Sẹ́nétọ̀ Natasha fi ẹsẹ̀ rìn wọ ilé aṣòfin l'Abuja lẹ́yìn tí àwọn agbófinró dá ọkọ̀ rẹ̀ padà

Natasha nigba to n fi ẹsẹ rin wọle

Oríṣun àwòrán, other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan ti fara han ni ile aṣofin agba orilẹede Naijiria ti gunlẹ si gbagede ileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria nilu Abuja.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn agbofinro atawọn ẹṣọ ile aṣofin apapọ ko jẹ ki ọkọ ti oun atawọn to tẹle e wa wọ wọle si gbagede ile aṣofin naa.

Ni kete ti awọn ẹṣọ da ọkọ rẹ duro la gbọ pe Natasha bọ silẹ ninu ọkọ to wa to si bẹrẹ si ni fi ẹsẹ rẹ rin wọ inu uleegbimọ aṣofin naa.

Aṣofin agba naa ti awọn alaṣẹ ile naa ti fofin de fun oṣu mẹfa pe ko gbọdọ wa sibi ijoko ile naa tabi ṣe ojuṣe aṣofin kankan ti lerileka pe oun yoo pada si ẹnu iṣẹ yala awọn alaṣẹ ile naa fẹ tabi wọn kọ lẹyin idajọ ti ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja gbe kalẹ laipẹ yii pe ijiya ti ile aṣofin agba fun Sẹnetọ Natasha lori ẹsun ti wọn fi kan an pọ ju fun ẹsun naa, nitori naa ki ile naa gba a laaye pada.

Amọṣa, nigba to gbiyanju lati pada si ẹnu iṣẹ rẹ nile aṣofina apapọ lọjọbọ to kọja, awọn ẹṣọ ile aṣofin naa ko gba a laaye lati wọle si gbagede ile aṣofin apapọ naa.

Awọn ẹṣọ ati agbofinro da ọkọ ayọkẹlẹ alawọ dudu ti Natasha wa ninu rẹ duro, bakan naa ni wọn da ọkọ to wa niwaju rẹ, ti Aisha Yesufu wa ninu rẹ duro pe wọn ko gbọdọ wọ ile aṣofin apapọ.

Nigba to ya lo kuku bọ silẹ ninu ọkọ rẹ to sir in ẹsẹ wọ inu ile aṣofin apapọ, toun tawọn ololufẹ rẹ.