'Àwàdà kọ́ ni ẹgbẹ́ Shine-Shine Ladies, nnkan tí à n ṣe nínú ilé wa gan-an ni'

Àkọlé fídíò,
'Àwàdà kọ́ ni ẹgbẹ́ Shine-Shine Ladies, nnkan tí à n ṣe nínú ilé wa gan-an ni'

Laipẹ yii ni ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Shine-Shine Ladies gba ori ayelujara, nitori awọn fidio ti wọn n gbe jade, nibi ti wọn ti n kọ awọn obinrin nipa itọju ọkọ.

Ninu awọn fidio naa ni awọn obinrin ọhun ti ma n mura jatijati, lo awọn wiigi ti ko ni laari ati awọn nnkan miran ti ko jẹ ki irinisi wọn wu ni.

Ọpọ eeyan, koda to fi mọ awọn gbajumọ oṣere ati lori ayelujara lo bẹrẹ si ni ṣe fidio lati fihan pe ọmọ ẹgbẹ ni awọn.

Amọ ibeere ti awọn eeyan kan ṣi n wa idahun si ni pe, ṣe lootọ ni pe iru igbeaye bayii ni awọn obinrin naa n gbe ni tootọ tabi wọn kan n ṣe awada?

Eyi lo mu ki BBC News Yoruba tọ oludasilẹ ẹgbẹ Shine-Shine Ladies, Arabinrin Cecilia Olayanju, to si sọ nipa bi ẹgbẹ naa ṣe bẹrẹ, ati afojusun wọn.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Arabinrin Olayanju ṣalaye pe, larin adugbo ti oun n gbe ni awọn ti kọkọ bẹrẹ ẹgbẹ naa, ko to o di pe awọn pinnu lati wọ ori ayelujara ki wọn o le maa kọ ọpọ iyawo ile ni ẹkọọ.

O ni ninu ẹgbẹ Shine-Shine Ladies Club, awọn ọkọ awọn ọmọ ẹgbẹ lo n dan, kii ṣe awọn to jẹ iyawo.

"Ẹgbẹ irọrun fun ọkunrin ni, nitori pe ọkunrin lo yẹ ko maa gbadun.

"A ti fi ara wa silẹ fun awọn ọkọ wa."

Arabinrin Cecilia Olayanju sọ pe ipinnu awọn ninu ẹgbẹ naa ni lati ri daju pe gbogbo obinrin wa nile ọkọ.

Ki lo mu ko bẹrẹ ẹgbẹ Shine-shine Ladies?

Cecilia Olayanju

Arabinrin Olayanju ṣalaye pe irẹwẹsi ọkan to ba oun lasiko to ni awọn idojukọ ninu igbeyawo lo mu ki oun bẹrẹ.

O ni "ọna lati mu inu ara mi dun lo gbe mi de ori ayelujara Tiktok, nibi ti mo ti n ju oriṣiriṣi fidio sibẹ".

O ni lootọ ni awọn kan n bu oun amọ oun ṣakiyesi pe, awọn to nifẹ nnkan ti oun n ṣe pọ ju awọn ti ko nifẹ rẹ lọ.

"Ko wu mi ki n ki n kuro nile ọkọ rara, nitori naa ni mo ṣe n ṣe awọn nnkan ti mo n ṣe."

Tako igbagbọ ọpọlọpọ eeyan pe awada lasan ni awọn obinrin to wa ninu ẹgbẹ Shine-Shine Ladies n ṣe, oludasilẹ ẹgbẹ sọ pe awada kọ.

O ni igbeaye ti gbogbo awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ n gbe ninu igbeyawo wọn ni awọn fi n ṣe fidio, kii ṣe ere rara.

"Awọn eeyan o mọ pe mi o fi ṣe yẹyẹ.

"Ọna lati mu ki awa obinrin di ibujoko wa mu ni ẹkọ ti a n kọ."

Oju wo ni ọkọ rẹ fi n wo awọn nnkan to n ṣe?

Olori ẹgbẹ, Cecilia Olayanju sọ pe oun wa nile ọkọ ti oun fẹ.

"Ọdun 2028 ni mo ṣe igbeyawo, ọkọ mi si nifẹ si gbogbo awọn nnkan ti a n ṣe."

O ni ko si ọkunrin ti ko ni i nifẹ si nnkan ti awọn n ṣe.

Bakan naa lo sọ pe awọn ni ofin to pọ fun ọmọ ẹgbẹ.

Lara awọn ofin wọn ni pe wọn kii beere owo lọwọ ọkọ wọn, bẹẹ ni owo ti wọn fi n ṣe irun ori wọn ko gbọdọ ju ọọdunrun naira lọ.

O ni lootọ ni awọn eeyan le ma a fi oju were wo awọn nitori bi awọn ṣe n mura, amọ o tẹ awọn lọrun.

Arabinrin Olayanju tun sọ pe awọn yoo fi iwa ati iṣe naa le awọn ọmọ obinrin ti awọn bi lọwọ.