Wo bí ìmọ̀ ẹ̀rọ àtọwọ́dá àti àsọdùn ṣe ń gbóríyìn fún olórí ológun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Chiagozie Nwonwu, Mungai Ngige, and Olaronke Alo
- Role, BBC Global Disinformation Unit
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Eefin bẹrẹ si i ru lati ori ilẹ kan, bẹẹ ni Beyoncé, to wọsọ ologun naa farahan ninu ọkọ akọtami kan. Ọgagun Ibrahim Traoré, olori ologun to n ṣejọba ni Burkina Faso naa wa ninu fidio to n kọrin ọhun, o si yinbọn kan.
"K'Oluwa da aabo bo Ibrahim Traoré loju ọna ogun to n ja nitori awọn eeyan rẹ, bo ṣe n gbiyanju lati ja wọn gba lọwọ amunisin." Bẹẹ ni orin to n ja too ninu fidio naa n wi.
Ṣugbọn fidio naa ki i ṣe gidi, ki i ṣe Beyoncé tabi Ibrahim Traoré lo wa nibẹ. Atọwọda ni fidio naa, ti wọn fi imọ ẹrọ ṣe ti yoo si jọ gidi loju.
O le lọgọrun-un awọn fidio bayii ti wọn lo imọ ẹrọ ti a mọ si AI fi ṣe, awọn fidio naa n ṣafihan Traoré bii akọni ọmọ ilẹ Afrika, ọpọ rẹ lo jẹ pe oun ti ko ri bẹẹ ni wọn n sọ. Ọpọlọpọ fidio bayii lo ti kun ori ayelujara kaakiri ẹkun Sahara ilẹ Africa lati ipari oṣu Kẹrin.
Bi ina inu ọyẹ lo n ran kiri awọn ẹka ayelujara bii X, Facebook, Instagram, TikTok, WhatsApp ati Youtube lawọn orilẹede bii Naijiria, Ghana ati Kenya, wọn n kede Traoré bii awokọṣe fun awọn olori ilẹ Africa yoku.


Àtìlẹyìn ojúlówó àti àtọwọ́dá
Ọgbẹni Traoré, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to gbajọba Burkina Faso ni 2022, ṣafihan ara rẹ bi ẹni to korira imunisin, o maa n tako bi awọn orilẹede alagbara ṣe n da si ọrọ ilẹ Adulawọ, agaga ilu France, Russia ni ologun yii mu ni ọrẹ.
Labẹ isakoso Traoré, ijọba tiwa-n-tiwa ti koju awọn ijakulẹ kan, pẹlu iroyin to n jade pe o n ti awọn oniroyin mọle pẹlu awọn to ba tọka aleebu rẹ, wọn lo n fipa mu wọn wọ iṣẹ ologun. Iroyin kan to jade laipẹ yii lati 'Human Rights Watch', sọ pe ijọba yii ti pa to eeyan ọgọrun-un kan ninu ikọlu kan to waye loṣu Kẹta.
Ṣugbọn bi Ọgbẹni Traoré's ṣe maa n farahan nita bii olori ti ko wa aye maya ti jẹ ki ọpọ eeyan fẹran rẹ, ni Burkina Faso ati nilẹ okeere pẹlu. Ọpọ ero lo n wọ tẹle e lẹyin nigboro olu ilu naa ti i ṣe Ouagadougou.
Awọn kan n fi we Thomas Sankara, wọn ni boya olori ogun Burkina Faso tẹlẹ naa ti wọn pa ninu iditẹgbajọba 1987 lo tun pada wa.
Awọn awoye ṣapejuwe Traoré's bii ẹni to gbo lẹnu to si maa n koju awọn orilẹede nla pe ki lo kan wọn pẹlu ọrọ ilẹ Adulawọ. Wọn mọ ọn bii ẹni to da lẹnu ṣaka to si tun ni ọgbọn lati maa ba awọn akọroyin sọrọ.
Bi atilẹyin gidi ṣe wa fun Traoré kari Africa, " ilana imọ ẹrọ atọwọda ti wọn n lo fun un ki i ṣe gidi" Eliud Akwei, oluyẹwo kikun lati Code for Africa, to n tọpinpin iroyin ofege, lo sọ bẹe.
Awọn fidio ti wọn fi AI ṣe naa yoo maa jọ gidi, bo tilẹ jẹ pe awọn ohun ti ko ri bẹẹ nipa Traoré ati ijọba rẹ lo n gbe. Fidio kan sọ pe wọn fun ọkan lara awọn ẹṣọ Traoré ni $5 million lati pa a, awọn to ti wo fidio ọhun ti le ni miliọnu kan, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹri to fidi ohun to ṣẹlẹ yii mulẹ.
Fidio kan wa to gbajumọ pupọ ti awọn to wo o ti wọ miliọnu mẹrin aabọ (4.5 million).Fidio naa ṣafihan olori ogun yii ninu ọkọ ofurufu, ti oṣiṣẹ ibẹ ko si da a mọ, to ni ki ologun naa fi aga rẹ silẹ fun oniṣowo ọmọ ilẹ Faranse kan.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ni agbelẹrọ ni fidio naa, ọpọ ẹka youtube lo n tun fidio naa pin, ti wọn n gbe e jade bii pe o ṣẹlẹ loootọ ni.
Dokita Lassane Ouedraogo, lati Yunifasiti Ohio to si jẹ ọmọ Burkina Faso, sọ pe ''ọpọ awọn nnkan to n wa ninu fidio yii ko le ṣẹlẹ. O ni otitọ ni awọn mi-in ninu wọn, ṣugbọn aṣodun tun maa n kun un."
Awọn olorin bii Selena Gomez ati Rihanna pẹlu ologun Traoré ni wọn ti fi imọ ẹrọ to pọ, o si le ni ogoji iru rẹ ti wọn pin si YouTube laaarin ọsẹ kan.
A ba ọmọ Naijiria kan sọrọ lori fidio 'deepfake'' kan to ṣe ti Ọgbẹni Traoré si han nibẹ pẹlu akọrin R. Kelly, o ti to eeyan 1.8 million to ti wo o bayii.
"Idi kan ṣoṣo ti mo fi ṣe e naa ni ti imọ ẹrọ kan ti eeyan le lo, to ni 'Ibrahim Traoré' ninu."
Oguji Nnamdi Kenneth, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, sọ pe oun fẹran ologun naa gan-an, fidio rẹ toun ṣe si jẹ koun pa $2000 lori ẹka YouTube.
"Ẹrọ lasan ni gbogbo ẹ, AI ni, mo ro pe o yẹ kawọn eeyan mọ, emi o wa lati tan ẹnikan kan jẹ."

Oríṣun àwòrán, X
Fi wúrà ṣọrọ̀
Nigba ti Ọgbẹni Traoré lọ si St. Petersburg, fun ipade kan nipa Russia-Africa loṣu Keje ọdun 2023 ni iroyin okiki kan tun tan kalẹ nipa rẹ. Wọn n pin aworan oun ati Aarẹ Russia, Vladmir Putin, wọn si n gboriyin fun un nipa ọrọ to sọ ni Russia. Koda, awọn ẹka iroyin to lorukọ nla ni Russia naa gbe iroyin nipa rẹ, eyi si fun Traoré lokiki si i.
Lẹyin iyẹn ni omiran tun bẹrẹ nibẹrẹ ọdun yii, nigba ti yoo si fi di oṣu Kẹrin, ọrọ naa ti sun kan ilẹ America.
Ninu ipade kan ni US, olori Africom, General Michael Langley, fẹsun kan Traoré pe o n lo awọn wura to wa nipamọ lorilẹede rẹ lati da aabo bo ijọba rẹ.
Ọrọ yii di ariwo laaarin awọn olufẹ Africa lori afẹfẹ, wọn si n sọ pe America fẹẹ yọ Traoré nipo ni. Ọpọ awọn ohun ti wọn gbe jade nipa ọrọ yii lo jẹ irọ gbuu.
Lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, oju opo kan ni X, ti eeyan to to miliọnu meji n tẹle, kede pe Langley sọ pe ẹrujẹjẹ ni Ibrahim Traoré fun awọn eeyan rẹ."
Ṣugbọn ohun ti Ọgbẹni Mr Langley sọ, gẹgẹ bi akọsilẹ ti BBC ri ni pe ere ti Burkina Faso n jẹ lara wura ti wọn fi pamọ bi nnkan amuṣọrọ, jẹ paṣipaarọ lati da aabo bo aarẹ ologun wọn."
Laaarin ọjọ mẹwaa pere, eeyan to le ni 10.9 lo wo fidio ayederu kan to ni i ṣe pẹlu aabo Traore .
Ṣugbọn ni tododo, awọn ṣọja Russia ti wa ni Burkina Faso tẹlẹ lati koju igbesunmọmi, ti bi wọn ṣe wa nibẹ ko si ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ọrọ ilẹ America.
Loju opo X, ẹnikan naa tun ju fidio kan ti ọpọ ero wa nibẹ, wọn si kọ ọ sibẹ pe:. "Ẹ wo ọpọ ero ti wọn n wọde ni France, nitori Ibrahim Traoré ati ki Burkina Faso le maa ṣejọba ara rẹ lọ."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eeyan ẹgbẹrun mẹta fẹran fidio ti wọn n pin kiri lori ayelujara naa, wọn ko si fi han pe irọ gbuu ni.
Lati ile rẹ loriẹede Ghana, ọkunrin kan, Sulemana Mohammed to n lo oju opo ayelujara, pin fidio yii kan naa, o si kọ ọ sibẹ pe awọn eeyan Traoré ni South Africa niyẹn. Koda lẹyin ti BBC ti fi han pe eyi ki i ṣe otitọ, Ọgbẹni Mohammed taku pe bo ṣe ri lọdọ toun niyẹn.
"O maa n pa mi lẹrin gan-an tawọn eeyan ba n ro pe ohun ti a n sọ nipa awọn olori wa ko ri bẹe."
Sulemana Mohammed lo sọ bẹẹ.
O ni oun nifẹẹ Traoré pupọ, nitori "oun ni ohun ti awọn eeyan Africa ti n wa lati ọdun pipẹ sẹyin."














