Njẹ́ o mọ̀ pé àwọn èèyàn kan le di aláìsàn tí ara wọn bá kan ara ẹlòmíràn? Wo bó ṣe kàn ọ́

Ọkunrin ati obinrin to joko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Christine Ro
    • Role, BBC Future
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Maura gbagbọ pe rọba idaabobo lo gba ẹmi oun la.

Obinrin naa to ti pe ẹni ọdun mẹtalelogoji bayii to n fi Ohio, nilẹ Amẹrika ṣebugbe sọ pe wahala naa bẹrẹ lẹyin ti oun le lọmọ ogun ọdun.

O ni "Mo ṣakiyesi pe oju ara mi n jo mi lẹyin ibalopọ lai si rọba idaabobo."

Ko sọ ọrọ naa fun ololufẹ rẹ lasiko naa amọ o duro ki ọkunrin naa lọ tan ki o to lọ wẹ.

O paarọ awọn oṣẹ ati ipara to n lo amọ pabo ni gbogbo igbiyanu rẹ lati yanju iṣoro ọhun ja si.

Lẹyinorẹyin, o pinya pẹlu ọrẹkunrin rẹ naa o si bẹrẹ ere ifẹ pẹlu ẹlomiran to fẹran lati maa lo rọba idaabobo.

Amọ lẹyin eyii ni wahala miran tun bẹrẹ.

O ni "lalẹ ọjọ kan lẹyin ti a ni ibalopọ tan ni mo ṣakiyesi pe ahọn mi bẹrẹ si n wu.

"Ololufẹ mi ri ohun to n ṣẹlẹ o si fi igbe ta, lẹyin naa lo fun mi ni 'inhaler' mi ti mo si bẹrẹ si n mi diẹdiẹ lẹyin naa."

Maura jẹ ẹnikan to n ba aisan semisemi finra atawọn nnkan mii, o gbagbọ pe rọba idaabobo ti wọn lo lo ja.

Ko mọ pe o ṣeeṣe ki eeyan ni aleji si atọ ọmọkunrin.

Bo tilẹ jẹ ko fi bẹẹ wọnpọ, awọn eeyan kan wa ti ara wọn ko fẹran lati maa kan ara ẹlomiran, bii bẹẹ kọ, awọn nnkan yoo sun si wọn lara, wọn si le dubulẹ aisan.

Amọ o ṣoro lati le sọ ohun to n ṣokunfa irufẹ aleji bayii.

Lati agọ ara

Lọpọ igba, oniruru idi ni ara ẹnikan fi le maa kọ lati kan ara ẹlomiran.

Fun apẹrẹ, agọ ara le maa gbe awọn nnkan oloorun didun kan kiri bii eyii ti eeyan n lo lẹyin ti wọn ba fa irun ara tan.

O ṣoro lati mọ ohun to maa n jẹ ki ara sun ti ẹnikan ba fara kan ẹlomiran.

Ara obinrin ọmọ ilẹ Amẹrika kan maa n sun to ba ti gboorun ara ọkọ rẹ.

Ọjọgbọn Sabine Altrichter, ni nile ẹkọ giga Kepler University Hospital ni Austria ni bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati fidi rẹ mulẹ, awọn eeyan kan to ni aisan 'mast cell disorders' gbagbọ pe ara wọn le maa sun latari oorun to n jade lati ara ẹlọmiran.

Oniruru eroja lo maa n jade lati are eeyan to le jẹ ki ara eeyan maa run, awọn eroja yii le jẹ awọn kẹmika bii 'toluene' ti won maa n ri lara epo robi ti won fi n ṣe ọda tabi ike.

Awọn mii maa n ko 'toluene' nigba ti wọn ba n fa 'glue' simu tabi lara siga mimu.

Ọwọ to n da yẹpẹ danu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn eeyan kan wa ti wọn ni arun ti orukọ rẹ n jẹ People Allergic To Me (PATM).

PATM ni igba ti ara ẹnikan ba n kọ ara ẹlomiran bii ki awọn eeyan maa semi tabi wukọ niwaju wọn.

Lọdun 2023, Yoshika Sekine, to jẹ olukọ ni fasiti Tokai ni Japan ṣe iwadii awọn eroja to n jade lara awọn to sọ pe awọn ni arun PATM. Ninu awọn gaasi bii ọgọrin ti wọn wadii rẹ, 'toluene' ni wọn ri to pọju lara wọn.

Gaasi naa jade lara wọn nigba mọkandinlogoji ju awọn ti ko ni PATM lọ.

Sekine sọ pe "niṣe ni wọn maa n mi toluene simu, eyii to maa n wọ inu ẹdọforo to si maa n pin ara rẹ sinu itọ wọn.

Ẹwẹ, awọn kan wa ti ara wọn maa n kọ oogun ara wọn funra wọn, amọ ara wọn kii kọ oogun ara ẹlomiran.

Awọn ohun to n jade lati inu omi ara

Ara eeyan tun le maa kọ awọn nnkan latari awọn omi to n jade lati ara irufẹ ẹni bẹẹ tabi ẹlomiran.

Nilẹ Gẹẹsi, obinrin kan ko le mi mọ lẹyin to ni ibalopọ pẹlu ọkunrin to jẹ ẹpa tan ṣaaaju ibalopọ wọn bo tilẹ jẹ ọkunrin naa ti fọ ẹnu ati ara rẹ lẹyin to jẹ ẹpa ọhun tan.

Yatọ si awọn nnkan ti eeyan jẹ, awọn iwadii kan ti fi han pe awọn eroja protein kan ninu omi ara le jẹ ki ara eeyan kọ ara ẹlomiran.

Irofẹ eroja protein yii le wa ninu atọ ọmọkunrin.

Aworan awọn to n fẹnukonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn itọju to wa

Lara awọn ọna ti wọn n gbiyanu lati fi tọju irufẹ aisan yii ni fifun ọkunrin ni abẹrẹ labẹ awọ ara rẹ.

Ọna yii naa ni wọn n gba toju awọn ọkunrin ti ara wọn n kọ atọ ara wọn.

Amọ ṣṣa, awọn onimọ sọ pe owo gọbọi ni wọn fi n ṣetọju rẹ, pupọ ninu awọn to n gba itọju ni ko si fẹ na irufẹ owo bẹẹ lati gba itọju ọhun.

Aworan lati ori oke giga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Onimọ kan, Benrstein atawọn akẹgbẹ rẹ ṣe sọ pe awọn ti n ṣe aṣeyọri lori awọn itọju kan eyii ti wọn ṣe laarin wakati meji pere.

Ninu alaye wọn, wọn ni awọn kọkọ ya atọ ọkunrin ati omi inu rẹ sọtọ, wọn po atọ naa pọ pẹlu awọn nnkankan ki wọn to fi sinu oju ara obinrin.

Wọn ni pẹlu itọju naa, obinrin ọhun yoo lanfani lati maa ni ibalopọ pẹlu ọkunrin naa lai si wahala kankan.

Lapapọ, awọn onimọ sọ pe imọ to wa nipa bi eeyan ṣe n pin omi ara lasiko ibalopọ ko tii to.

Onimọ kan ni fasiti Nicolaus Copernicus ni Poland, Marek Jankowski sọ pe oun ti ri ẹnikan ti omi inu oju ara rẹ le daabo bo o lọwọ irufẹ nnkan bayii amọ iwadii ijinlẹ ko tii pọ to lori rẹ.

O ni oun gbagbọ pe o ṣeeṣe ki oun ri awọn eeyan mii to ni irufẹ aisan yii lati gbiyanu lati tọju wọn.

Fun awọn ti ara wọn ko fẹran ati maa kan ololufẹ wọn, ewu nla ni fun ibaṣepọ awọn mejeji.

Maura gbagbọ pe bi ara rẹ ko ṣe fẹran atọ ololufẹ rẹ wa lara eredi ti wọn fi pinnu lati ma bi ọmọ kankan.

Lootọ ni Maura ati ololufẹ rẹ n lo rọba idaabobo bayii, amọ kii ṣe gbogbo awọn ti ara wọn n kọ nnkan bayii ni roba idaabobo yoo tẹ lọrun.