Ìjọba gbẹ́sẹ̀lé wíìgì àti ọṣẹ tí wọ́n fi ń bóra, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nicolas Negoce & Natasha Booty
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọpọ awọn eeyan ni Dakar, to jẹ olu ilu orilẹede Senegal ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn alaṣẹ ṣe fofin de lilo wiigi obinrin ati ọṣẹ ti wọn fi n bora nibi eto oge ṣiṣe kan nibẹ.
Ọjọ Aje ni ileeeṣẹ to n ri si ọrọ aṣa fi atẹjade kan lede ninu eyi ti adari ajọ Grand Théâtre de Dakar, Serigne Fall Guèye, buwọlu nibi to ti fi aṣẹ naa lede.
O ni eredi igbesẹ ọhun ko ṣẹyin akitiyan lati gbe aṣa ilẹ naa larugẹ ati lati daabo bo ẹtọ awọn obinrin.
Amọ awọn ti ko faramọ igbesẹ ọhun fi ẹsun kan Guèye pe niṣẹ lo n ṣọ awọn obinrin to si n fi ọrọ aṣa boju, eyii to mu ki ijọba gbẹsẹ kuro lori ofin naa lọjọ keji.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ẹgbẹ awọn to n ja fun ẹtọ awọn obinrin atawọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan sọ pe atẹjade naa fi han pe awọn obinrin ko ni ẹtọ kan naa bi awọn ọkunrin ni Senegal, paapaa pẹlu obinrin kereje to wa ninu ijọba Aarẹ, Bassirou Diomaye Faye.
Lori ayelujara, ọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun ti wọn si sọ pe o wa fun lati gbogun ti ẹtọ awọn obinrin.
Ọrọ naa tunbọ le koko si nitori ẹgbẹ oṣelu ti Serigne Fall Guèye ti wa, eyii ti wọn mọ bii ẹgbẹ to korira ijọba amunisin, aṣa ilẹ okeere to si n polongo igbeleke aṣa ilẹ adulawọ.
Ki wọn to yan an sipo olori ajọ aṣa, oun lo n lewaju ọrọ aṣa to si n polongo idapada aṣa ilẹ adulawọ ninu ẹgbẹ naa.
Awọn alatako rẹ n sọ pe o ti n fi ifẹ inu rẹ sinu ijọba lasiko ti ko yẹ ko fi si ibikankan.
Onimọ nipa ọrọ to n lọ kan, Fatoumata Ba sọ fun BBC pe "kii ṣe ọrọ wiigi tabi awọ ara la n sọ yii, ọrọ pe eeyan n lo agbara rẹ lori awọn eeyan to si n pa awọn ti ko ba gba tirẹ lẹnumọ ni."

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Lara awọn to sọrọ tako igbesẹ naa ni Henriette Niang Kandé to jẹ ajafẹtọ awọn obinrin bere lori ayelujara eredi ti irufẹ aṣẹ bẹẹ yoo fi waye.
O ni "ni ti irun ati wiigi wiwọ o yẹ ki a bere lọwọ adari ileeṣẹ aṣa boya nnkan to n sọ le ṣeeṣe.
"Ṣe a le sọ pe ki awọn ọkunrin dẹkun ati maa fa irun ori wọn nitori wọn jẹ apari? Abi a le ni ki wọn ma wọn kọla ti wọn n wọ ki ọrun wọn ba le gun si mọ?"
Ẹwẹ, awọn to fọwọ si igbeṣe naa, bo tilẹ jẹ wọn ko pọ to awọn to tako ko o, sọ pe igbesẹ ti adari ileeṣẹ aṣa ọhun gbe wa fun igbelarugẹ aṣa ilẹ wọn.
Guèye funra rẹ ni ohun ti oun ṣe ko ṣẹyin igbesẹ lati da aṣa ilẹ adulawọ to si sọnu pada paapaa ni ẹka eto oge, eyii ti aṣa igbalode ti n parẹ.
Sibẹsibẹ, awọn alatako rẹ ni irufẹ igbeṣe bẹẹ ti yoo kan sọ aṣa di ohun ti oju n ri lasan ni.
Onimọ nipa iwa eeyan lawujọ, Mame Diarra Thiam sọ fun BBC pe "ti eeyan ba fẹ da aṣa ilẹ adulawọ pada lootọ, o yẹ ko kọkọ bẹrẹ lati ibi ede, eto ẹkọ, eto ọrọ aje ati idajọ ododo – kii ṣe gbigbẹsẹle irun tabi ọṣẹ ti wọn fi n bora."
Nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun, Serigne Fall Guèye yi ofin naa pada lẹyin ti ọpọ araalu bẹrẹ si n fi oko ọrọ ranṣe si.
O ni erdi ti oun fi yi ofin ọhun pada ko ṣẹyin bi awọn araalu ko ṣe ni imọ ohun ti oun gbinyanju lati ṣe ni ibamu pẹlu afojusun ajọ naa.
Wayi o, igbesẹ lati yi ofin naa pada, tun ti bi awọn kan ninu bii olootu ijọba, Ousmane Sonko atawọ mii to ṣe atilẹyin fun lasiko ipolongo ibo.
Orilẹede Senegal jẹ ibi ti ọpọ eeyan ti n lo wiigi, ti wọn si n lo ọṣẹ atawọn ipara ti wọn fi n bora lai naani awọn akoba ti yoo ṣe fun ilera wọn.
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe wọn ti yi ofin naa pada, awuyewuye ti ofin ọhun kọkọ da silẹ ko tii tan nilẹ.















