Mọ nípa àìsàn inú iṣan tí ìjọba America kéde pé ó kọlu Ààrẹ Trump

Aare Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ilẹ America kede l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keje ọdun 2025 , pe aisan kan ti a mọ si Chronic Venous Insufficiency, n da Aarẹ ilẹ naa, Donald Trump, laamu.

Akọwe iroyin fun ile ijọba America, Karoline Leavitt, to kede ọrọ naa ṣalaye pe, iṣan ọwọ Aarẹ Trump ni aisan naa kọlu.

Ikede yii lo waye lẹyin ti awọn aworan ọwọ Trump to da bii pe egbo wa nibẹ gbode kan.

Laipẹ yii ni ọwọ Trump wu to si lọọ ṣayẹwo, gẹgẹ bi Akọwe iroyin rẹ, Leavitt, ṣe ṣalaye.

Leavitt sọ pe ọwọ Trump to da bii pe egbo wa nibẹ ki i ṣe nnkan babara.

O ni bo ṣe n maa n bọ awọn eeyan lọwọ kiri lo fa a.

Akọwe iroyin America tẹsiwaju pe oogun ara riro, Aspirin, ti Trump tun maa n lo fun iṣẹ ọkan rẹ lo fa ọwọ rẹ to da bii pe egbo wa nibẹ.

Ṣaaju akoko yii ni Trump, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79), ti maa n yangan pe ilera oun pe pupọ.

O ti figba kan sọ nipa ara rẹ ri pe, oun ni "aarẹ to ni alaafia julọ to n gbe lorilẹ aye."

Ṣugbọn ki gan-an ni arun inu iṣan to n da Donald Trump laamu yii?

Ki ni 'Chronic Venous Insufficiency'?

Aworan ọwọ meji to n ki ara wọn, ọkan ninu awọn ọwọ naa fi apẹẹrẹ ailera han

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dokita Matthew Edwards, Alaga ẹka to n ri si iṣẹ abẹ ọkan ni Yunifasiti Wake Forest, ṣalaye fun BBC nipa aisan yii pe:

"O ṣee ṣe ko jẹ pe awọn aisan to lagbara lo fa Chronic Venous Insufficiency nigba mi-in, ṣugbọn to ba jẹ pe funra ẹ lo kan n ṣe eeyan, ti ki i ṣe pe aisan nla kan lo fa a, Chronic Venous Insufficiency ki i ṣe aisan to le"

"O ṣee ṣe ki awọn eeyan to wa ni ọjọ ori aarẹ yii koju aisan naa, ida mẹwaa si marundinlogoji ninu wọn (10 -35%) le ni i"

Bakan naa ni awọn akọṣẹmọṣẹ sọ pe bi aisan yii ba kọlu eeyan, ẹni naa le maa sanra si i.

O tun le kọlu awọn eeyan ti ẹjẹ wọn ba maa n dì, latari bi wọn ṣe n duro loju kan lẹnu iṣẹ fun ọpọ akoko.

Dokita Edwards ṣalaye pe apa isalẹ ara ni Chronic Venous Insufficiency maa n saba kọlu.

O ni eyi to n ṣe Trump yii ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ọwọ rẹ to dégbò, ti awọn eeyan n gbe kiri.

"Gbogbo wa lo ṣee ṣe ki ara wa maa da bii pe egbo wa nibẹ nigba ti a ba ti n dagba.

"Bẹẹ naa lẹ dẹ ṣe maa ri ọpọ eeyan ti wọn n lo oogun ti a mọ si Aspirin ati awọn oogun mi-in to le mu ki ẹjẹ wọn maa ṣàn daadaa. "

Dokita Edwards lo ṣalaye bẹẹ.

Bakan naa ni Dokita Meryl Logan, lati ẹka to n ri si iṣẹ abẹ ọkan ni University of Texas, ṣalaye pe nigba ti iṣan ẹsẹ ko ba gbe ẹjẹ lọ sinu ọkan mọ, ti ẹjẹ si lọọ rogun si isalẹ ẹsẹ ni aisan yii maa n waye.

O ni eyi yoo mu ki ẹsẹ naa wu.

"Chronic Venous Insufficiency tumọ si pe awọn iṣan to n gbe ẹjẹ lọ si ọkan da iṣẹ silẹ, ti ẹjẹ si duro sibi ẹsẹ naa lai le lọ."

Dokita Logan lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Ọnà àbáyọ

Bi eeyan yoo ba gbogun ti aisan yii, awọn dokita sọ pe o da kiru ẹni bẹẹ maa wọ ibosẹ ti wọn ti fi oogun oyinbo rẹ, nigba to ba fẹẹ sun.

Bakan naa ni ki wọn maa fi ipara pa ẹsẹ wọn ki wọn too sun.

Wọn tun gbọdọ maa gbe ẹsẹ naa soke bi wọn ba fẹẹ sun lalẹ pẹlu.