Lójú mi báyìí ni ọ̀rẹ́ mi tik ú, mo ń wòó bí bàlúù náà ṣe gba orí rẹ̀': akẹ́kọ̀ọ́ ṣàlàyé bí bàlúù iléeṣẹ́ ọmọogun ṣe j alu iléẹ̀kọ̀ọ́ rẹ̀

Farhan Hasan jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ileẹkọ naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Farhan Hasan ṣẹṣẹ pari idanwo rẹ tan to si fi kilasi silẹ lati lọ maa ba awọn ọrẹ rẹ kan fi ọrọ jomitoro ọrọ nigba ti baluu ijagun orilẹede Bangladesh j alu awọn kilasi kan ni ọgba ileẹkọ rẹ - to si gba ẹmi eeyan mẹtadinlọgbọn.

"loju mi korokoro bayii ni baluu to n jona naa n kọlu ile naa" ni alaye ti akẹkọọ Milestone School and College naa ṣe fun BBC News Bangla.

Awọn fọnran aworan to jade lati ileẹkọ naa lagbegbe ariwa olu ilu orilẹede naa, Dhaka ṣe afihan iru ina nla ati eefin to sọ, lẹyin ti baluu naa kọlu ile alaja meji.

O le ni aadọsan eeyan to farapa lasiko ti baluu naa ja.

Ileeṣẹ ọmọogun orilẹede naa ṣalaye pe baluu ijagun F-7 ni aṣiṣe kan lẹyin to gbera fun eto idanilẹkọ kan ni nnkan bi aago kan ọsan kọja iṣẹju diẹ. Awakọ baluu naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Flight Lieutenant Md. Taukir Islam, pẹlu wa lara awọn to ku.

Ibudo ijamba naa

Farhan, to ba BBC News Bangla sọrọ pẹlu aburo Baba rẹ ati Baba rẹ fi kun un pe: "Ọrẹ mi timọtimọ tie mi ati ẹ jọ wa ninu gbọngan idanwo, ku ni iṣoju mi bayii.

Ni iṣoju mi bayii…baluu naa gba ori rẹ kọja. Ọpọlọpọ awọn obi ni wọn n duro sibẹ nitori awọn akẹkọọ kekeke ti jade fun ọjọ naa, wọn si ti n jade lọkọọkan…baluu naa ko gbogbo wọn mọra lọ ni."

Olukọ kan ni ileẹkọ naa, Masud Tarik, ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe oun gbọ ibugbamu kan: "Nigba t imo wo ẹyin wo, ina ati eefin nikan ni mo ri… Ọpọlọpọ alagbats ati akẹkọọ lo wa nibẹ."

Bi awọn eeyan ṣe n sa kijokijo kiri, awọn ọkọ adoola ẹmi atawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n gbiyanju lati wa ọna lati gbe awọn to farapa atawọn oku jade ni ileẹkọ Milestone School and College naa.

Ko din ni ọgbọn ọkọ adoola ẹmi ambulansi lawọn eeyan ri ti wọn wọn n lọ kaakiri lati gbe awọn eeyan.

Arabinrin kan to n kaakiri lati beere nipa ọmọkunrin rẹ ṣalaye fun BBC News pe ọmkunrin oun pe oun lori ago lẹyin ti ijamba baluu naa ṣẹlẹ, amṣa oun o tii gburo rẹ lẹyin igba naa.

Awọn oṣiṣẹ n ṣiṣẹ idoola ẹmi nibi iṣẹlẹ ijamba baluu naa.

Oríṣun àwòrán, nur photo via Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko din ni aadọta eeyan, mọde ati agbalagba ti wọn ko lọ si ileiwosan fun ọgbẹ ina to jo wọn gẹgẹ bi dokita kan ni ile iwosan fun ijamba ina lorilẹede naa ṣe sọ.

Ọpọlọpọ awọn idile atawọn mọlẹbi awọn to farakaasa ijamba ina naa bii Shah Alam, ti ọmọ ẹgbọn rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹjọ, Tanvir Ahmed to ku ninu ninu ijamba baluu naa, ni wọn yabo ileewosan naa.

"Ọmọ aburo mi t imo fẹran pupọ wa ninu ile igbokusi bayii, Ọgbẹni Alam di ẹgbọ̀n rẹ, baba Tanvir, ti ọfọ ọmọ rẹ ko jẹ ko le sọrọ mu.

Ọpọlọpọ awọn to w ani ileewosan naa ni wọn jẹ awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹsan an si mẹrinla.

Wọn ti kede ọjọ iṣẹgun gẹgẹbi ọjọ idaro lorilẹede Bangladesh.

Muhammad Yunus, aṣiwaju ijọba fidihẹ lorilẹede Banladesh sọ pe, wọn yoo gbe "awọn igbesẹ to yẹ" lati ṣe iwadii ohun to ṣokunfa ijamba naa, ati lati "ṣeto iranwọ gbogbo to ba yẹ".

Muhammad Yunusu ṣalaye loju opo ayelujara X rẹ pe: "Akoko idaro nla leyi fun gbogbo orilẹede yii. Mo gba adura ilera kankan fun awọn to farapa. Mo si ti paṣẹ fun awọn alaṣẹ gbogbo, titi kan awọn ileewosan tọrọkan lati koju iṣẹlẹ yii bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

Aworan ibudo ijamba naa.

Wọn ti gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ lati ṣe wo iṣẹlẹ ijamba naa.

Gẹgẹbi atẹjade kan ti ileeṣẹ ọmọogun orilede naa fi sita ṣe sọ, awakọ baluu na gbiyanju lati yi ọwọ baluu naa kuro ni agbegbe ileegbe naa si awọn ibi ti eeyan ko pọ si lẹyin ti wahala de ba baluu naa. Wọn ni pe o ṣẹṣẹ gbera ni ibudo awọn ọmọogun ofurufu kan ni olu ilu orilẹede naa ni.

Bàálù ológun já lulẹ̀ sí ọ̀gbà ilé ẹ̀kọ́, èèyàn 19 kú, 164 farapa
Aworan ibi ti baalu ti ja lulẹ

Oríṣun àwòrán, AbdulGroni/Grik/Getty Images

O kere tan, eeyan mọkandinlogun lo ti padanu ẹmi wọn ti eeyan 164 si farapa lẹyin ti baalu ologun Bangladesh ja lulẹ si ọgba ile ẹkọ kan niluu Dhaka ti i ṣe olu ilu orilẹede naa.

Fidio ti ile ẹkọ Milestone School & College lapa ariwa Uttara ṣafihan bi ina ti sọ ti eefin si ru soke lẹyin ti baalu ọhun fori sọ ikle alaja meji.

Ileeṣẹ ologun sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita loju opo Facebook wọn pe nnkankan lo bajẹ ninu baalu ileeṣẹ ọmọgun naa lẹyin ti o gbera tan.

Baalu ọhun ni ileeṣẹ ologun sọ awọn ọmogun n lo o lati kọ wiwa baalu ologun.

Awakọ baalu naa wa lara awọn eeyan to ku ninu ijamba ọhun.

O le ni aadọta eeyan to fi mọ awọn ọmọde ti wọn gbe lọ sile iwosan lẹyin ti ina jo wọn lara nibi ijamba baalu naa.

Ọjọ ori awọn akẹkọọ to w anile ẹkọ naa bẹrẹ lati ọdun mẹrin si ogun ọdun.

Rezaul Islam to jẹ ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ naa sọ fun BBC pe oun ri bi baalu ti lọ fori sọ ile ẹkọ ọhun.

Masud Tarik, olukọ mii sọ fun Reuters pe oun gbọ ibugbamu, oun si ina ati eefin nigba toun wẹyin.

Akẹkọọ mii naa sọ pe oun ri baalu ọhun nigba to lọ fori sọ ile ẹkọ awọn.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọmogun ofurufu ṣe ṣalaye, awakọ baalu naa, Lt Md. Taukir Islam, kọkọ gbiyanju lati dari baalu naa si agbegbe ti eeyan ko ti pọ ju lẹyin ti nnkan ṣadeede bajẹ lara baalu naa.

Wọn ti ko awọn to farapa nibi ijamba ọkọ ofurufu naa lọ si ile iwosan nigba ti eto idoola ẹmi si n lọ lọwọ.

Ileeṣẹ ologun ti gbe igbimọ kan dide lati ṣe iwadii kikun lori ijamba ọhun.

Olori ijọba fidihẹ orilẹede Bangladesh, Muhammad Yunus ti sọ pe ijọba yoo ṣe iwadii lati mọ nnkan to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.