Bàbá onílé dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn kàn pé ó pa akẹ́kọ̀ọ́ méjì tó jẹ́ ayálégbé rẹ̀, tó ti kọ́kọ́ jí gbé

Ọkunrin ti wọn so ọwọ rẹ mọ ẹyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu baba onile kan, Oladele Femi atawọn afurasi mii lori ẹsun ijinigbe ati ṣiṣekupa awọn akẹkọọ fasiti meji kan.

A gbọ pe akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba-Akoko, AAUA lawọn oloogbe náà, ki baba onile wọn to gbẹmi wọn.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal, sọ fun awọn akọroyin pe akẹkọọ ọlọ́dún keji ni awọn oloogbe naa, Abah John Friday, ẹni ọdun marundinlọgbọn ati ọrẹ rẹ obìnrin, Okah Andrel Eloho, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, onile naa lo ṣamọna bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọ ọhun gbé, ki wọn to gbẹmi wọn.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, NPF

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Adebowale ni inu oṣu Kẹfa ni wọn kọ lẹta si ọlọpaa pe awọn mọlẹbi awọn akẹkọọ naa n wa wọn, ki awọn oṣisẹ ẹka to n gbógun ti ìwà ijinigbe, 'Antikidnapping' to bẹrẹ iṣẹ.

Ninu iwadii wọn, ọlọpaa lọ si ọja igbalode Computer Village, to wa ni Ikeja, niluu Eko, nibi ti wọn ti ṣawari ẹrọ ilewọ iPhone 14 Pro Max to jẹ ti ọkan lara awọn akẹkọọ ọhun, Friday, eyii ti wọn ri lọwọ ọkunrin kan, Abdul Mohammed Mubarak.

Ọlọpaa ni "ninu iwadii, Mubarak sọ pe ọkunrin kan, Ojo Michael lo ta ẹrọ ilewọ naa fun oun, nigba ti a lọ fi ṣikun mu Micheal niluu Aramoko-Ekiti, a ri ọkọ ayọkẹlẹ Lexus RX 350 to jẹ ti ọkan lara awọn oloogbe naa lakata rẹ.

"Nigba ti a fi ọrọ wa lẹnu wo, Micheal sọ pe oun kopa ninu idigunjale, ijinigbe ati isekupani awọn olóògbé náà.

"Micheal sọ siwaju si pe, Oladele Femi, to jẹ baba onile ọkan lara awọn olóògbé náà, lo pinlẹ bi gbogbo igbesẹ naa ṣe waye."

Kọmiṣọna ọlọpaa sọ siwaju si pe N800,000 ni wọn gbe kuro ninu apo olóògbé to jẹ ọkan ninu awọn iṣuna lẹyin ti wọn ji wọn gbe.

Iwadii fi han pe Micehal fi ipa ba obinrin oloogbe naa sún, lẹyin to ri pe o da oju oun mọ ki wọn to gbẹmi awọn mejeji.

Ọlọpaa ti ṣawari oku obinrin akẹkọọ naa ninu igbo kan lẹba ilu Ode-Ekiti, wọn si ti gbe oku naa lọ sile igbokusi fun iwadii.