Bí Atiku àtàwọn míì ṣe fi PDP sílẹ̀, ipa wo ni yóò ní lórí ẹgbẹ́ náà?

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Dele Momodu/David Mark/Others
Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó tún fìgbà kan jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti kéde pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀.
Nínú lẹ́tà kan tó jáde sórí ayélujára lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje, ọdún 2025 ṣàfihàn pé Atiku Abubakar ti kọ lẹ́tà náà lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje.
Ó kọ lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní wọ́ọ̀dù Jada 1, ìjọba ìbílẹ̀ Jada ìpínlẹ̀ Adamawa.
Atiku ní ìdí tí òun fi ń kọ̀wé fipò sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà kò ṣẹ̀yìn àwọn ìyapa ẹnu tó ń wáyé láàárín òun àti ẹgbẹ́ náà.
"Ṣíṣe igbákejì ààrẹ fún sáà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti jíjẹ́ olùdíje sípò ààrẹ fún ìgbà méjì nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jẹ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí ìgbé ayé mi."
Abubakar Atiku tẹsiwaju pé ó pọn dandan fún òun láti pọ̀ sókèrè rajà látàrí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ náà èyí tó lòdì sí àwọn nǹkan tó dúró lé.
Ó sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún àǹfàní tí wọ́n fún òun láti ṣe igbákejì ààrẹ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́jọ àti àǹfàní tí wọ́n fún òun láti dupò ààrẹ ní ìgbà méjì.
"Ṣíṣe igbákejì ààrẹ fún sáà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti jíjẹ́ olùdíje sípò ààrẹ fún ìgbà méjì jẹ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí ìgbé ayé mi. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ yìí, ó jé ohun ìbànújẹ́ ọkàn fún mi láti ṣe ìpinnu yìí."
Àwọn èèkàn tó ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀
Ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Keje ni èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP míì, Dele Momodu tún kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Dele Momodu nínú lẹ́tà rẹ̀ fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan tó ń ṣiṣẹ́ tako ìjọba àwaarawa ti gba àkóso ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Lòdì sí Atiku tí kò ì tíì kéde ẹgbẹ́ òṣèlú tó fẹ́ darapọ̀ mọ́, Momodu ní òun ti lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC.
Momodu tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ́dún 2021 tó sì du tíkẹ́ẹ̀tì láti dupò ààrẹ fún ẹgbẹ́ náà lọ́dún 2022 sọ pé lẹ́sẹ̀kesẹ̀ ni ìkọ̀wé fí ẹgbẹ́ sílẹ̀ náà.
Láti ìgbà tí àwọn ààrẹ Bola Tinubu ti ń ko ara wọn jọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí láti ọ̀nà tí wọ́n fi máa gba àkóso Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́dún 2027 ni oníkálukú wọn ti ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sílẹ̀.
Ṣáájú ni David Mark tí òun náà jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tẹ́lẹ̀ kéde pé òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀ tó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Ní ọjọ́ tí àgbáríjọ àwọn alátakò ọ̀hún kéde ẹgbẹ́ òṣèlú ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n máa lò lọ́dún 2027 láti tako Tinubu ni David Mark gba káàdì gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ADC tí wọ́n sì yàn-án ní alága fìdí ẹ́ fún ẹgbẹ́ náà.

Oríṣun àwòrán, aatiku/Instagram
Ó dára bí àwọn tó fọwọ́ aago PDP sẹ́yìn ṣe ń kúrò – Makinde
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti sọ̀rọ̀ lórí bí Atiku Abubakar ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀.
Makinde tó tún alága fún àwọn gómìnà ẹkùn gúúsù lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ní bí Atiku ṣe fi ẹgbẹ́ náà sill kó ní ipa kankan lára ẹgbẹ́ àti pé ohun tó bá wuni ni ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Ó ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fi ààyè sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tàbí fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ nígbà tó bá wù wọ́n.
Ó fi kun pé ó dára kí gbogbo àwọn tí yóò máa fọwọ́ aago ẹgbẹ́ náà sẹ́yìn láti tètè fi ẹgbẹ́ sílẹ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, ó ní PDP kò rí ẹgbẹ́ náà bí èyí tó le ṣe ìdíwọ́ tàbí jẹ́ ìdúnkokò fún PDP.
Ipa tí ìgbésẹ̀ Atiku, Momodu, Mark le ní lórí PDP
Onírúurú awuyewuye ló ti ń wáyé lẹ́yìn tí Atiku kéde láti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ nítorí àwọn àìṣedédé kan tó ní ó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Gómìnà Seyi Makinde ti ìpínlẹ̀ Oyo, tí òun náà jẹ́ èèkàn nínú PDP sọ pé ìgbésẹ̀ Atiku náà kó ní nípa kankan lórí ẹgbẹ́ náà èrò àwọn onímọ̀ yàtọ̀ lórí èyí.
Onímọ̀ nípa òṣèlú, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dhikirulahi Yagboyaju wòye pé lábẹ́ ètò ìṣèjọba àwaarawa èyí tí Nàìjíríà ń lò lásìkò yìí, ó ní ẹ̀tọ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú ni láti kúrò nínú ẹgbẹ́ kan bọ́ sí òmíràn.
"Fífi ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀ jẹ́ ara ẹ̀tọ́ tí àwọn tó bá ń ẹgbẹ́ òṣèlú tán ní nìyẹn tó bá ti jẹ́ pé ètò òṣèlú tàbí ìjọba àwaarawa tí orílẹ̀ èdè kan yàn láàyò bí irú èyí tí Nàìjíríà yàn láàyò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí."
Ó ní ètò ìṣèjọba yìí fi ààyè gba ẹgbẹ́ tó pọ̀ tí ẹni tó bá sì ń ṣe òṣèlú le bọ́ láti ẹgbẹ́ kan sí òmíràn tí ohun tí wọ́n bá ń ṣe nínú ẹgbẹ́ kan kò bá tẹ lọ́rùn mọ́ tàbí bá ìgbàgbọ́ rẹ̀ mu.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Yagboyaju wòye pé àsọdùn ni pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò ní mọ báwọn èèkàn ẹgbẹ́ náà ṣe ń fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ míì.
Ó fi kun pé èèkàn gbòógì ni Atiku jẹ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, tó sì ti di àwọn ipò tó lágbára mú ní Nàìjíríà látara ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú bó ṣe ti ṣe igbákejì ààrẹ.
Ó ní Atiku ní àwọn èèyàn tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ tó máa tẹ̀le pẹ̀lú bó ṣe fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ èyí tí yóò mú àdínkpu bá iye ọmọ ẹgbẹ́ tí PDP ní.
"Atiku lórúkọ nínú ètò òṣèlú Nàìjíríà tó ń tọ́ka si pé bí wọ́n ṣe ń kúrò yẹn, wọ́n máa kúrò pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọn.
"Nǹkan tó ń jẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú ní agbára ni bí wọ́n bá ṣe ni ọmọ ẹgbẹ́ sí tó sì jẹ́ pé gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ló máa ń fẹ́ kí ọmọ ẹgbẹ́ wọn máa pọ̀ si."
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ní ẹgbẹ́ òṣèlú tí Atiku lọ darapọ̀ mọ́ ni yóò tún rí èrò si èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n ní agbára kún agbára.
Onímọ̀ náà ní báwọn èèyàn ṣe ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ bọ́ sí òmíràn, tí ẹgbẹ́ tí wọ́n bá sì darapọ̀ mọ́ náà bá ní agbára jẹ́ nǹkan tó dára fún Nàìjíríà nítorí ó máa jẹ́ kí ìjọba tó wà lórí ipò jí gììrì sí ojúṣe wọn.
"Tí ẹgbẹ́ alátakò bá ti ń lágbára, a jẹ́ kí ẹgbẹ́ tó wà ní ìjọba jókòó gírí láti ṣe nǹkan táwọn aráàlú bá ń fẹ́ nítorí wọn ò ní fẹ́ kí agbára bọ́ sọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ alátakò."
Iye ìgbà tí Atiku ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ bọ́ sí òmíràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí Atiku yóò máa ti ẹgbẹ́ òṣèlú kan bọ́ sí òmíràn. Kíkọ̀wé fi ẹgbẹ́ PDP sílẹ̀ rẹ̀ yìí tún jẹ́ abala mìíràn nínú ìrìnàjò òṣèlú rẹ̀.
Ìgbésẹ̀ tuntun rẹ̀ yìí ló mú jẹ́ ìgbà karùn-ún tó ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ bẹ́ sí òmíràn láti ọdún 1999 tí Nàìjíríà ti padà sí ìjọba alágbádá.
Ọdún 1999 ni wọ́n dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣùgbọ́n tí wọ́n yàn-án láti ṣe igbákejì ààrẹ Olusegun Obasanjo kí wọ́n tó búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
Ó ṣe igbákejì ààrẹ náà láàárín ọdún 1999 sí 2007.
- PDP sí Action Congress (AC), 2006
Ọdún 2006 ni Atiku fi PDP sílẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress lẹ́yìn tí aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín òun àti Olusegun Obasanjo lórí ẹni tó máa gba ipò ààrẹ.
Ó dupò ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú AC lọ́dún 2007 tó sì pàdánù sọ́wọ́ Umaru Musa Yar'Adua tí ẹgbẹ́ PDP.
- AC padà sí PDP, 2009
Atiku padà sí PDP lọ́dún 2009 lẹ́yìn tí aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín òun àti adarí ẹgbẹ́ òṣèlú AC nígbà náà, tó tún jẹ́ ààrẹ Nàìjíríà báyìí Bola Tinubu.
Ó gbìyànjú láti dupò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2011 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣùgbọ́n Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Goodluck Jonathan ni tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ já mọ́ lọ́wọ́.
- PDP sí All Progressives Congress, (APC), 2014
Ṣáájú ètò ìdìbò ọdún 2015 Atiku tún fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà náà.
Ó fẹ̀sùn kàn nígbà náà pé àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan ń wáyé nínú ìṣèjọba PDP lábẹ́nú ni òun fi fẹgbẹ́ sílẹ̀.
Ó díje du tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ APC láti dupò ààrẹ lọ́dún 2015 àmọ́ tó pàdánù sọ́wọ́ Muhammadu Buhari.
- APC padà sí PDP, 2017
Atiku tún padà sí PDP lọ́dún 2017 pẹ̀lú ẹ̀sùn pé APC kò ṣe àmúṣẹ àwọn ìlérí tí wọ́n ṣe fáwọn aráàlú lásìkò ìpolongo ìbò àti pé wọ́n ń fi ojú kéré àwọn kan nínú ẹgbẹ́.
Ó díje dupò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP lọ́dún 2019 àmọ́ tó tún pàdánù sọ́wọ́ Muhammadu Buhari ti APC.
Bákan náà ló tún rí tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ lọ́dún 2023 láti díje du ipò ààrẹ. Èyí ló fa awuyewuye láàárín òun àti àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP márùn-ún nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kan Atiku pé kò tẹ̀lé àdéhùn pé kí ipò agbára padà sí ẹkùn gúúsù Nàìjíríà.
- PDP sí ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun, 2025
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Atiku Abubakar kò ì tíì kéde ẹgbẹ́ òṣèlú tó fẹ́ darapọ̀ mọ́, ó ní òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀.
Ohun tó fa ìgbésẹ̀ tuntun náà bí Atiku ṣe sọ kò ṣẹ̀yìn ìfaǹfà tó ń wáyé nínú PDP.
Ọ̀pọ̀ ló ti ń sọ pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ni Atiku máa darapọ̀ mọ́ látàrí àgbáríjọ tó ti ń wáyé tẹ́lẹ̀.















