Mi ò kí ń pe ara mi ní ọmọ Naijiria mọ́- Kemi Badenoch

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi orilẹede Naijiria ni, olori ẹgbẹ oṣelu Conservative lorilẹede UK, Kemi Badenoch, ti ni oun ki i pe ara oun lọmọ Naijiria mọ.
Kemi Badenoch sọ pe oun ko tiẹ sọ iwe irinna ọmọ Naijiria oun di ọtun mọ ( renew) lati ọdun 2000.
Orilẹede United Kingdom ni awọn obi Kemi bi i si, ṣugbọn Naijiria ati UK lo ti ṣe igba ewe rẹ.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo wa nigba to pada si UK, o ni nitori wahala oṣelu ati aiṣe deede ọrọ aje loun ṣe kuro.
Nibi eto kan ti atokun eto, Gyls Brandreth Rosebud, ṣe ni Kemi Badenoch ti sọ pe:
"Ọmọ Naijiria ni mi nipasẹ awọn irandiran mi, ṣugbọn ti mo ba fẹẹ fi ara mi han, emi ki i ṣe ọmọ Naijiria bẹẹ yẹn.
"Mo mọ orilẹede naa daadaa, mo ni ọpọ mọlẹbi nibẹ, o si maa n wu mi lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ, ṣugbọn ibi ti awọn ẹbi mi wa bayii ni ile mi."
''Mi ò lérò pé mo nílò ìwé ìrìnnà Naijiria mi''
Ni afikun ọrọ rẹ, Kemi Badenoch sọ pe oun ko ro pe oun ni kinni kan toun yoo lo iwe irinna (Passport) Naijria fun.
"Mi o tiẹ ki n ri i ro. UK ni mo ti lo ọpọ igbesi aye mi, mi o ro pe mo nilo rẹ. "
Nigba to n ṣalaye nipa idi ti ero rẹ nipa Naijiria ṣe ri bi eyi, Badenoch to gbe niluu Eko, sọ pe nigba ti baba oun ku toun si fẹẹ gba fisa, ko rọrun rara.
Bakan naa lo ni bi eto oṣelu Naijiria ṣe ri, oun ko ṣe gbadun rẹ.
Kemi sọ pe ibanujẹ loun fi pada si UK ni 1996, ati pe awọn obi oun gan-an ti maa n sọ ọ tẹlẹ pe oun ko ni ọjọ iwaju ni Naijiria yii.
O fi kun un pe nigba toun balẹ si UK, oun ri i pe gbogbo wọn ni wọn gba oun tọwọtẹsẹ, ẹlẹyamẹya ko si ninu ọrọ wọn.
"Nnkan ti mo ri ni pe awọn eeyan ko ya mi sọtọ, ohun to maa n jẹ ki n ja fun UK nibikibi ti ọrọ ẹlẹyamẹya ba ti waye niyẹn. "
Ẹ o ranti pe eyi kọ ni igba akọkọ ti Badenoch yoo sọ ero rẹ nipa Naijiria, ọpọ eeyan lo si maa n koro oju si ohun to maa n sọ.
Ipari ọdun to kọja ni awọn kan bu u nigba to ni ipaya loun fi gbe Naijiria, ati pe ijẹkujẹ awọn oloṣelu gba okun gan-an.














