Ohun tí ìwé òfin Naijiria sọ lórí ọ̀rọ̀ Kemi Badenoch tó ní àwọn ọmọ òun kò lànfàání láti di ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adari ẹgbẹ oṣelu Conservative Party ni United Kingdom, Kemi Badenoch, tun ti sọrọ mii nipa orilẹede Naijiria eyi to da awuyewuye silẹ.
Nnkan ti Kemi sọ lọtẹ yii ni pe loootọ ni oun jẹ ọmọ Naijiria, amọ, awọn ọmọ ti oun bi si oke okun ko lanfaani lati jẹ ọmọ Naijiria.
Kemi to jẹ ọmọbibi orilẹede Naijiria sọrọ yii lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu oniroyin Fareed Zakaria lori ẹrọ amohunmaworan CNN.
Alaye lori bi yoo ṣe jẹ ko nira fawọn eeyan to n wa si UK lati ilẹ okeere bii Naijiria ni Kemi n sọ lori eto naa ti o fi mẹnu ba orilẹede Naijiria.
Kemi fi Naijiria ṣe apẹẹrẹ wi pe loootọ loun jẹ ọmọ Naijiria nitori nibẹ lawọn obi oun ti wa, ṣugbọn awọn ọmọ ti oun bi si UK ko lanfaani lati jẹ ọmọ Naijiria nitori oun jẹ obinrin.
Ọrọ yii fa awuyewuye paapaa julọ laarin awọn ọmọ Naijiria lori itakun ayelujara.
Idi niyii ti BBC Yoruba fi ṣe atupalẹ nnkan ti iwe ofin Naijiria sọ lori jijẹ ọmọ oniluu ati awọn to lẹtọọ labẹ ofin lati jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
Nnkan ti iwe ofin Naijiria sọ lori jijẹ ọmọ oniluu
Iwe ofin orilẹede Naijiria ti wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 1999 ṣe alakalẹ lori ẹni to le jẹ ọmọ Naijiria ati bi eeyan ti le di ọmọ Naijiria.
Lori ọrọ ti Kemi Badenoch sọ, ọna mẹta ni eeyan fi le jẹ tabi di ọmọ orilẹede Naijira – nipasẹ bibi eeyan si Naijiria, nipasẹ siṣe iforukọsilẹ lati di ọmọ Naijiria ati nipasẹ ki ijọba sọ eeyan di ọmọ oniluu.
Awọn alakalẹ yii wa ni abala 25, 26, ati ẹka 27 iwe ofin orilẹede Naijiria.
Wọnyii ni atupalẹ nnkan ti awọn abala iwe Naijiria naa sọ lori didi ọmọ oniluu:
Didi ọmọ Naijiria nipa ibi
Iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999, ṣalaye kikun pe awọn wọnyii ni ọmọ orilẹede Naijiria:
• Ẹni ti wọn bi si orilẹede Naijiria ṣaaju ayajọ ominira, ti eyikeyi ninu awọn obi rẹ tabi awọn to bi obi rẹ jẹ ọmọ bibi agbegbe kan ni Naijiria.
Ofin naa sọ pe eeyan ko le jẹ ọmọ Naijiria bi wọn ko ba bi awọn obi rẹ tabi awọn iya agba tabi baba agba rẹ si Naijiria.
Ẹnikẹni ti wọn bi si Naijiria lẹyin ominira, ti iya tabi baba rẹ, tabi awọn obi wọn jẹ ọmọ Naijiria.
Ẹnikẹni ti wọn ko bi si Naijiria, ṣugbọn ti eyikeyi ninu awọn obi rẹ jẹ ọmọ Naijiria.
Lakọkọ, ka fi ye ara wa pe ọmọ Naijiria ni Kemi Badenoch, pẹlu bo ṣe jẹ pe ọmọ Naijiria ni obi rẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko bi i si Naijiria.
Eeyan le di ọmọ oniluu nipasẹ iforukọsilẹ
Gẹgẹ bi abala kẹrindinlọgbọn, ipin kin-in-ni (1) iwe ofin ọdun 1999 bi wọn ṣe ṣatunṣe rẹ ṣe wi, eeyan le di ọmọ orilẹede Naijiria bi:
Ẹni naa ni iwa rere, o ni ọkan mimọ, o lero ire, to si ti bura lati jẹ olododo si orilẹede yii.
Obinrin yoowu to ba fẹ ọmọ Naijiria l'ọkọ.
Ẹnikẹni to ba ti dagba lọjọ ori ati ni gbogbo ọna, ti wọn bi si ẹyin odi, ṣugbọn ti awọn to bi obi rẹ jẹ ọmọ Naijiria.
Ni bayii, bi ẹnikẹni ba fẹẹ di ọmo Naijiria labẹ isọri yii, ẹni naa ni lati forukọsilẹ, aarẹ orilẹede yoo si buwọ lu u.
Igbesẹ yii ki i ṣe asare ṣe, o ni eto ati ilana lati tẹle.
Ajeji le di ọmọ oniluu ni Naijiria nini amuyẹ iwa Ọmọluabi
Abala 27 iwe ofin Naijiria la a kalẹ pe aarẹ le sọ ajeji di ọmọ oniluu ni Naijiria niwọn igba ti ẹni naa ba ti lawọn amuyẹ ti iwe ofin sọ.
Lara awọn amuyẹ ti ẹni naa gbọdọ ni, ni pe o ti gbọdọ gbe ni Naijiria fun bii ọdun mẹẹdogun.
Iru eeyan bẹẹ si tun gbọdọ bura pe oun yoo huwa bii ọmọluabi ni Naijiria.
Labẹ awọn abala mẹtẹẹta yii, awọn ọmọ Kemi Badenoch lanfaani lati jẹ ọmọ oniluu ni Naijiria nitori iya wọn ati awọn obi rẹ jẹ ọmọ Naijiria gẹgẹ bii abala 25 iwe ofin Naijiria ṣe la a kalẹ.
Koda, wọn tun le di ọmọ Naijiria nipa fifi orukọ silẹ bo tilẹ jẹ pe wọn ko bi wọn si Naijiria.
Amọ, niwọn igba to jẹ wi pe mama wọn ati awọn obi rẹ jẹ ọmọbibi Naijiria, awọn naa le forukọ silẹ lati di ọmọ oniluu ni Naijiria.
Eleyii ko ni ṣe bo ya obinrin tabi ọkunrin lo bi ọmọ silẹ okeere, iru awọn ọmọ bayii lẹtọọ lati di ọmọ oniluu ni Naijiria niwọn igba to jẹ wi pe ọmọbibi Naijiria ni obi wọn.
Ta ni Kemi Badenoch?
Orukọ abisọ rẹ ni Olukemi Adegoke, wọn bi ni ilu Wimbledon lọdun1980.
Ṣugbọn o dagba niluu Eko lorilẹede Naijiria ati America nibi ti iya rẹ ti jẹ olukọ.
O pada si ilẹ Uk ni ọmọ ọdun merindinlogun lati gbe pẹlu ọrẹ iya rẹ nitori ọrọ oṣelu ati kudiẹkudiẹ to ba Naijiria lasiko naa.
O gba orukọ Badenoch lẹyin to fẹ ọkọ rẹ, Hamish Badenoch, ẹni to wa lati orilẹede Scotland.
Kemi ṣapejuwe orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ilu ti ko si ofin, to si ranti gbogbo ohun to la kọja lasiko to gbe ni ilu Eko.
Lara awọn nnkan ti Kemi ti sọ nipa Naijiria to da awuyewuye silẹ ni ọrọ to sọ lasiko irinajo rẹ lọ si US, to ni ilu Eko jẹ ilu kan ti ko ti si nkankan to n sisẹ.















