Àrẹ̀mọ Saudi tó wà ní ẹsẹ̀ kan àye, ẹsẹ̀ kan ọ̀run fún ogún ọdun ti jáde láyé

Baba Arẹmọ ree to di mọ ọmọ rẹ lori ibusun.

Oríṣun àwòrán, Social media

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aafin ọba Saudi Arabia ti kede iku Arẹmọ wọn, Alwaleed bin Khalid bin Talal, ẹni to ti wa nipo ailaju fun ogun ọdun.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje ọdun 2025 ni Arẹmọ Alwaleed ku lẹni ọdun marundinlogoji, (35), lẹyin to ti wa nipo aimọ nnkan kan fun ogun ọdun.

Baba rẹ, Khalid bin Walid, lo fi atẹjade to kede iku naa si oju opo X rẹ, pẹlu adua pe ki Ọlọrun gba ìpẹ̀ ọmọ to jade laye naa.

" A gba kadara lori ohun gbogbo ti Ọlọrun ba ti kọ, ṣugbọn bi a ṣe n banujẹ ni a n ṣọfọ ipapoda ọmọ wa ọwọn, Ọmọọba Alwaleed bin Khalid bin Talal bin Abdulaziz Al Saud, ki Ọlọrun ṣaaanu fun un, o ti pada sọdọ Ọlọrun ọga ogo lonii."

Bẹẹ ni atẹjade naa wi.

Ailaju tabi mọ ibi ti eeyan wa yii ni a mọ si 'Coma' lede oyinbo.

Bi Ọmọọba Alwaleed ṣe wa nipo aiyirapada fun ogun ọdun naa ni wọn ṣe fun un ni inagije;Arẹmọ to n sun, (Sleeping Prince).

Ta a ni Arẹmọ Waleed bin Khalid?

Ọmọọba to jade laye naa ree pẹlu baba rẹ, nigba to wa ni kekere.

Oríṣun àwòrán, Social Media

Ọdun 1990 ni wọn bi Arẹmọ Waleed bin Khalid, ọdun 2005 lo ni ijamba ọkọ to lagbara kan.

Ile ẹkọ awọn ologun ni Arẹmọ Saudi naa wa nigba to ni ijamba to da wahala yii silẹ.

Ijamba ọkọ naa mu ki ẹjẹ maa jade ninu ori rẹ lọhun-un, eyi to mu ko wọ coma, ti ko si laju mọ titi ti ọlọjọ fi de bayii.

Ni gbogbo asiko to fi wa nipo aimọ nnkan kan yii, itọju to n ri gba lati ara awọn ẹrọ ti wọn n lo fun un lo gbe e duro.

Pẹlu awọn itọju nilana iṣegun oyinbo mi-in.

Ni 2019, iroyin jade pe ori rẹ ati ejika rẹ osi n mì, ṣugbọn ko tori rẹ laju naa.

Ni nnkan bii oṣu meloo sẹyin, ahesọ tun gbode pe Arẹmọ Saudi ti ji saye.

Ṣugbọn awọn eeyan rẹ sọ pe irọ ni iroyin ọhun, ko too di pe wọn kede iku rẹ bayii.

Ni gbogbo igba to fi wa nipo aimọ nnkan kan yii, itọju to peye gidi ni Aafin Saudi n fun ọmọọba naa.

Awọn ẹbi rẹ taku pe ki wọn ṣaa maa tọju rẹ lọ ni.

Baba rẹ, Ọmọọba Khalid, rọ awọn olutọju rẹ lati fi awọn ohun to n ran an lọwọ lati wa laaye silẹ.

O ni iwalaaye ati iku ko si lọwọ ẹnikan, afi ọwọ Oluwa.