Wo ohun tó n ṣẹlẹ̀ nínú ọpọlọ àwọn tó n ta tẹ́tẹ́

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria Stories
Ọkan lati ma ṣe ta igbesẹ akikanju nu. Idaniloju wi pe lasiko yii, anfaani nla yoo wa. Aile kora ẹni nijanu nipa nina owo. Aile ronu nipa bi gbese ṣe n korajọ.
Awọn nnkan wọnyi lo ṣee ṣapejuwe ohun to n ṣẹlẹ si awọn ti tẹtẹ tita ti jẹ gaba lọkan wọn, bii tẹtẹ bọọlu – ohun ti wọn ṣapejuwe rẹ ninu iwe ilera gẹgẹ bii aaganna tẹtẹ, iyẹn gambling disorder.
Ẹgbẹ awọn dokita to n ṣe itọju ọpọlọ l’Amẹrika, American Psychiatric Association sọ pe “ni gbogbo igba ni aworan naa maa n farahan ninu aye awọn to n ta tẹtẹ.”
O ran wọn leti pe iṣoro naa kọja bẹẹ, to fi jẹ jẹ bo ṣe n ṣakoba fun mọlẹbi ẹni to farajin fun tẹtẹ laayo, bẹẹ naa lo tun ṣakoba fun agbegbe.
Ati pe ki lo n lọ gangan ninu ọkan ẹni to ni aagannan tẹtẹ? Ki lo de ti awọn to fi ara jin fun tẹtẹ ṣe maa n ni iru aisan yii – ti awọn miran kii sii ni? Ati pe ki ni wọn le ṣe lati koju ipenija yii?
BBC ti kan si awọn akọṣẹmọṣẹ lati beere ibeere, ti wọn si ti fi awọn idahun wọn sita ati awọn ibeere miran to fi ara pẹ ẹ.
Ṣiṣe agbeyẹwo ọpọlọ ẹni to farajin fun tẹtẹ
Dokita ọpọlọ Lucas Spanemberg, oniwadii ijinlẹ nile ẹkọ ọpọlọ ti Brain Institute of the Pontifical Catholic University of Rio Grande do Sul (PUC-RS), tọka sii wi pe ko si iyatọ laarin ẹni to farajin fun tẹtẹ tita ati awọn to n mu ọti, kokeeni ati awọn egboogi oloro miran, ati pẹlu awọn to fẹran ibalopọ, ounjẹ, rira ọja ati bẹẹbẹẹlọ.
“A ni agbegbe kan ninu ọpọlọ ti a n pe ni ‘limbic system’, nibi ti gbogbo ohun to n ṣiṣẹ ninu ara ti parapọ. Wọn si maa n jẹ ka ni imọlara,” ohun ti dokita yii sọ ree.
Ohunkohun to ba n fun wa ni idunnu – nini ibalopọ, jijẹ ounjẹ ti a fẹran, sisunmọ awọn ti a fẹran, abbl. – maa n fa ki ohun ti a n pe ni ‘neurotransmitter dopamine’ sọkalẹ ni agbegbe naa.
Spanemberg ṣalaye pe kini naa ṣe pataki pupọ fun igbe aye wa ati bi awọn eeyan ati ẹya kan yoo ṣe pẹ loke eepẹ to.
O tẹsiwaju pe oriṣiriṣi nnkan lo maa n wọnu ọpọlọ awọn eeyan lọ, to si jẹ agbegbe to n sọrọ nipa rẹ lo n ṣe awọn iṣẹ naa.
O ni awọn kẹmika kan wa ti wọn n ṣiṣẹ ninu ọpọlọ, to jẹ pe awọn ni wọn n fa ki eeyan yan ohun kan laayo lati maa ṣe, tabi fẹran, ti yoo si maa ṣe e loorekoore.
“Ni ṣisẹ-n-tẹle, eeyan le bẹrẹ sii dawọ ohun to mn mu ere dani duro, lati mu ki kẹmika naa ṣiṣẹ ninu ọpọlọ, fun ohunkohun to ti jẹ gaba ninu ọpọlọ lati gba agbegbe naa,” Spanemberg tẹnumọ ọrọ rẹ.
Agbegbe inu ọpọlọ to ni ojuṣe lati yanju iṣoro...
Dokita Vinícius Andrade, lati inu ẹgbẹ Addictions Commission of the Brazilian Association of Psychiatry, jẹ ko di mimọ pe awọn agbegbe miran ninu ọpọlọ ti wọn ti fi ara jin fun ‘limbic system’ naa ni ipa ti wọn n ko ninu aaganna tẹtẹ.
“A le ri agbegbe kan ti a n pe ni ‘prefrontal cortex’, to wa niwaju ori wa, ohun lo si n ṣiṣẹ fun ipinnu ṣiṣe ati yiyanju iṣoro,” ohun ti akọṣẹmọṣẹ to tun tun jẹ amugbalẹgbẹ oniṣẹgun oyinbo ni Impulse Disorders Outpatient Clinic of the University ti São Paulo (USP) tọka si ree.
Bakan naa lo tun sọ pe imọ ẹkọ kan tọka si ohun ti wọn n pe ni ‘amygdala’, eyii ni wọn le sọ pe o n fa wahala ṣise.
Ni ojuṣe, awọn iyatọ yii lo ma n jẹ ko ṣoro lati ronu to dara nipa boya lati ko owo sori tẹtẹ ti ko si idaniloju wi pe yoo jẹ, lati ri ere ọjọ iwaju.
Gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ naa ṣe ṣalaye, ohun to n ṣe ṣẹlẹ yii lo nii ṣe pẹlu bi eeyan ba ṣe fi ara silẹ sii.
Ki lo de ti awọn eeyan ṣe n ṣaisan tita tẹtẹ - ti awọn miran kii ṣe
Agbeyẹwo apilẹkọ ti wọn gbe jade lọdun 2019 ninu iwe ti wọn pe ni ‘Nature Reviews’, eyi ti awọn akọṣẹmọṣẹmọṣẹ lati Yale University nilẹ Amẹrika ati awọn ile-ẹkọ giga lawọn orileede bii Canadia ati Australia buwọ lu ṣe akọsilẹ pe ida 0.4 ati 0.6% ni awọn eeyan to n ni aisan tẹtẹ tita.
Wọn ni awọn nọmba naa lo ni ṣe pẹlu iwadii. Ni Hong Kong, akọsilẹ naa jẹ bii ida 1.8%, nigba to si le ju bẹẹ lọ bii 2% ni Australia.
Ni apapọ, ajọ World Health Organization (WHO) gba wi pe eyan kan ninu ọgọrun eyan lo n koju iṣoro aisan tẹtẹ tita.
Ṣugbọn bawo wa ni ti awọn to n ta tẹtẹ lawọn orileede miran lagbaye ni gbogbo igba? Njẹ awọn nnkan wọnyi naa n ṣẹlẹ laarin wọn?
Bẹẹni idahun naa. Dokita Hermano Tavares, to jẹ alakoso agba ni Pathological Gambling Outpatient Clinic ati Impulse Disorders Program ni ile ẹkọ Institute of Psychiatry ti Hospital de Clínicas de São Paulo, ranti iṣẹ ti wọn ṣe lọdun mẹwaa sẹyin, eyi to ṣafihan ida mejila si mẹẹdogun awọn ọmọ Brazil to n ta tẹtẹ.
Ki lo n ṣapejuwe aisan tẹtẹ tita
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni American Psychiatric Association ṣalaye pe wọn le ṣe ayẹwo yii lara eeyan kan nigba ti wọn ba kofiri pe o ni awọn aleebu bii:
Ironu atigbadegba nipa tẹtẹ tita (bii ko maa ranti awọn tẹtẹ to ti ta sẹyin ati awọn eyi to n gbiyanju lati ta lọjọ iwaju);
Nilo lati ta tẹtẹ, pẹlu afikun owo to fi n ta tẹtẹ ọhun;
Nini iporuru ọkan ati aile kora ẹni nijanu nipa tita tẹtẹ;
Aini isinmi tabi aile kora ẹni nijanu lati dẹkun tita tẹtẹ;
Riri tẹtẹ tita gẹgẹ bii ọna lati bọ kuro lọwọ iṣoro kan tabi wahala;
Lẹyin to ba ti padanu owo tabi nnkan gidi sinu tẹtẹ, yoo maa ronu lati tubọ tẹsiwaju lati le gba awọn nnkan naa pada;
Ọna lati tọju aaganna tẹtẹ tita
Nigba ti wọn ba ti ṣe ayẹwo, oniruuru ilana ni wọn le tọka si lati fi koju rẹ
“Ọna ti wọn le gbe e gba le nii ṣe pẹlu iru iwa ti alaisan tẹtẹ tita naa ni. Pupọ wọn lo tun ni awọn nnkan aaganna miran to n ba wọn finra bii irẹwẹsi, eyi to tun nilo itọju. Lọpọ igba tẹtẹ maa n gba oniruuru ọna yọ, awọn iwa teeyan ko nii le fi ṣere, eyi si ni yoo tun bi aaganna miran,” Spanemberg ṣalaye.
Nipa titọju ipo to wa nilẹ (bii irẹwẹsi, iporuru ọkan, bi apẹẹrẹ), ohun to maa n ṣẹlẹ ni lati wa ọna abayọ - ati papaa lati wa ọna lati tẹri iwa naa bolẹ.
Ni afikun, aisan tẹtẹ tita ṣee tọju nipa titẹle ilana oogun, ati biba irufẹ ẹni bẹẹ sọrọ ọlọgbọn, ati ọrọ iyanju lati le jẹ ki wọn jawọ.
“Ifọrọwerọ nipa ọrọ iwuri. Ni awọn akọṣẹmọṣẹ maa n lo lati fi gbogun ti iru iwa aisan tẹtẹ tita. Iriri si ni wọn fi maa n ba wọn ṣe papọ, awọn miran si wa ni ipele lati fi iwa naa silẹ,” Spanemberg fi kun ọrọ rẹ.
Ni awọn igba miran, awọn dokita maa n kọ oogun fun awọn alaisan naa.
“A mọ pe awọn oogun ni kilaasi ‘opioid antagonist’ le ṣe iranwọ fun awọn to yan tẹtẹ tita laayo," Andrade ṣalaye.
Oniṣegun naa tun tọka si ẹgbẹ oluranlọwọ kan. “Ni Brazil, a ni ẹgbẹ ti a n pe ni Gamers Anonymous and Gaming Addicts, ti wọn n ṣiṣẹ takutakun.”















