Fayose, Ladoja àtàwọn gómìnà míì tí EFCC fẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn àmọ́ tí ilé ẹjọ́ tú sílẹ̀

Ladoja, Fayose atawọn gomina tẹlẹ meji

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ giga kan niluu Eko ti da gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan, Ayodele Fayose, lare ninu ẹjọ lilu owo ilu ni ponpo ti EFCC fi kan an.

Lọjọ iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2025 yii ni ile ẹjọ naa sọ pe fayose ko jẹbi ẹsun kiko owo ti iye rẹ le ni biliọnu meji naira jẹ ti ajọ EFCC fi kan an lati ọjọ pipẹ.

Fun ọpọ ọdun ni Fayose fi n jẹjọ naa to da lori ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu lasiko ijọba rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti amọ ile ẹjọ ti sọ pe ẹsun naa ko ni ẹri to dantọ tako gomina ana ọhun.

Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Ayodele Fayose

Adajọ sọ pe "ikọ olupẹjọ kuna lati so olujẹjọ mọ ẹsun ti wọn fi kan an ni ọna ti yoo mu ki ile ẹjọ ke pe e lati wa wi tẹnu rẹ."

Ṣaaju ni ile ẹjọ naa ti kọkọ fun afurasi naa laaye lati lọ soke okun fun itọju lẹyin to bẹbẹ fun.

Lẹyin idajọ naa ni Fayose ṣe ajọyọ pẹlu awọn ololufẹ rẹ fun atilẹyin wọn lasiko igbẹjọ naa.

Wayi o, kii ṣe Fayose ni gomina akọkọ ti yoo foju bale ẹjọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ni Naijiria amọ ti ile ẹjọ yoo sọ pe ko jẹbi tabi ko da ẹjọ ọhun nu.

Yatọ si Fayose, iwọnyii ni awọn gomina ni Naijiria to ti jẹjọ ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọkumọ amọ to bọ lọwọ igbẹjọ ọhun lai gba idajọ ẹbi.

Rashidi Ladoja – Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ

Rashidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, @Omojuwa

Fun odidi ọdun mọkanla gbako ni igbẹjọ ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ti EFCC fi kan gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ naa fi n lọ ki ile ẹjọ to da a nu.

Ọdun 2008 ni EFCC fẹsun kan Ladoja ati kọmiṣọna eto iṣuna rẹ, Waheed Akanbi pe wọn ṣe owo ti iye rẹ din diẹ ni biliọnu marun un naira baṣubaṣu.

Lasiko to n dajọ, ile ẹjọ sọ pe EFCC kuna lati pese ẹri to dantọ lori ẹjọ to fi kan Ladoja ati Akanbi.

Adajọ sọ pe ọrọ ti awọn ẹlẹri mẹfa ti EFCC ko wa sile ẹjọ sọ tako ara wọn.

O fi kun pe ẹsun ti wọn fi kan Ladoja ko koju oṣuwọn ati pe o yẹ ki wọn ṣe iwadi wọn daadaa ki wọn to maa fi ẹsun iwa ibajẹ kan ẹnikẹni.

Sule Lamido – Gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹ

Sule Lamido

Oríṣun àwòrán, Sule Lamido

Sule Lamido ni gomina ipinlẹ Jigawa, to jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ to toṣi julọ ni Naijiria, laarin ọdun 2007 si 2015.

Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o gba owo abẹtẹlẹ lọwọ awọn ileeṣẹ kan ko to gbe iṣẹ akanṣẹ ijọba fun wọn.

Ẹsun bii mẹtadinlogoji ti apapọ owo rẹ jẹ lilu ₦1.35b ni ponpo ni EFCC fi kan oun atawọn ọmọ rẹ, Aminu ati Mustapha, lọdun 2015.

Lẹyin ọdun mẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ naa ti wọn si n sun siwaju, ile ẹjọ da ẹjọ naa nu lọdun 2023 latari pe ipinlẹ Jigawa lo yẹ ki wọn ti gbọ ẹjọ ọhun dipo ilu Abuja.

Kaka ki ile ẹjọ tare ẹjọ naa si Jigawa, niṣe lo da ẹjọ ọhun nu ti gbogbo igbiyanju EFCC lati pe ẹjọ kọtẹmilọrun si ja ofo.

Danjuma Goje – Gomina ipinlẹ Gombe tẹlẹ

Danjuma Goje

Oríṣun àwòrán, Danjuma Goje

Danjuma Goje ni gomina ipinlẹ Gombe lati ọdun 2003 si 2011, wọn si fẹsun kan an pe o lu owo ti iye rẹ to biliọnu marundinlọgbọn naira ni ponpo.

EFCC bẹrẹ ẹjọ rẹ lọdun 2012, koda awọn akẹkọọ ṣe iwọde pe o gbọdọ foju wina ofin.

Amọ nigba ti yoo di ọdun 2019 ti Goje jawọ kuro ninu ere ije si ipo Aarẹ ile igbimọ aṣofin lati ṣatilẹyin fun oloogbe Muhammmadu Buhari, EFCC fa ẹjọ ọhun le adajọ agba Naijiria lọdun naa lọhun lọwọ.

Ko pẹ si asiko naa ti adajọ agba ọhun lo agbara rẹ labẹ ofin lati da ẹjọ naa nu bo tilẹ jẹ pe EFCC fa ẹlẹrii arundinlọgbọn kalẹ, titi di oni, ẹjọ naa ti di itan.

Orji Uzor Kalu – Gomina Abia tẹlẹ

Orji Uzor Kalu

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Orji Uzor Kalu ṣejọba ni ipinlẹ Abia laarin ọdun 1999 si 2007, ni 2007, EFCC ni o kowo to le ni bililọnu meje naira jẹ.

Lẹyin ọdun mejila to ti n ṣe ẹjọ, ilẹ ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun mejila fun lọdun 2019 amọ nigba ti yoo di ọdun 2020, ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria yi idajọ naa po latari pe adajọ to ṣedajọ rẹ ọhun ti gba itẹsiwaju lẹnu iṣẹ ko to ṣedajọ naa.

EFCC gbiyanju lati bẹrẹ ẹjọ naa lakọtun amọ gbogbo igbiyanju rẹ ni ijọba apapọ bẹgi dina latari pe wọn ko ri awọn iwe kan lara awọn iwe ẹjọ naa.

Lọwọ yii, Orji Uzor Kalu ti wa nile igbimọ aṣofin Naijiria gẹgẹ bii ọkan lara awọn aṣofin lonii.

Peter odili – Gomina ipinlẹ Rivers nigba kan ri

Peter Odili

Oríṣun àwòrán, @Real_AmakaIke

Laarin ọdun 1999 si 20017 ni Odili ṣe ijọba ni Rivers amọ irawọ rẹ milẹ titi lẹyin ti EFCC ni o kowo ti iye rẹ to ọgọrun miliọnu naira jẹ.

Bo tilẹ jẹ ẹsun naa tobi pupọ, ko foju bale ẹjọ lori ẹsun naa titi di oni.

Eyii ko ṣẹyin bi ile ẹjọ kan ṣe paṣẹ lọdun 2007 pe EFCC ko gbọdọ ṣewadii rẹ tabi fi ṣikun ofin mu.