Ṣé lóòótọ́ ni agbébọn jí ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn mẹ́fà gbé n'Igboho, tí wọ́n tún pa lára wọn?

Ọkọ̀ awọn Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbami-gbami ko yẹ agba, ẹranko n le mi bọ wa ko yẹ ọdẹ.

Ṣugbọn iroyin kan to gbode bayii n tọka si irufẹ nnkan bayii. Iroyin naa n ṣalaye, pe mẹfa ninu awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ni ikọ ajinigbe kan gbe lọ niluu Igboho, ipinlẹ Oyo.

Mọjumọ owurọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keje ọdun 2025 ni a gbọ pe ijinigbe naa waye.

Koda, iroyin kan sọ pe wọn tun pa lara awọn ẹṣọ alaabo naa.

Ṣugbọn lati tan imọlẹ si otitọ to wa nidii iroyin naa, BBC News Yoruba kan si Kabiyesi, Ọba Joel Olalere, Alapeta Igboho, nibi ti iroyin sọ pe ijinigbe naa ti waye.

Bakan naa la ba olori ikọ ọmọ ogun Amọtẹkun Oyo sọrọ, iyẹn Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju.

Bo tilẹ jẹ pe Olori Amotẹkun Oyo ṣalaye tiẹ lọna to tako iroyin naa, to si tun ṣepe fun awọn to n gbe e kiri, esi ti Kabiyesi fọ, tọka ohun to ṣẹlẹ gan-an.

Ẹṣọ Amọtẹkun mẹ́ta ni wọ́n jí gbé, kì í ṣe mẹ́fà-Alepata

Nigba to n ṣalaye iṣẹlẹ naa fun BBC News Yoruba laaarọ Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje ọdun 2025, Kabiyesi Ọmọwe Joel Olalere Olawuwo, Alepata Igboho sọ pe:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

'' Mẹfa kọ ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn ji gbe, mẹta ni, a si ti ri gbogbo wọn gba pada bayii pẹlu iranlọwọ awọn Amọtẹkun ati awọn ọdẹ ati ilu.

''Iṣẹlẹ naa waye mọjumọ ana la gbọ, awọn meji si jajabọ lọwọ wọn.

''Mojumọ oni yii nisinyi, wọn ti ri ẹnikan yooku gba.''

Nipa ibi ti wọn ti ji awọn ẹṣọ naa gbe, Alepata ṣalaye pe igbo 'Old Oyo National Park', ni.

O ni igbo naa wa loju ọna Igboho si Igbẹti. '

Kabiyesi sọ pe igbo naa wa lati ọna Ariwa orilẹede Naijiria, to fi kọja si Oyo ati awọn agbegbe miran.

Lori ohun to gbe awọn ẹṣọ Amọtẹkun debi ti wọn ti bọ sọwọ ajinigbe, Kabiyesi Alepata sọ pe oun ko mọ ohun to gbe wọn debẹ.

O ni ṣugbọn ohun to daju ni pe ajinigbe ji wọn gbe, wọn si ti gba ominira bayii.

Boya ọwọ ti ba eyikeyi ninu awọn ajinigbe naa, Ọba Olalere ni oun ko ti i gbọ nipa ohun to jọ bẹẹ.

O fi kun un pe ọrọ ti di oju ni alakan fi n ṣọri, bi eeyan yoo ba gba agbegbe naa kọja.

Ṣugbon awọn ẹṣọ alaabo ti wa ni sẹpẹ lati kapa iru iṣẹlẹ bẹẹ, gẹgẹ bi Kabiyesi Olaṣorogan Kẹrin, Alepata Igboho, ṣe wi.

Wọn kò jí ẹ̀ṣọ́ Amọtẹkun gbé l'Oyo, àwọn ni wọ́n wọgbó lọ fúnra wọn - Olórí ikọ̀ Amọtẹkun Oyo

Ninu alaye tiẹ lorii pe wọn ji ẹṣọ Amọtẹkun mẹfa gbe nipinlẹ Oyo, Olori ikọ naa, Ajagufẹyinti Olayinka Olayanju, ṣalaye pe irọ patapata ni iroyin naa.

'' Iru iroyin buruku wo niyẹn, ki lo de ti awọn eeyan maa n parọ, ki ni wọn n gba nibẹ?

''Iru iroyin bayii maa n bi eeyan ninu gan-an, ki wọn maa fi ẹmi eeyan ṣere bayii.

''Awọn ẹṣọ wa mẹta ni wọn lọ sinu igbo funra wọn, lai jẹ pe ẹnikẹni ran wọn lọ sibẹ.

'' Wọn kuro nibi iṣẹ wọn, wọn paarọ aṣọ, aṣọ ile lasan ni wọn wọ lọ sinu igbo, wọn lọọ da iṣẹ ara wọn jẹ ninu igbo naa ni, bi wọn ṣe ko sọwọ awọn agbesunmọmi niyẹn.

'' Meji ninu wọn jajabọ, wọn sare pada si ẹnu iṣẹ wọn ni nnkan bii aago meje alẹ.

'' Lẹyin igba naa la to o mọ pe ọkan ninu wọn ṣi wa lọdọ awọn eeyan naa.

''Nigba to si di nnkan bii aago kan oru oni, a ri ẹnikan to ṣẹku sọhun naa gba.''

Bẹẹ ni olori ikọ Amọtẹkun Oyo, Olayinka Olayanju, ṣalaye tiẹ.

O fi kun un pe ikọ Amọtẹkun lo funra ẹ ba awọn ẹṣọ mẹta naa wi fun iwa ti wọn hu, ki i ṣe pe wọn ji wọn gbe bi awọn kan ṣe n sọ kiri.

Ṣugbọn ohun ti awọn eeyan n sọ lori iṣẹlẹ naa ni pe o jọ gáté, kò jọ gàté, ọrọ naa fi ẹsẹ mejeeji tiro gátegàte.