Ilé ẹjọ́ dá Ayo Fayose silẹ, wọ́n ni kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìkówójẹ ₦6.9 billion tí EFCC fi kàn án

Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose, maa lọ layọ ati alaafia, nitori ko jẹbi ẹsun ikowojẹ ₦6.9 billion ti ajọ EFCC fi kan an.

Adajọ Chukwujekwu Aneke to gbe idajọ naa kalẹ, ṣalaye pe ajọ EFCC ko ribi kankan lati fidi ẹsun fifi owo ilu ko dukia jọ, ki eeyan waa fi orukọ miran bo o loju (Money laundering) kan Fayose.

Bakan naa lo ni wọn ko fidi ẹsun naa mulẹ ti ile ẹjọ fi le ba a ṣe ẹjọ ju bẹẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2018 ni wọn kọkọ gbe Fayose lọ si kootu lori ẹsun kan naa.

Adajọ Mojisola Olatoregun lo n gbọ ẹjọ ọhun nigba naa, ki ajọ EFCC too beere fun ayipada, ti wọn si gbe e lọ siwaju Adajọ Aneke.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣíwájú

Gẹgẹ bi iwe ipejọ ti wọn fi fẹsun kan gomina Ekiti tẹlẹ naa ṣe wi, owo to to ₦1.2 billion ni Fayose ko sapo ni 2014.

Akọsilẹ ijọba sọ pe o lo owo naa lati polongo ibo fun ipo gomina to dije fun.

Bakan naa ni wọn lo gba miliọnu marun-un owo dọla ($5) lọwọ Obanikoro, lai gba owo naa lọna ẹtọ labẹ ofin.

Bẹẹ ni wọn tun fẹsun kan Fayose, pe o ko owo to ju ₦1.6 lọ sapo ara rẹ, lati fi ra awọn dukia jọ.

Awọn ileeṣẹ bii De Privateer Ltd ati Still Earth Ltd ni iroyin sọ pe Fayose ti ra awọn dukia naa, orukọ awọn eeyan mi-in lo si fi ra a .

Eyi tako ofin 'Money Laundering '(Prohibition) Act, ti ọdun 2011.

Apapọ ẹsun mọkanla lo gbe Ayodele Fayose de iwaju Adajọ Aneke.

Koko inu rẹ ni fifi ọna eru ko dukia jọ, ki eeyan si fi ẹtọ boju lẹyin kiko owo sapo ara ẹni ati ole jija.

Nígbà wo ni Fayose hùwà yìí?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe wi, lasiko ti gomina Ekiti tẹlẹ naa wa nipo gomina lo huwa naa.

Wọn fi kun un pe awọn owo ti wọn lo ji ko naa tun kan ọfiisi oludamọran pataki lori eto aabo tẹlẹ.

Lasiko igbẹjọ kan to waye logunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025, ile ẹjọ ko gbe idajọ kalẹ lẹyin to gbọ awijare Agbẹjọrọ agba ilẹ Naijiria, Kanu Agabi to gbẹnu sọ fun Fayose.

Agbẹjọro agba, Olalekan Ojo, lo ṣoju fun olujẹjọ keji, (Spotless Investment Limited); nigba ti Rotimi Jacobs toun naa jẹ agbẹọro agba Naijiria ṣoju fun ajọ EFCC.

Agbẹjọro fun Fayose ninu awijare rẹ, sọ fun kootu l'Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji yii, pe ẹjọ ti wọn pe onibara oun ko ri ẹsẹ mulẹ.

O ni Abiodun Agbele, ti wọn ni oun naa lọwọ ninu ẹsun yii, ko rọjọ niwaju kootu pẹlu awọn yoku.

Eyi to ni o mu ẹsun naa fuyẹ gẹgẹ.

O rọ kootu lati gba pe Ayo Fayose ko lẹjọọ jẹ, ki ile ẹjọ yọnda rẹ lati maa lọ lalaafia.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Aneke paṣẹ pe ki Ayodele Fayose maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia.