Àwọn oníṣẹ̀ṣe yarí nípìnlẹ̀ Ogun, wọ́n ní àwọn n lọ sílé ẹ̀jọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lé wọ̀n níbi ìsìnkú Awujalẹ

Awujale ilẹ Ijebu to waja

Oríṣun àwòrán, @adedayo_viktor

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn oniṣẹṣe ipinlẹ Ogun ti koro oju si bi awọn kan ṣe le awọn ẹlẹsin ibilẹ kuro nile Awujalẹ ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, lasiko eto isinku rẹ.

Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2025 ni Awujale darapọ mọ awọn babanla rẹ ti ọpọ eeyan kaakiiri agbaye si ṣedaro ori adẹ ọhun.

Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara, nibi ti awọn kan ti n le awọn oniṣẹṣe kuro nibi eto isinku naa.

Akọrọyin BBC News Yoruba to wa nibi isinku naa jabọ pe, lootọ ni wọn le awọn kan jade nile oloogbe ọhun amọ oun ko le sọ boya oniṣẹṣe ni wọn le tabi bẹẹ kọ.

Nigba ti BBC kan si agbẹjọro ati alakoso awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ogun, Oloye Ifasola Opeodu, to jẹ Oluwo Iperu fidi iroyin naa mulẹ, o si ṣalaye pe awọn to le awọn oniṣẹṣe kuro nibi eto isinku naa ti ṣẹ si ofin ijọba ipinlẹ Ogun.

Ifasola fidi rẹ mulẹ pe yatọ si pe wọn le awọn eeyan naa, awọn ọmọ ogun tun wa lara awọn to le wọn kuro nibẹ.

"Gbogbo awa oniṣẹṣe yoo gba ile ẹjọ lọ"

O ni "Ko si nnkankan to ṣẹlẹ ju pe wọn tapa si ofin ti ijọba ipinlẹ ogun gbe kalẹ lori ọrọ ọba atawọn oloye lọdun 2021.

"Gbogbo awọn oniṣẹṣe ilẹ Yoruba, to fi mọ awọn ti ipinlẹ Ogun ati Ijebu-Ode ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ, a maa lọ sile ẹjọ lati le ṣe amulo ofin yẹn gangan, lati le kọju ija si gbogbo awọn to ṣe nnkan ti wọn ṣe ni ijẹta yẹn. Nitori eewọ ni, o dẹ lodi si ofin.

"Nnkan ti ofin sọ ni pe eto iṣẹṣe, ilana iṣẹṣe ati aṣa wa ni wọn gbọdọ fi jẹ ọba, ohun si ni wọn gbọ fi sin ọba.

"O dẹ wa ninu ofin yẹn wi pe wọn ko gbọdọ yọ ohunkohun tabi ge ohunkohun kuro lara ọba amọ gbogbo etutu ibilẹ to ba yẹ ki wọn ṣe ni wọn gbọgbọ ṣe lati igba ti ọba ti waja.

"Wọn gbọdọ ṣe etutu naa si ara oku ọhun ki wọn to sin in."

"A gbọdọ ṣe etutu lati dena ajalu nla ati ajakalẹ arun laarin ilu"

Agbẹjọro naa sọ siwaju si pe o di dandan ki wọn ṣe etutu to yẹ ki wọn se si ara oloogbe naa bi bẹẹ kọ ewu n bẹ loko longẹ ilẹ Ijebu.

O ni "eewọ ni, eewọ ni,eewọ ni, ajakalẹ arun gidi ni, oriṣirṣi nnkan lo maa ṣẹlẹ. Ajalu buruku buruku lo maa ṣẹlẹ, nitori naa ni a ṣe gbọdọ ṣe."

Ifasola ṣalaye pe eredi ree ti wọn fi gbọdọ ṣe etutu to yẹ lati dena nnkan buruku to le ṣẹlẹ nitori ai ṣe e.

Àkọlé fídíò, Èrò àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ogun ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí òfin tó dé sínsin òkú àwọn olóyè tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

O fi kun pe nigba ti wọn yoo ba ṣe etutu naa, awọn agbofinro atawọn to le awọn oniṣẹṣe kuro nibi eto isinku naa lo gbọdọ wa nibẹ nitori ohun ti awọn oniṣẹṣe fẹ ṣe ko lodi si ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ẹlẹsin mii ti wọn kii ṣe oniṣẹṣe ko lẹtọ lati wa nibi eto isinku naa nitori ko si ninu iwe ofin ipinlẹ Ogun bẹẹ.

O fidi rẹ mulẹ pe awọn imaamu to lọ kirun si ara oloogbe naa ti tapa si ofin nitori ofin ipinlẹ Ogun lori ọrọ ọba ko faye gba awọn ẹlẹsin Musulumi lati lọ kirun si ara ọba, yala o jẹ Awujale tabi ọba mii.

Ifasola pari ọrọ rẹ pe ọna abayọ kan ṣoṣo si ọrọ yii ni ki wọn gba awọn oniṣẹṣe laaye lati ṣetutu to yẹ ki wọn ṣe.

Ati pe ijọba gbọgbọ gba ofin laaye lati ṣiṣẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ ma baa waye mọ lọjọ iwaju.