Ṣé lóòótọ́ ni Muhammed ọmọ Babangida kọ̀ láti gba ipò tí Tinubu fún un? Àlàyé rèé

Aworan Muhammed Babangida ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, D/Olusegun/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin kan to lu ori itakun ayelujara pa ni irọlẹ ọjọ Aje ọjọ kọkanlelogun oṣu Keje lo sọ pe Muhammed Babangida to jẹ ọmọkunrin olori ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ibrahim Babangida, kọ lati gba ipo ti Aarẹ Bola Tinubu fun un.

Ipo ọhun ni a gbọ pe o jẹ ipo alaga banki eto ọgbin, BOA, ni Naijiria.

Ọpọ iwe iroyin lo gbe iroyin ọhun wi pe ọmọ Babangida kọ lati gba ipo ti Tinubu yan an si.

Bawọn kan ṣe n kan saara si Muhammed lawọn kan n bu ẹnu ẹtẹ lu u lori iroyin naa to sọ pe ọ kọ lati gba ipo ti aarẹ Naijiria yan an si.

Lẹta ayederu kan ninu eyi ti Muhammed ti sọ pe oun kọ lati gba ipo ti Tinubu yan an si naa ti tan kalẹ lori itakun ayelujara ki o to wa sọrọ wi pe irọ nla ni lẹta ọhun.

Aworan lẹta ayederu

Oríṣun àwòrán, D/Gov/X

Muhammed Babangida sọrọ lori iroyin to lu ori ayelujara pa

Ko pẹ ti iroyin naa lu ori ayelujara pa ni Muhammed sọrọ soke nigba to sọ pe iroyin ofege lawọn kan n gbe kiri wi pe oun kọ lati gba ipo ti Tinubu yan oun si.

Ọgbẹni Muhammed ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe irọ to jina si ootọ ni iroyin to sọ pe oun kọ lati gba ipo ti Tinubu yan oun si.

Muhammed ni awọn to n gbe iroyin yii kiri fẹẹ ṣi awọn araalu lọna ni, ati pe wọn tun fẹẹ bu ẹnu atẹ lu ijọba Tinubu to wa lode lo jẹ ki wọn maa gbe iroyin ofege kiri lori ayelujara.

Ọmọkunrin Babangida fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi lede wi pe oun ''Muhammed gba ipo ti Aarẹ Tinubu yan oun si gẹgẹ bii alaga banki to n ri si eto ọgbin.''

Muhammed tun sọ ninu atẹjade naa pe oun mọ riri ipo ti Aarẹ Tinubu yan oun si, ati wi pe oun dupẹ gan an lọwọ Tinubu fun igbagbọ to ni ninu oun.

Ọmọkunrin Babangida tun sọ ninu atẹjade to fi sita naa wi pe gbogbo awọn to n gbe iroyin ofege kiri ni yoo foju wina ofin.

O ni awọn yoo ṣe iwadii finifini lati mọ awọn to wa nidi iroyin naa, gbogbo wọn si ni idajọ ododo yoo waye lori wọn.

Bakan naa ni Muhammed tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa ṣe iwadii ati ayẹwo iroyin ti wọn ba ri lori itakun ayelujara daadaa ki wọn to gba a gbọ.

Iyansipo Muhammed Babangida jẹ ọkan lara oniruuru ipo ti Tinubu ti yan awọn eeyan si lori siṣe itaniji awọn ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ.