Ọba Sikiru Adetona wọ káà ilẹ̀ sùn ni ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí, àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ kò yọjú

Oku ọba Adetona àti ibojì rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wọn tí sin oku kabiyesi, ọba Sikiru Kayode Adetona, Awujalẹ ilẹ̀ Ijebu sì ile rẹ tí ó wà ní igbeba, Ijebu Ode ni ilana ẹṣin Mùsùlùmí.

Déédéé aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ òní ni wọ́n fi ìyókù ara Ọba Adetona fún ilẹ̀ nibi ti àwọn èèkànlú péjú si.

Akoroyin BBC News Yoruba ti o wa ni ibi eto ìsìnkú naa royin pe, ẹsẹ kò gba ero níbi eto isinku ọba alaye naa ti o waja ni ọjọ́ aiku ana.

Òkú Ọba Adetona

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi eto isinku ọba alaye naa, gomina ìpínlẹ̀ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun ni ipilẹ Ogun tí padanu ọba alaye kan nilẹ Yoruba, ti o gbajumọ julọ lórí ìtẹ́.

Gomina ni eto ìsìnkú àwọn ọba yoo maa jẹ ìlànà ẹṣin tí wọn ba n sìn gẹgẹ bó ṣe wa ninu ofin ìpínlẹ̀ ogún.

Bi ẹ kò ba gbagbe, ọ̀rọ̀ ìsìnkú àwọn ọba tí de ile ẹjọ, ti wọn si ti gba pe ki wọn maa sin àwọn ọba ní ìlànà ẹṣin wọn.

Àwọn èèkànlú péjú fún ìsìnkú Awujalẹ

Lára àwọn ilumọkaa eniyan pàtàkì tí wọ́n peju síbi eto isinku ọba alade naa ni, gomina ìpínlẹ̀ Ogun, ọmọọba Dapo Abiodun

Àwọn èèkànlú yoku ni Aliko Dangote, Mínísítà fun ọ̀rọ̀ abẹle, Bosun Tijani ati Asofin Agba ni ìpínlẹ̀ Ogun, Olamilekan Adeola.

Bákan náà, igbakeji ààrẹ tẹ̀lẹ́, Yemi Osinbajo, gomina ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu, gomina tẹlẹ ni ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ati awọn èèkànlú mìíràn.

Ọba Sikiru Adetona

Oríṣun àwòrán, Awujale Palace

Àwọn èèkànlú péjú fún ìsìnkú Awujalẹ ní ìrọ̀lẹ́ òní , gbogbo ọjà ni Ijebu Ode pa kése

Igi dá, erin wo Àjànàkú sun bí òkè n'ilu Ìjẹ̀bú Òde, bí oriade ìlú náà, ọba Sikiru Kayode Adetona ṣe dára pọ mọ àwọn baba ńlá rẹ.

Ọjọ́ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu Keje ọdun 2025 ni wọn tufọ ikú oriade náà, tó jọba fún ọdún márùn-úndínláadọ́rin, to si lo ọdún mọ́kànlélaadọ̀run lókè eepẹ.

Àwọn eekanlu àti lookọ-lookọ ni wọn tí darapọ pẹlu awọn ọmọ, mọlẹbi àti olùgbé ilu ijebu ode lati ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fun kabiyesi, ọba Adetona.

Ile adani kabiyesi tí ó wà ní agbegbe Igbeba, ní ijebu ode ni eto ìsìnkú ọba náà yóò ti waye ni ilana ẹṣin musulumi.

Ogbeni Ọjà ilẹ Ìjẹ̀bú, Oloye Sunny Folorunso Kuku ati èèkànlú miran

"Yóò pẹ ka to rí irú Ọba Adetona mọ nílùú Ijebu Ode"

Akoroyin BBC News Yoruba ti o wa ni igbeba Ijebu Ode, níbi eto isinku ọba kabiyesi Awujalẹ naa jabọ pe gbogbo ọjà ni ó wa ní titipa yíká ìlú ijebu òde.

Bakan naa, Tokunbo Talabi tí ó sọrọ lórúkọ ìjọba ipinlẹ Ogun ni, adanu n là ní iku ọba naa jẹ fun ìlú ijebu ode, ipinle ogun àti orile-ede Naijiria lapapọ.

Ninu ọrọ ibanikẹdun tìrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Ọjà ijebu ode, Oloye sunny Kuku ni ọba Sikiru Kayode Adetona yoo maa wa ni iranti fun iwa ìṣọ̀kan rẹ fun gbogbo ọmọ bibi ijebu lapapo.

Oloye Sunny Kuku fi kun pe, yoo pẹ díẹ̀ kí ilu ijebu to tun ri iru ọba Sikiru Kayode Adetona mọ.

Igbakeji Aare orile-ede Naijiria tẹ́lẹ̀ rí, Ojogbon Yemi osinbajo àti àwọn èèkànlú miran

Àwọn eekanlu ti péjú fún ìsìnkú Awujalẹ

Àwọn adari, alufa ati olori ẹṣin musulumi ni wọn ti wa ní igbeba, Ijebu Ode níbi tí eto isinku kabiyesi awujale naa ti fẹ́ waye eyi ti Imam agba ijebu ode le iwaju gbogbo elesin musulumi náà.

Lara awon lórúkọ tí wọn tí wa nibi eto isinku kabiyesi ọba Awujalẹ naa ni, olórí ọmọ ọba ijebu, Wasiu Ayinde Marshal, gomina tẹle rí ní ipinle ogun, Otunba Gbenga Daniel, igbakeji gomina ipinle ogun, Naimat Salako Oyedele ati awon miran.

Agogo mẹ́rin ọsan oni ni ireti wa pe eto isinku kabiyesi naa yoo waye ní ilana ẹṣin musulumi.