Ṣé o ṣe é ṣe kí nǹkan mímú aṣaralóore tí o yàn láàyò máa ba eyín rẹ jẹ́? Àlàyé rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Nazanin Motamedi
    • Role, BBC Persian
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn igo omi ti a fi eso pelo tabi ẹlẹrindodo ti a fi omi osan peloo rẹ jẹ ohun mimu to ṣe ara loore,paapaa ti a n fi rọpo ohun mimu ti wọn n fi eroja atọwọda ṣe.

Ṣugbọn awọn onimo ijinlẹ sayensi ti fihan pe iru awọn ohun mimu wọnyi, ti wọn fi eso ṣe, le mu idibajẹ ba eyin lai ni atunṣe.

Kii ṣe iroyin buburu, Awọn oniwadii ni King's College London (KCL) ni United Kingdom, ẹni ti o ni iriri ti o ju ogun ọdun lọ, rii pe ọna ati aṣa mimu wọn, le mu adinku ba eyin wa.

Mo lọ lati pade awọn ẹgbẹ kan lati le ṣe ayẹwo eyin mi.

Ibajẹ ati ki iṣalẹ eyin si

Gẹgẹ bii ọmọde, wọn ma n kilọ nigba gbogbo nipa iho - awọn iho kekere ti o n dagba ninu eyin - ati bi adun ati chocolate ṣe le ba eyin rẹ jẹ.

Nigba ti o ba jẹ awọn ounjẹ ti o ni suga, awọn kokoro aifojuri kan le wọ inu eyin.

Ayafi ti awọn iho yii ba tobi, pupọ wọn ni a le ṣe atunṣe si.

Ṣugbọn iho eyin n ṣiṣẹ otooto. Awọn asiii lati inu ounjẹ ati ohun mimu ma n kọlu enamel – abala ọwọ iṣalẹ eyin.

Enamel lo ma n ṣe aabo fun abala eyin wa, ṣugbọn ko le daabobo ikọlu nigba gbogbo lati awọn awọn asiidi ati suga. Ni kete ti o bajẹ ẹ, ko si ayipada.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Ibajẹ ma n ba eyin nigba ti enamel ba ti koju ikọlu jijẹ ounjẹ to ni asiidi ati awọn ohun mimu ti o ni suga," Dokita Polyvios Charalambous, oniṣẹ abẹ eyin ati ọmọ ẹgbẹ ti ẹgbẹ iwadii King's College London lori iho eyin.

"Ipadanu enamel, ti a ko ba ṣe itọju rẹ, le fa ọpọlọpọ iho si eyin pẹlu abawọn, ahọn fifọ, eyin le kán , o si le ma lr gba nnkan tutu tabi gbigbona mọra" o fi kun.

Aworan

Idanwo ati iwadii fihan pe didi ohun mimu tabi fifi awọn ohun mimu to ni eroja asiidi si ẹnu n fa ibajẹ eyin, bi awọn iwa yii se n tẹsiwaju ni ajọsepọ n tẹsiwaju pẹlu eyin ati ohun mimu asiidi.

"Lati daabobo eyin, ma ṣe mu tabi di awọn ohun mimu to ni asiidi si ẹnu fun igba pipẹ. O tun le lo ohun to n fa ohun mimu lati inu igo ti a mọ si 'Straw' lati le din ajọsepọ pẹlu eyin ku. Iwadii ṣe atilẹyin pe lilo straw ma n mu adinku ba eyin bibajẹ, "Dokita Charalambous sọ.

Ẹgbẹ KCL rii pe jijẹ ati mimu nnkan to ni asiidi, paapa laarin awọn ounjẹ, gbe eewu nla dani fun eyin.

Awọn ti wọn ma n mu ohun mimu to ni asiidi lẹẹmeji lojumọ laarin ounjẹ, bii ẹlẹrindodo, omi pẹlu eso lemon, ni o ṣe e ṣe ki wọn ni ijamba eyin.

Nitori naa nipa sisọ akoko lilo pẹlu ọgbọn, boya pẹlu ounjẹ rẹ tabi lẹsẹkẹsẹ ṣaaju tabi lẹyin rẹ, o le daabo bo eyin rẹ.

Ohun mimu wo lo n fa ki eyin ma ṣi?

Aworan

Ẹgbẹ KCL ṣe afiwe awọn ipa ti awọn ohun mimu oriṣi mẹrin n ni lori minu adinku ba eyin nipa fifi awọn ayẹwo enamel sinu omi osan, cola, Ayran (ohun mimu yogurt ti kii ṣe carbonated), ati tii eso.

"Lẹyin wakati kan, ibajẹ ti a ṣe akiyesi jẹ deede si mimu awọn ohun mimu mẹta fun ọjọ meji. Awọn aworan lati inu ẹrọ ṣafihan ijamba.

Awọn abajade naa la oju wa si pe awọn ohun mimu to ma n ni gaasi 'fizzy', n fa ipalara pupọ julọ.

Omi osan, berries pupa, ati nikẹyin, Ayran (yogurt ati omi), lo tẹle.

Ayran jẹ ohun mimu ibilẹ ti ọpọ n gbadun ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede, bi India, Pakistan, Lebanoni, Siria, Tọki, Iran, ati Armenia.

Ounjẹ wo lo n fa ki eyin ma a ṣi?

Awọn ounjẹ ati ohun mimu asiidi le ja si ki eyin ma ṣi. Pupọ awọn eso ni o ni asidi ninu, pẹlu awọn eso citrus bii satsumas, eyi to ni asiidi ju ọgẹdẹ ati apricots. Awọn ounjẹ miiran ni:

  • Chillies
  • Tomato ati Ketch-up
  • Kimchi
  • Sauerkraut
  • Vinegars ati pickles (bi eso apple cider vinegar)
  • Alọpọ eso
  • Alọpọ omi ati eso
  • Tii mimu bii berry tii, rosehip, ginger ati lemon.
  • Ọti
  • Ẹlẹrindodo

Bawo ni iho eyin ṣe wọpọ si?

Awọn onisegun eyín kilọ wi pe ki eyin ma si ti di isoro ti o wọpọ ni agbaye ati pe o n peleke si.

O fẹrẹ to ida ọgbọn agbalagba ti o wa ni ọjọ-ori 18-35 ni Yuroopu ti wọn ko ni ju ogun eyin, gẹgẹ bii iwadii ọdun 2013 ti Dokita David Bartlett dari ni Prosthodontics ni King's College London Dental Institute.

Ni ifiwera, iwadii fihan pe o le ni eniyan 2,924 to jẹ ọjọ ori kan naa, ni awọn orilẹ-ede Arab mẹfa to n koju ogun eyin.

Oman ni ida 60.7%, Saudi Arabia (57.1%), UAE (49.3%), Egypt (32.9%), Kuwait (31.5%), ati Jordani (16.5%).