Ipò wo ni Gómìnà Katsina wà báyìí lẹ́yìn tó kàgbákò ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́ Àìkú?

Oríṣun àwòrán, Umar Dikko Radda
Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina ti sọ̀rọ̀ síta lórí ipò tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà wà lẹ́yìn tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Dikko Umar Radda ní ìjàmbá ọkọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ogúnjọ́, oṣù Keje, ọdún 2025.
Àtẹ̀jáde kan tí ìjọba Katsina fi léde ṣàlàyé lásìkò tí gómìnà Radda ń ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú Daura láti Katsina ní ọkọ̀ Golf kan yà bàrà kúrò lórí títì tó sì lọ kọlu ọkọ̀ gómìnà náà.
Adarí ètò ìpolongo fún fún gómìnà ìpínlẹ̀ Katsina, Maiwada Dammallam sọ fún BBC pé lẹ́yìn ìjàmbá náà ni wọ́n gbé Gómìnà Radda lọ sí ilé ìwòsàn Daura Hospital níbi tó ti kọ́kọ́ gba ìtọ́jú kí wọ́n tó gbe lọ sí ilé ìwòsàn Katsina Teaching Hospital níbi tó ti gba ìtọ́jú tó péye láti ri dájú pé kò sí wàhálà kankan.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina sọ pé àwọn àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Gómìnà Dikko Umaru Radda wà ní ìlera pípé.
Maiwada Dammallam fi kun fún BBC pé èèyàn mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ tí Gómìnà Radda wà nínú rẹ̀ lásìkò tí ìjàmbá náà wáyé, táwọn náà sì ti ṣe àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn.
"Gómìnà wà pẹ̀lú olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina, Alhaji Abdulkadir Mamman Nasir, olórí ẹkùn Kuraye àti Alhaji Shamsu Funtua lásìkò ìjàmbá náà.
"Kò sí ẹni tó farapa púpọ̀ jùlọ tó bẹ́ẹ̀ nínú wọn, èèyàn kan ló nílò kí wọ́n rán ojú ọgbẹ́ rẹ̀, gbogbo wọn ti kúrò ní Daura tí wọ́n sì ti wà ní Katsina báyìí," Maiwada Dammallam sọ.
Adarí ìpolongo sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Katsina tún tẹ̀síwájú pé gómìnà ti pinnu láti mú àdínkù bá iye ọkọ̀ tó ń tẹ̀lé lọ sí Daura láti ìgbà tí ààrẹ àná ní Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti jáde láyé nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lọ sí Daura padà sí Katsina láti ìgbà tí Buhari ti jáde láyé.
Ó ní "ọkọ̀ bíi mẹ́ta ni wọ́n gbé lásìkò ìrìnàjò náà nítorí láti ìgbà tí Buhari ti kú ni gómìnà ti ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Daura. Tí wọ́n sì ti mú àdínkù bá iye ọkọ̀ tó ń tẹ̀lé ààrẹ nítorí kí ìnáwó ọkọ̀ le dínkù."
Bákan náà ni wọ́n jiyàn àwọn ìròyìn tó gba orí ayélujára èyí táwọn kan ti ń gbé nípa ìlera Gómìnà Radda lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ náà.
Ṣáájú ni èèyàn kan fi sójú òpó X rẹ̀ pé Gómìnà Radda kán ní egungun lásìkò tó ní ìjàmbá ọkọ̀ láàárín Daura sí Katsina tó sì ti ń gba ìtọ́jú.
Ọ̀pọ̀èèyàn lójú òpó náà ni wọ́n ti ń bèèrè bóyá lóòótọ̀ ni ìròyìn náà tàbí ìròyìn òfégè, táwọn míì sì ń gbàdúrà kí ara gómìnà ọ̀hún tètè balẹ̀.















