Mọ̀ nípa 'Imole Millionaire Draw', lótò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fẹ́ fi kojú ìṣẹ́ àti òṣì

Àwòrán àwọn nọ́mbà tẹ́tẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti sàlàyé ìdí tí wọ́n fi ń ṣàtìlẹyìn fún iléeṣẹ́ lótò kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀, èyí tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní 'Imole Millionaire Draw'.

Nígbà tó ń bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹrìndílọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025, Kọmíṣánnà fún ọ̀rọ̀ okoòwò ní ìpínlẹ̀ Osun, Bunmi Jenyo ṣàlàyé pé agbékalẹ̀ iléeṣẹ́ aládani tí ìjọba ń ṣe àtìlẹyìn fún ni iléeṣẹ́ náà.

Jenyo ní ìdí tí ìjọba Osun fi ṣe àtìlẹyì fún ètò náà ni láti mú àdínkú bá ìṣẹ́ àti òṣì ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní ètò lótò tí iléeṣẹ́ náà fẹ́ máa gbé kalẹ̀ yóò máa pèsè ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó fáwọn èèyàn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ èyí ló mú kí ìjọba ṣe àtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ àti pé iléeṣẹ́ náà ní àkọ́ọ́lẹ̀ tó dára láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó wá dá okoòwò sí Osun.

"Gbogbo ìlànà àti ìgbésẹ̀ tó bá máa mú ìgbéga bá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun ni ìjọba ti ṣetán láti ṣe àtìlẹyìn fún."

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí pé ètò náà ń ṣe àgbéga fún tẹ́tẹ́ títa, Kọmíṣánnà náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀èdè tó ti gòkè àgbà bíi Amẹ́ríkà àti Yúróòpù ni wọ́n ní àwọn iléeṣẹ́ lọ́tírì tó ń mú ìgbéga bá ètò ọrọ̀ ajé wọn.

"Iléeṣẹ́ lọ́tírì tó wà ní Britain máa ṣe àtìlẹyìn fáwọn àjọ ẹ̀sìn, ètò eré ìdárayá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó dàbí ṣíṣe padà fún àwùjọ ni.

Jenyo fi kun pé gbogbo ìlànà tó yẹ nípa ṣíṣe lọ́tírì ni iléeṣẹ́ náà ti tọwọ́bọ àdéhùn láti ṣe ló jẹ́ kí àwọn fún láàyè láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbésẹ̀ wọn.

Ṣáájú ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ 2AG Nigeria Limited, Ladi Adebayo ti kéde Ìdásílẹ̀ lọ́tìrì náà lábẹ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí okoòwò ní ìpínlẹ̀ Osun.

Èròńgbà ìdásílẹ̀ lọ́tìrì náà gẹ́gẹ́ bí Adebayo ṣe sọ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò náà tó wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Keje ni láti ri kojú ìṣẹ́ àti òṣì.

Ó ní èèyàn mẹ́rin ni yóò máa di ọlọ́rọ̀ látara ètò ní oṣooṣù.

Ó fi kun pé àwọn kò gbé ètò náà kalẹ̀ fún ìdárayá lásán bíkòṣe láti ṣe ìrónilágbára fáwọn aráàlú lójúnà àti mú ìgbéga bá bí ìpínlẹ̀ Osun ṣe ń pawó wọlé lábẹ́nú.

Báwo ni ètò náà yóò ṣe máa wáyé?

Àwọn èèyàn tó ń wo nọ́mbà lọ́tírì bóyá wọ́n jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọn yóò máa ṣe àfihàn ètò náà lórí àwọn ìkànnì ayélujára iléeṣẹ́ náà lórí Youtube, Facebook, Instagram, àti TikTok ní aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

₦500 ni àwọn tó bá fẹ́ kópa nínú ìdíje náà yóò máa san èyí tó le mú wọn jẹ́ ẹbùn lóríṣiríṣi.

Mílíọ̀nù kan náírà (₦1 million) ni ẹni àkọ́kọ́ yóò jẹ, tí ẹni tó bá gbé ipò kejì yóò sì jẹ ẹgbẹ́rùn lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (₦500,000).

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Àádọ́ta lé ní igba (₦250,000) ni ẹni tó bá gbé ipò kẹta yóò gbà ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Ìlànà mímú nọ́mbà pẹ̀lú ẹ̀rọ ìgbàlódé ni wọn yóò máa fi mú ẹni tó bá jẹ lójúnà àti ṣe àrídájú rẹ̀ pé ètò náà kò ní èrú kankan nínú.

Ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2025 ni wọ́n ní ètò náà máa gbérasọ tí wọ́n sì ti ń bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn jíròrò láti ṣe ìpolongo tó tọ́ lórí rẹ̀.

Kí ni ìyàtọ̀ lọ́tìrì àti tẹ́tẹ́ títa?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìtumọ̀ tẹ́tẹ́ títa kò ju kí èèyàn fi nǹkan ẹyọ̀kan sílẹ̀ kó sì fẹ́ fi gba ìlọ́po púpọ̀ rẹ̀ padà.

Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá jẹ, wọn yóò fún ni ìlọ́po owó tó fi ta tẹ́tẹ́ náà, bí kò si jẹ, owó tó fi ta tẹ́tẹ́ ọ̀hún wọgbó nìyẹn.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ náà ni ọ̀rọ̀ lọ́tírì náà rí nítorí èèyàn fẹ́ fi owó kékeré jẹ nǹkan ńlá ni àti pé bí èèyàn kò bá jẹ, yóò pàdánù owó tó fi ṣe lọ́tìrì náà.

Ìrònú pé àwọn yóò jẹ ìlọ́po owó ló máa ń wà lọ́kàn ẹni tó bá ń ta tẹ́tẹ́, wọ́n kì í fẹ́ fi ọkàn síbi pé àwọn le má jẹ, èyí ló sì máa ń jẹ́ kí wan tẹ̀síwájú nínú ìwà náà.

Bákan náà bí èèyàn bá jẹ owó ńlá níbi tẹ́tẹ́, ẹni náà kò ní sọ pé ó tit ó òun, yóò túnbọ̀ máa ta si pẹ̀lú èròǹgbà pé òun le jẹ si.

Bẹ́ẹ̀ náà lórí fún àwọn tó ń ta lọ́tìrì nítorí ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń fẹ́ ta ní ọ̀pọ̀ ìgbà pẹ̀lú èrò pé tí orúkọ àwọn bá pọ̀ nínú àwọ̀n, ó ṣeéṣe kí àwọn jẹ.

Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ jé ní Nàìjíríà, Bisi Iyaniwura ṣe sọ, ó ní kò sí ìyàtọ̀ kan gbòógì láàárín lọ́tìrì àti tẹ́tẹ́.

Ó ní ọ̀rọ̀ lọ́tìrì àti tẹ́tẹ́ dàbí ọmọ ìyá àti bàbá kan náà tí wọ́n fún ní orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni.

Iyaniwura ṣàlàyé pé ìjọba ìpínlẹ̀ lábẹ́ òfin, ní ẹ̀tọ́ láti gbé ìlànà kalẹ̀ lórí ètò lọ́tìrì àti tẹ́tẹ́ títa àmọ́ wọn kò gbọdọ̀ gbé iléeṣẹ́ lójú gẹ́gẹ́ bí ààyò nítorí àwọn iléeṣẹ́ míì táwọn náà ń ṣe irúfẹ́ iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.

Ò wòye pé ìjọba nílò láti ṣe àmójútó báwọn èèyàn ṣe ń ta tẹ́tẹ́ nítorí ó ti di bárakú fún ọ̀pọ̀ èèyàn, tó sì ń sọ wọ́n di ẹdun arinlẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní Nàìjíríà ni kò fẹ́ ṣiṣẹ́ mọ́ nítorí pé wọ́n ń wá ọrọ̀ òjijì tó sì jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun nílò láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà tó yẹ láti ri pé wọ́n ṣàmójútó ètò náà dáadáa.

"Kìí ṣe nǹkan tó yẹ kí ìjọba gbárùkù tì, tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti ṣe àwọn òfin láti de àwọn iléeṣẹ́ tó ń gba lọ́tìrì yẹn.

"Ó ní láti ní gbèdéke iye tí èèyàn kan gbọ́dọ̀ lè ta lójúmọ́."

Onímọ̀ náà sọ pé gbígbé àwọn ìlànà báyìí kalẹ̀ kò ní jẹ́ káwọn èèyàn ṣi ètò náà lò ju bó ṣe yẹ lọ.