Ìjọba àpapọ̀ Naijiria tako ìpè tí Nnamdi Kanu pé láti da ẹjọ́ rẹ̀ nù, ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ siwaju

Aworan Nnamdi Kanu ni ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ kan niluu Abuja ti mu Ọjọ Kẹwaa oṣu Kẹwaa lati gbe idajọ kalẹ lori pe ki wọn da ẹjọ to n tako olori ajọ IPOB, Nnamdi Kanu nu, eyi to gbe wa si ile ẹjọ.

Ipe ki wọn da ẹjọ nu yii ni wọn gbe kalẹ ni Ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2025, ti wọn si tẹwọgba ni Ọjọ Ẹri, Ọjọkejidinlogun oṣu keje ọdun 2025.

Nigba to gbe ibeere naa kalẹ, agbẹjọro olujẹjọ, Kanu Agabi, SAN ṣalaye fun ile ẹjọ idi ti wọn fi pe fun dida ẹjọ nu.

O ni;

  • Lasiko ifọrọwerọ awọn ẹlẹrii, ọpọ awọn ẹlẹrii n lo sọ pe, "N ko mọ", "N ko ranti" fun ọgọrin igba. Eyi tako ofin ẹri
  • Awọn olupẹjọ kọ lati dahun ibeere mẹwaa ti olujẹjọ beere
  • Gbogbo awọn ẹlẹri to sọrọ ni ile ẹjọ ni ipa ti awọn ko ni lati gbọ ọrọ olujẹjọ ṣugbọn wọn ko ṣe iwadii
  • Ọpọ ẹri ni wọn gba jade lẹyin igbẹjọ, eyi ti ko bojumu.
  • Awọn ẹlẹrii ko sọ pato ohun ti wọn gbọ, ohun ti wọn sọ fun wọn ati ohun ti wọn foju ri lasiko iwadii nigba ti wọn n jẹri.
  • Fun ẹsun iwa ipanle, ẹlẹri ko sọ ẹnikẹni to ni pe ọrọ Kanu lo jẹ ki oun wu iwa naa.
  • Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti sọ saaju pe ile ẹjọ ko ni ẹtọ lati fa ọrọ ju.

Nigba to n fesi, Adegboyega Awomolo, SAN, agbẹjọro olupẹjo ni awọn ti pe ẹlẹri marun un lori igbẹjọ naa, ti wọn si pe ẹri tok say di prosecution don call five witnesses wey dem use prove evri element for di case.

Adegboyega ṣalaye pe ni iwọn ba to jẹ ofin ko faye gba sisọ ọrọ to le da rogbodiyan silẹ, olujẹjọ ni lati ṣalaye idi ti o fi n leri .

O ni Kanu gba baali lati ọdun 2017 si 2022 ṣugbọn ileẹjọ ni ko wa ni ihamọ nitori aabo araalu.

Ẹsun wo ni wọn fi kan Kanu?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọdun 2021 ni ijọba apapọ mu olori ẹgbẹ to n jijagbara fun idasilẹ orilẹede Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu, ti Biṣọọbu ijọ Anglican niluu Enugu, Ẹniọwọ Emmanuel Chukwuma ti sọ pe ipasẹ obinrin ni wọn fi mu.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹniọwọ Chukwuma ni to salaye ọrọ yii fun iwe iroyin Punch ni ọdun naa, wa lu ijọba lọgọ ẹnu lori bi wọn ṣe mu Kanu pada, lẹyin to sa lọ tẹlẹ nigba ti wọn kọkọ fi ọwọ ofin mu un.

''Nigba to wa ni oke okun, oun lo n lo awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB nilẹ Igbo lati maa da rogbodiyan silẹ."

Awọn ẹsun to ni i sẹ pẹlu iditẹ mọ ijọba, igbesunmọmi ati awọn ẹsun miran ni ijọba Naijriia fi kan Kanu.

Bo ṣe sọ pe oun ko jẹbi yii, awọn agbẹjọro ijọba sọ pe awọn ti ṣetan lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa

O ti to ọdun mẹrin ti igbẹjọ Nnamdi Kanu ti n waye

Ni ọdun 2022, Ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Umuahia, nipinlẹ Abia, paṣẹ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS pe ko san biliọnu kan Naira fun Nnmadi Kanu gẹgẹ bi owo itunnu fun ile rẹ ti ajọ naa kọlu nilu Iaiama Afaraukwu loṣu Kẹsan-an, ọdun 2017.

Nibi igbẹjọ naa, Onidajọ Benson Anya tun sọ fun ijọba apapọ Naijiria pe o gbọdọ kọ iwe ẹbẹ si Kanu ninu iwe iroyin mẹta lori ikọlu naa.

Ninu igbẹjọ miran to tun waye lori ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan Nnamdi Kanu, eyi to waye nilu Abuja bakan naa ni Kanu ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti ijọba fi kan oun.