Ohun tí Awujale ṣe nígbà ayé rẹ̀ nípa ìsìnkú àwọn ọba rèé, táwọn oníṣẹ̀ṣe kò fi kópa níbi ìsìnkú rẹ̀

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2025 ni Awujale ilẹ̀ Ijebu, Oba Sikiru Adetona sí ilé rẹ̀ tó wà ní Igbeba, Ijebu Ode lẹ́yìn tí Ọba náà wàjà lálẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Keje.
Ìlànà ẹ̀sìn Islam ni wọ́n fi sin Ọba Adetona èyí tí Imam àgbà ìlú Ijebu Sheikh Muftaudeen Ayanbadejo darí rẹ̀.
Àmọ́ lẹ́yìn ìsìnkú ọba náà ni àwọn ìròyìn kan ti ń jà lórí ayélujára pé wọn kò fún àwọn oníṣẹ̀ṣe láàyè láti ṣe ojúṣe wọn níbi ètò ìsìnkú ọ̀hún.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn báwọn èèyàn kan ṣe ń lé àwọn kan tó farajọ àwọn oníṣẹ̀ṣe kúrò níbi ètò ìsìnkú.
Ohun táwọn èèyàn náà ń sọ nínú fídíò náà ni pé káwọn oníṣẹ̀ṣe náà máa lọ pé òkú Mùsùlùmí ni òkú táwọn fẹ́ sin.
BBC News Yorùbá kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ibi ètò ìsìnkú Oba Adetona ni wọ́n ti ya fídíò náà.
Kódà àwọn ìròyìn kan tún gbe pé àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi lé àwọn oníṣẹ̀ṣe ọ̀hún kúrò níbi ètò ìsìnkú náà.
Kí ni òfin sọ nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Ọba ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Oríṣun àwòrán, DABIODUN/X
Ní ọdún 2021 ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun gbé òfin kan kalẹ̀ tí wọ́n pè ní "Obas and Chiefs Law of Ogun State 2021" lójúnà àti bomi pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ aáwọ̀ tó máa ń wáyé lórí ìfinijoyè àti ìsìnkú àwọn ọba tó máa ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.
Ní pàtàkì jùlọ, àwọn èyí tó máa ń wáyé láàárín àwọn afọbajẹ, àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn àtàwọn ẹbí ọba.
Ohun tí òfin náà gbé lórí jùlọ ni ìlànà oyè jíjẹ àti ìsìnkú àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà.
Abala kẹjọ òfin náà là á kalẹ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi tipátipá mú ọba tàbí olóyè kankan wọ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tàbí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yòówù tí kò bá fẹ́.
Abala Karùndínlọ́gọ́ta òfin náà ni wọ́n ti ṣe àlàkalẹ̀ bí wọ́n ṣe lè sin àwọn ọba àti gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́.
Òfin náà sọ pé òkú ọba ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ sínsin ní ìlànà àṣà àti ìṣe ìlú náà níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ní ọwọ́ yíyọ ẹ̀yà ara èèyàn tàbí jíjẹ ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ọba ní àǹfàní láti sọ ìlànà tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n fi sin àwọn ṣáájú kí ọba bẹ́ẹ̀ tó wàjà yálà ní ìlànà ẹ̀sìn mùsùlùmí, ìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹ̀ṣe àti pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tàpá sí àlàkẹlẹ̀ àwọn ọba náà.
Òfin náà fi kun pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dí àwọn ẹbí ọba tó bá wàjà lọ́wọ́ láti sin òkú wọn ní ìlànà tó bá wù wọ́n.
Ẹnikẹ́ni tó bá tàpá sáwọn ìlànà yìí gẹ́gẹ́ bí òfin ni ó ṣeéṣe kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì tàbí ọdún kan gbára láìsí àǹfàní sísan owó ìtanràn.
Gómìnà Dapo Abiodun níbi ètò ìsìnkú Ọba Adetona sọ pé ìsìnkú àwọn ọba yóò máa wáyé ní ìlànà ẹ̀sìn tí wọ́n bá ń sìn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú òfin ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn oníṣẹ̀ṣe yarí

Oríṣun àwòrán, Ikorodu Traditionalist
Lẹ́yìn tí ìjọba gbé òfin náà kalẹ̀ làwọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun fariga, tí wọn si paroko ikilọ ranṣẹ si gbogbo awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ni ipinlẹ naa.
Bakan naa ni wọn fi ewe ọmọ mọ awọn oriade kan ti wọn pe ni "aletilapa" ọba leti, lati jinna si eto ọba jijẹ ati isinku ọba nipinlẹ naa lati asiko naa lọ.
Ẹgbẹ́ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ogun ni inu awọn ko dun si ilana oye jijẹ tuntun naa.
Wọn ni awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi n ṣi ofin oye jijẹ ni ipinlẹ naa tumọ si bo ṣe wu wọn.
Nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Ṣagamu, awọn oniṣẹṣe labẹ aṣia ẹgbẹ Oniṣẹṣe Parapọ lorilẹede Naijiria woye pe, ofin oye jijẹ naa, ninu ẹsẹ kiini de ikarun un abala karundinlọgọta faaye silẹ lati sin ọba to ba waja ni ilana iṣẹṣe.
Agba Oye Ifaṣọla Ọpẹodu, to sọrọ lorukọ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe naa woye pe, abala ofin ti a n sọrọ rẹ yii to fun awọn mọlẹbi ọba to ba waja laaye lati wa nibi isinku rẹ, yoo da awuyewuye silẹ laarin awọn mọlẹbi naa atawọn ti iṣẹṣe faye gba lati ṣeto ikẹyin fun ọba to ba waja.
Awujalẹ ló lewaju òfin pé kí wọn máa sin àwọn Ọba ní ìpínlẹ̀ Ogun ni ìlànà ẹ̀sìn tí wọn ń sìn
Kì í ṣe ìyàlẹ́nu rárá pé wọn sin Ọba Adetona ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí nítorí nígbà ayé rẹ̀, òun gan-an ló lewaju nínú ìjà gùdù pé kí wọn máa sin ọba ní ìpínlẹ̀ Ogun nibamu pẹlu ẹṣin to ń sìn nígbà ayé rẹ.
Ọba Adetona ní níbi ìpàdé kan tó wáyé ní ọjọ́ kejidinlọgbọn oṣu Kejìlá ọdún 2016, ní àwọn ọba tí gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹni mẹ́rin kalẹ, méjì jẹ Mùsùlùmí, méjì sí jẹ́ Kristẹni, tí yóò soju ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà to wá yíká ilẹ̀ Ijebu.
"Ojúṣe ìgbìmọ̀ náà ni lati fikunlukun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ awo Osugbo, tí wọn ń jà òkú àwọn ọba gbà kiri, tí wọn sì tún ń gba àwọn dúkìá kan lọ́wọ́ àwọn ẹbí ọba, tí wọn sì ń sìn àwọn ọba ní ìlànà ẹṣin ìbílẹ̀.
Mo jẹ kò ye wọn pé ojúṣe àwọn Osugbo kọ ní láti sìn ọba tó bá wàjà, àmọ́ nibamu pẹlu àṣà wá, ojúṣe wọn ní láti parí ìjà ààlà ilẹ̀ oko gẹ́gẹ́ bíi ọba ṣe pàṣẹ fún wọn. "
Gbogbo rádaràda yìí gbọdọ dáwọ́ dúró láti àkókò yìí lọ, iranṣẹ ọba lásán ni àwọn Osugbo, àwọn èèyàn kò sọ gbọ́dọ̀ sá fún wọn mọ.
Ṣe ni kí àwọn ẹbí ọba tó bá wàjà yọ pankẹ́rẹ́, kí wọn nà wọn jáde kúrò lọdọ wọn nítorí ìpinnu ẹni kọ̀ọ̀kan ni ẹṣin to bá gbà jẹ́. "
Lẹyin èyí ni ijọba ìpínlẹ̀ Ogun gbé òfin kalẹ pé kí wọn máa sin àwọn Ọba ní ìlànà ẹṣin tí wọn ba n sìn.















