Ṣé lóòótọ́ ni Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l'Abuja ti buwọ́ lu ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ tuntun 31? Ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan awọn aṣofin Naijiria nile igbimọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Laipẹ yii ni iroyin kan gbode, pe ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria ti buwọlu idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn tuntun.

Agbẹnusọ ile igbimọ naa, Yemi Adaramodu, ṣapejuwe iroyin naa bii ofege ati awuruju.

Adaramodu ṣalaye fun BBC News Pidgin, pe " Ile igbimọ aṣofin apapọ nikan ko le da ṣe idasilẹ awọn ipinlẹ, bẹẹ si ni aba naa tun gbọdọ gba ọna to pọ kọja fun atunṣe labẹ ofin. Koda, ipade ita gbangba (Public hearings) yoo wa ninu eto naa".

Bakan naa ni Adaramodu sọ pe lati da ipinlẹ tuntun silẹ, ida meji ninu mẹta awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin awọn ipinlẹ naa gbọdọ fi ọwọ si i.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu Keji ọdun 2025 yii ni ni ile igbimọ Aṣoju-ṣofin kede pe awọn gba aba kan to n pe fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn, ti yoo jẹ tuntun lorilẹede yii.

Alaga igbimọ naa, Benjamin Kalu, dabaa nigba naa pe ki wọn da ipinlẹ tuntun silẹ si i.

O ni eyi yoo wa lati Aarin-Gbungbun Ariwa, mẹrin yoo wa lati Ariwa-Ila-Oorun, marun-un lati Ariwa-Iwọ-Oorun, marun-un lati Guusu- Ila-Oorun, mẹrin lati Guusu-Guusu ati meje lati Guusu-Iwọ-Oorun.

Bi ile igbimọ Aṣofin agba ba gba aba yii wọle, Naijiria yoo ni ipinlẹ mẹtadinlaadorin (67) ti yoo ju aadọta ti America ni lọ.

Kí ni òfin Naijiria sọ nípa ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀?

Abala kẹjọ ofin orilẹede Naijiria lo fi aaye silẹ fun idasilẹ ipinlẹ tuntun.

Lakọkọ, o kere tan, ida meji ninu mẹta awọn to n beere ipinlẹ tuntun gbọdọ fọwọ si aba naa, iyẹn awọn to n ṣoju ipinlẹ ọhun nile igbimọ Aṣofin ati ti Aṣoju.

Lẹyin naa ni wọn yoo gbe aba naa yẹwo pẹlu ibo didi, o kere tan, ida meji aṣoju awon to n beere ipinlẹ tuntun yoo dibo, wọn yoo sọ pe awọn fẹ ipinlẹ tuntun loootọ.

Lẹyin eyi ni awọn kan lati ipinlẹ yoo buwọ lu u, awọn kan lati ile igbimọ Aṣoju naa yoo si fi ọwọ si i.

Igbẹsẹ to kẹyin ni ki ida meji ninu mẹta awọn aṣoju ile mejeeji buwọ lu u.

Àtúpalẹ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń dá àbá rẹ̀ náà rèé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarin Gbungbun Ariwa (NORTH-CENTRAL)

Ipinlẹ BENUE, lati Benue.

Ipinlẹ OKUN, lati Kogi.

Ipinlẹ OKURA, lati Kogi

Ipinlẹ CONFLUENCE, lati Kogi.

Ipinlẹ APA-AGBA, lati Guusu Benue (South Senatorial District).

Ipinlẹ APA, lati Benue.

Ipinlẹ kẹtadinlogoji ti wọn yoo pe ni olu ilu ilẹ wa, Abuja.

Ariwa- Ila-Oorun (NORTH-EAST)

Ipinlẹ AMANA, lati Adamawa.

Ipinlẹ KATAGUM, lati Bauchi

Ipinlẹ SAVANNAH,lati Borno.

Ipinlẹ MURI, lati Taraba.

Ariwa- Iwọ-Oorun (NORTH-WEST)

Ipinlẹ KADUNA TUNTUN ati ipinlẹ GURARA lati Kaduna.

Ipinlẹ TIGA lati Kano.

Ipinlẹ KAINJI lati Kebbi.

Ipinlẹ GHARI lati Kano

Guusu -Ila -Oorun ( SOUTH-EAST)

Ipinlẹ ETITI, ti yoo jẹ ikẹfa lati ẹkun yii.

Ipinlẹ ADADA, lati Enugu.

Ipinlẹ URASHI lati Guusu -Ila-Oorun.

Ipinlẹ ORLU lati Guusu- Ila-Oorun Naijiria.

Ipinlẹ ABA, lati Guusu-Ila-Oorun Naijiria.

Guusu-Guusu (SOUTH-SOUTH)

Ipinlẹ OGOJA, lati Cross River.

Ipinlẹ WARRI, lati Delta.

Ipinlẹ BORI, lati Rivers.

Ipinlẹ OBOLO, lati Rivers ati Akwa Ibom.

Guusu- Ila-Oorun (SOUTH-WEST)

Ipinlẹ TORU-EBE, lati Delta, Edo, ati Ondo.

Ipinlẹ IBADAN, lati Oyo .

Ipinlẹ LAGOON , lati Eko.

Ipinlẹ IJEBU, lati Ogun.

Ipinlẹ OKE-OGUN, lati Oyo.

Ipinlẹ IFE-IJESHA, lati Oyo ati Osun.

Ṣé Naijiria nílò ìpínlẹ̀ púpọ̀ sí i?

Gẹgẹ bi Ọmọwe Bello Maisudan, olukọ lẹka oṣelu nileewe giga Bayero University, Kano, ṣe wi, Naijiria ko nilo ipinlẹ tuntun si i.

Ọmọwe Maisudan ṣalaye pe nnkan mẹrin lo yẹ ki idasilẹ ipinlẹ tuntun da le lori.

Awọn nnkan naa bo ṣe ka wọn ni: Ibeere fun un, iye eeyan to wa lagbegbe kan, bi ilẹ wọn ṣe to ati bi wọn ṣe le da duro gẹgẹ bi ipinlẹ to.

Nipa ṣiṣe ibeere fun ipinlẹ tuntun, Ọmọwe Maisudan ṣalaye pe awọn eeyan le beere ipinlẹ tuntun, bi wọn ba ri I pe awọn ẹya to pọ ju wọn lọ n jẹ gaba lorii wọn.

Apẹẹrẹ iru ẹ gẹgẹ bo ṣe wi ni ipinlẹ Nasarawa ti wọn yọ lati ara Plateau, ati Bayelsa ti wọn yọ lati ipinlẹ Rivers.

Nipa bi wọn ṣe pọ to ati iye eeyan to wa nibi ti wọn ti n beere ipinlẹ tuntun, o gbọdọ kaju ẹ .

Wọn gbọdọ le da duro nipa owo, ki wọn ma maa duro de ijọba apapọ ki wọn too gbọ bukata ara wọn.

"Ti ẹ ba wo awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji (36) ti a ni bayii, meloo ninu wọn lo le da bukata ara wọn gbọ́ lai duro de ijọba.?"

Bẹẹ ni Ọmọwe Maisudan beere

"Loju iwoye temi, ti a ba tiẹ maa ṣe afikun ipinlẹ, ko gbọdọ ju marun-un lọ.''

O fi kun un pe alekun inawo ni alekun ipinlẹ jẹ fun ijọba apapọ.

O le fa kawọn kaa maa beere fun ipinya kuro lara orilẹede pẹlu, wahala rẹ pọ ju anfaani ibẹ lọ bi Maisudan tun ṣe sọ .