Àlàfo wo ni ikú Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Muhammadu Buhari yóò fi sí agbo òṣèlú ní Naijiria?

Aworan oloogbe, Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Muhammadu Buhari du ipo Aarẹ nigba ọtọtọ, o si lulẹ ko to wọle ni igba kẹrin
    • Author, Azeezat Olaoluwa, BBC News
    • Role, Senior Journalist Reporter
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O jọ bii pe iku aarẹ ana, Muhammadu Buhari ti fi alafo si aarin oṣelu ni Naijiiria, paapaa lagbegbe ariwa.

Ọpọ lo n reti ki awọn oloṣelu maa tiraka lati wọ bata ti Buhari bọ silẹ ni bayii ti wọn ti n murasilẹ fun eto idibo ọdun 2027.

Awọn eeyan agbegbe rẹ ko kan ri Buhari gẹgẹ bii oloṣelu nikan, wọn tun ri bii afara laarin awọn ti ko rọwọ họri atawọn eekan lawujọ.

Tinubu lo jogun atilẹyin awọn eeyan agbegbe naa lẹyin ipapoda Aarẹ nigba kan ri, Umaru Musa Yar'adua.

Wọn wo Buhari bii olootọ eeyan eyii ti awọn araalu fi fẹran rẹ lagbegbe naa, eyii lo tun mu ko ni ibo to le ni miliọnu mejila ninu ibo aarẹ ọdun 2011.

Buhari ṣaṣeyọri yii bo tilẹ jẹ pe owo ko pọ lọwọ rẹ lasiko eto idibo lọdun naa lọhun.

Pẹlu atilẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ati itan rẹ gẹgẹ bii ẹni ti ko fẹran iwa ajẹbanu, o bori ẹgbẹ oṣelu to wa lori aleefa lọdun 2015, o si fi idi aarẹ igba naa, Gooduck Jonathn janlẹ pẹlu ibo ti iye rẹ le n miliọnu meji abọ.

Buhari lasiko ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Buhari ni oloṣelu akọkọ to fidi Aarẹ to wa lori alefa janlẹ ni Naijiria

Bo tilẹ jẹ pe saa rẹ akọkọ ko tẹ araalu lọrun lori ọwọ to fi mu eto abo to mẹhẹ, eto ọrọ aje ati ọrọ iwa ibajẹ, o tun bori ibo Aarẹ lọdun 2019.

Buhari tun ṣe bii akin ṣaaju ibo ọdun 2023 nigba to kọ lati fa ọwọ ẹnikẹni soke gẹgẹ bi aayo to gbọdọ gba agbara ijọba lẹyin oun.

O sọ nigba naa pe ẹnikẹni to ba bori ibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu APC loun yoo ṣatilẹyin fun.

Lori igbesẹ yii, Aliyu sọ pe "o daadaa bi ko ṣe fi sibi kankan. Ko fẹ da si ọrọ ti ko kan an."

Buhari ko dakẹ lori bo ṣe fẹ lo akoko rẹ lẹyin saa rẹ, o ni oun ko fẹ ki ẹnikẹni yọ oun lẹnu.

Eyii ni ko ṣe jẹ iyalẹnu pe lẹyin to gbe agbara ijọba fun Tinubu tan lo pada si ilu ibi rẹ nipinlẹ Katsina, ti ọpọ araalu ko si gburo rẹ mọ.

Ọjọgbọn Aliyu sọ siwaju si pe "iku rẹ yoo fi alafo pupọ silẹ. A ri bo ṣe lọ si Daura, ọpọ eeyan lo tẹkọ leti lọ sibẹ lati lọ maa gba itọni lọwọ rẹ."

Amọ nipinlẹ Kano, Aliyu ni Buhari ko ni le fi alafo kankan silẹ nibẹ.

Olootọ eeyan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin eto idibo ọhun lo di alagbara oloṣelu ati adari ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC.

Nigba to n gba ọpa aṣẹ Naijiria lọdun 2015, o ni "mo wa fun gbogbo eeyan, mi o si wa fun ẹnikẹni" eyii to fi n paṣamọ si awọn oloṣelu pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ inu rẹ lagbo oṣelu Naijiria.

Nigba to n sọrọ lori ohun ti Buhari sọ, Ọjọgbọn Khalid Aliyu, to jẹ akọwe ajọ Jama'atu Nasril Islam, JNI, ni "ọrọ rẹ mi gbogbo agbo oṣelu titi, eyii to mu ki pupọ ninu wọn sa fi ilu silẹ lọ ilẹ mii.

Ni bayii ti wọn yo sin oku Buhari to jẹ eekan oloṣelu ni ariwa Naijiria, ọpọ lo n bere ipa ti iku rẹ yoo ni lara ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo ọdun 2027.

Wọn n woye pe ṣe Bola Tinubu yoo le ri atilẹyin awọn eeyan ariwa lai si Buhari laye mọ.

Eyii n tumọ si pe awọn oloṣelu atawọn alagbara oṣelu ni iṣẹ to pọ lati ṣe lati pa alaafo ti Buhari fi silẹ rẹ.

Ni bayii ti "Sai Baba" ti di ẹni ana, o da bii pe ẹgbẹ oṣelu APC ti padanu ju ẹnikan ṣoṣo lọ, ere ije ọdun 2027 si le nira fun wọn ju bo ṣe yẹ lọ.

Buhari ati Bola Tinubu to gba agbara lẹyin rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ oṣelu APC gba agbara lẹyin ti PDP ti ṣejọba fun ọdun mẹrindinlogun gbako

O ku sọwọ awọn alatako lati di alafo ti Buhari fi silẹ amọ ewo ninu wọn to lagbara lati tẹri si?

Ọjọgbọn Aliyu sọ pe awọn eeyan kan wa ti wọn le fẹ tọ ipasẹ Buhari, oloogbe ọhun si le nifẹ si titọ iṣisẹ awọn ọmọlẹyin rẹ ninu oṣelu.

Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, Aliyu sọ pe yoo ṣoru fun araalu lati gbagbe ẹni to ba gbele aye ṣe rere.

O ni "iku Buhari ti fun awọn to fẹ da bii tirẹ ni ipenija nla nitori bata ti wọn fẹ ti ẹsẹ bọ ṣugbọn a ko tii ri ẹnikẹni to le da bii tirẹ."

Naijiria ti wọ ipele tuntun bayii ti yoo ṣe abajade ibi ti oṣelu ọdun 2027 le ja si, o si da bi pe gbogbo oju lo wa lara ariwa Naijiria.

Ere ije lati jẹ aayo awọn eeyan iha ariwa bii ti Buhari ti wa bẹrẹ bayii pẹlu iku rẹ.

Aliyu pari ọrọ rẹ pe "ẹni to ba fẹ jẹ adari ti wọn ko ni gbagbe gbọdọ mọ pe Buhari kii ṣe ẹni to gbajumọ latari ọrọ to ni.

"Owo ko le ra orukọ rere ati ifẹ araalu, iwa rere ati ifaraẹnijin Buhari si araalu lo mu ki wọn fẹran rẹ.