Lóòtọ́ lèròǹgbà wà láti lọ sí APC tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èmi àti PDP ti lẹ̀pọ̀, a sì ti gbà láti ti Ààrẹ Tinubu lẹ́yìn fún sáà kejì – Gómìnà Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/x
Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun sọ pe oun ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ọṣun ti gba lati ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun saa keji ni ipo aarẹ Naijiria.
Gomina Adeleke sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara X rẹ ninu eyi to ti sọ pe oun atawọn atukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ ṣe ipinnu yii lẹyin ifikuluku ọpọlọpọ ọsẹ pẹlu awọn balaye, awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn iyalọja ati babalọja kaakiri ipinlẹ naa.
Bakan naa lo fi kun un awọn eeyan wọnyii pẹlu ti buwọlu oun gẹgẹbi oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun eto idibo ọdun 2026.
Ẹwẹ atẹjade ti wọn fi sita lẹyin ijiroro ati ifikuluku naa to waye ni ile ijọba ipinlẹ Ọṣun nilu Oṣogbo sọ pe lara awọn nnkan ti wọn ro mọ Aarẹ Tinubu lara ti wọn fẹ fi tii lẹyin bayii ni pe ọmọ onilẹ loun naa ni ipinlẹ Ọṣun.

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/x
Atẹjade naa fi kun un pe lootọ lọrọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC jade eleyi ti awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu APC ko fara mọ, ṣugbọn kii ṣe gomina Adeleke funrarẹ "lo gbe erongba ati dara pọ mọ APC dide"
"Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ko fara mọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, wọn kọ titori ifẹ ati ijolootọ si iṣakoso gomina , fẹ tẹle igbesẹ naa ni"
Lẹyin ipade wọn ọhun, awọn adarigbẹ oṣelu naa gba lati ṣe atilẹyin fun aarẹ Tinubu fun saa keji nitori "ipinlẹ Ọṣun ni ipinlẹ abinibi rẹ…"
Bakan naa ni wọn pinnu pe gomina Adeleke yoo dije fun ipo gomina lọdun 2026 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2026.















