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ayélujára sọ pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà kò pọ̀ rárá tí a bá wo iṣẹ́ táwọn agbábọ́ọ̀lù náà ṣe.

Ó ní iṣẹ́ takuntakun, ìfẹ́ orílẹ̀ èdè ẹni àti ọgbọ́n àtinúdá àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ni ààrẹ bu iyì fún pẹ̀lú ohun tó ṣe fáwọn ọmọbìnrin ọ̀hún.

Ó wòye pá ọ̀pọ̀ àwọn ìdíje bíi Big Brother Naija, BBN ni wọ́n máa ń fún ẹni tó bá gbégbá orókè ní owó tabua bíi ₦150m èyí tó ní kò ní ipa kankan lórí orílẹ̀ èdè.

Kí ló fa ìyapa ẹnu yìí?

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ọdún 2025 ni ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu fi ẹ̀bùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, ilé àti oyè dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá láti ṣe kóríyá fún wọn látàrí bí wọ́n ṣe gba ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù 2024 Women Africa Cup of Nations.

Ní ilé ààrẹ Aso Rock tó wà ní ìlú Abuja ni ààrẹ ti gbàlejò àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lẹ́yìn tí wọ́n padà sí Nàìjíríà láti Morocco tí ìdíje náà ti wáyé.

"Ní orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo fi oyè Officer of the Order of the Niger, OON, dá a yín lọ́lá," Tinubu sọ.

"Ní àfikún, mo darí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àkóso ilé ìgbé Renewed Hope Housing Estate láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ilé oní yàrá mẹ́ta mẹ́ta.

Bákan náà ni ààrẹ tún kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó náírà tí iye rẹ̀ jẹ́ $100,000 fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́rìnlélógún náà àti $50,000 fáwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn.

Níbi ayẹyẹ náà ni alága àwọn gómìnà Nàìjíríà tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn àtàwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn.

Ààrẹ Nàìjíríà àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons

Ìgbà tí àwọn olùdíje lére ìdárayá gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ààrẹ

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tàbí eléré ìdárayá yóò máa rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ ìjóba nígbà tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ takuntakun lásìkò ìdíje.

Ní ọdún 2023 tí ikọ̀ Super Eagles gbé ipò kejì níbi ìdíje AFCON ọdún 2023 ni ààrẹ Bola Tinubu fún wọn ní ẹ̀bùn ilé àti ilẹ̀ ní ìlú Abuja.

Bákan náà ni ààrẹ tún fún ní ẹ̀bùn owó tó sì fi oyè Member of Order of Niger, MON, tó fi dáwọn lọ́la.

Mutiu Adepoju sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìjọba máa ń ṣe kóríyá fáwọn eléré ìdárayá tí wọ́n bá ṣe dáadáa níbi ìdíje bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ẹni tó gba owó tó pọ̀ tó ti àwọn Super Falcons yí rí.

Ní ọdún 2022, ààrẹ àná ní Nàìjíríà, Muhammadu Buhari fún àpapọ̀ àwọn eléré ìdárayá tó kópa níbi ìdíje 2022 Commonwealth Games (CWG) ní ẹ̀bùn ₦200m.

Agbenusọ ààrẹ nígbà náà, Femi Adesina pé ààrẹ Buhari tún fi oyè dá àwọn eléré ìdárayá náà lọ́lá.

Góòlù méjíl, fàdákà mẹ́sàn-án àti bàbà mẹ́rìnlá ni ikọ̀ Nàìjíríà gbà níbi ìdíje náà, tí wọ́n sì jẹ́ ilẹ̀ Africa tó wà ní ipò tó wà lókè jùlọ pẹ̀lú ipò keje tí wọ́n gbé níbi ìdíje náà.