Ìjọba ológun ní Burkina Faso tú àjọ elétò ìdìbò ká

Ibrahim Traoré, ṣọja to n dari orilẹede Bukina Faso

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ibrahim Traoré
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Nibikibi lagbaaye, irori ijọba ologun ki i jọ ti awọn oloṣelu ti wọn n ṣejọba alagbada.

Ni bayii, lorilẹede Burkina Faso, ijọba ologun labẹ idari Ibrahim Traoré, ti tu ajọ eleto idibo orilẹede naa ka.

Wọn kede pe fifi owo ilu ṣofo ni ajọ to n ri si eto idibo ọhun wa fun, ko si idi kan fun wọn lati wa mọ.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle (The Interior ministry) ni yoo maa ri si idibo lọjọ iwaju bayii lorilẹede naa, gẹgẹ bi ẹka iroyin RTB TV ni Burkina Faso ṣe kede.

Tẹ o ba gbagbe, lati oṣu Kẹsan-an ọdun 2022 ti Ibrahim Traoré ti gbajọba orilẹede naa lo ti bẹrẹ awọn atunto to yatọ si ohun ti wọn n ba bọ nigba aye ijọba alagbada.

Lara atunto naa ni bi wọn ṣe sun ọjọ idibo to le gbe alagbada wọle pada siwaju.

Ọdun to kọja lo yẹ ki wọn ti dibo ọhun, ṣugbọn ṣọja to n ṣejọba sun un siwaju di oṣu Keje ọdun 2029.

Eyi yoo fun Ibrahim Traoré lanfaani lati maa ṣejọba lọ, oun naa yoo si le dupo aarẹ ninu idibo naa tasiko ba to.

Nipa ọrọ owo ilu, ẹka iroyin AFP royin pe minisita to n ri si ẹkun ilu kọọkan, Emile Zerbo, sọ pe owo to to $870,000 (£650,000) ni ijọba n na lọdun kan lori ibo.

''Bí a ṣe fagile àjọ yìí yóò jẹ́ ká lẹ́nu lórí ètò ìdìbò wa''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Emile Zerbo tẹsiwaju pe:

"Àjọ eleto idibo ti a tuka yii yoo jẹ ka le sọrọ lori ọna ti a ba fẹẹ gbe eto idibo wa gba.

"Bakan naa ni ko ni i jẹ ki awọn to n da si eto idibo lati ilẹ okeere jẹ gaba lorii wa. "

Ẹ o ranti pe ijọba ologun yii tako iranlọwọ ijọba amunisin France, ti wọn si n ba Russia ṣe lati ọdun kẹta ti wọn ti gbajọba.

Awijare ijọba ṣọja nigba naa ni pe awọn oloṣelu ko lagbara lati koju awọn alakatakiti ẹsin Islam to n da wahala silẹ niluu naa.

Ṣugbọn awọn ajafẹtọọ ọmọniyan koro oju si eyi.

Wọn fẹsun kan ijọba Ibrahim Traoré, pe araalu ni wọn n ba ja ki wọn too koju awọn agbesunmọmi.

Wọn fi kun un pe awọn ṣọja yii n pa eto ijọba awaarawa run, wọn si n pa ohun mọ araalu lẹnu, wọn ko jẹ ki wọn le sọ ohun to n dun wọn lọkan.

Bakan naa ni awọn kan n bu ẹnu atẹ lu ijọba Traoré, wọn ni awọn ko ti i ri nnkan kan to gbe ṣe latigba to ti gbajọba.

Ni oṣu mẹfa akọkọ ọdun 2025, awọn ikọ apaayan JNIM, kede pe ikọlu ọọdunrun din ni ogun (280) ni awọn ti ṣe si awọn eeyan Burkina Faso.

Onka yii pọ ni ilọpo meji ju iye ikọlu ti wọn ṣe loṣu mẹfa akọkọ ọdun 2024 lọ, gẹgẹ bi akọsilẹ iwadii ti BBC ṣe.