Ọmọ ni mo jẹ́ fún Ooni Ile Ife láéláé, Deji ìlú Akure ṣàlàyé

Ooni Ile Ife ati Deji Akure

Oríṣun àwòrán, Deji of Akure land/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alayeluwa, Deji ilu Akure, Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi, tun ti fidi rẹ mulẹ lẹẹkan si pe ọmọ loun jẹ fun Ooni Ile Ife, Ọba Eniran Ogunwusi, Ojaja Kẹta.

Ọba Aladetoyinbo Aladelusi sọ pe itan fi idi rẹ mulẹ pe awọn alakalẹ ati ilana tawọn babanla oun fi lelẹ loun n tẹle gẹgẹ bii ọmọ Oduduwa.

Deji ilu Akure sọrọ yii nibi ayẹyẹ ọdun kẹwaa rẹ lori apeere awọn baba rẹ lopin ọsẹ to kọja niluu Akure.

''Inu mi dun lati ri baba mi Ooni Ile Ife nibi ayẹyẹ ajọdun mẹwaa ti mo gori itẹ gẹgẹ bii Deji ilu Akure.

Lai si ani ani, Ooni ni baba gbogbo iran Yoruba lonii, oun ni baba Deji Akure.

Ọmọ Ooni si ni mo jẹ laelae, nnkan ti mo jogun ba lọwọ awọn baba mi ti wọn ti jẹ Deji Akure sẹyin niyẹn,'' Deji Akure lo sọ bẹẹ.

Oba Aladelusi ṣalaye pe loootọ ni Akure tobi ju Ile Ife lọ, ṣugbọn o ni Ile Ife ni gbogbo iran Yoruba ti ṣẹ wa.

Deji Akure ni Ife ni ile ati oriran iran Yoruba, nibẹ si ni gbogbo awọn ọba to n dade nilẹ Yoruba ti ṣẹ wa.

''Gbogbo ọba ilẹ Yoruba gbọdọ maa bu ọla fun Ooni Ile Ife tori oun lo n ṣoju itẹ Oduduwa''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oba Aladetoyinbo tun dupẹ lọwọ Olowo ti ilu Iwo, Oba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta to jẹ alaga igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Ondo fun bi o ti wa nibi ayẹyẹ naa.

''Olowo wa nibi ayẹyẹ naa pẹlu baba mi, idunnu nla lo jẹ fun mi bi mo ti bawọn mejeeji lori ijokoo nigba ti mo rin wọle.

Ooni beere lọwọ mi pe ki lo de ti mi o fi wa ni ikalẹ ki awọn to de, mo si da Oniriṣa lohun pe ti kabiyesi ba tiẹ ti wa ni ijokoo fun wakati mẹta ki n to de; emi ọmọ wọn ni wọn wa yẹ si.

Nitori ọmọ Ooni ni mo jẹ, ko si bi ọmọ ṣe le dagba to, ọmọ lo si maa jẹ fun baba rẹ.

Ọmọ ni emi Deji Akure jẹ fun Ooni, Oonirisa wa lati bu ọla fun ọmọ rẹ ni,'' Deji lo sọ bẹẹ.

Ṣaaju lọdun 2016 ni Deji Akure sọ pe gbogbo awọn ọba alaye ti wọn ba le sọ pe Ile Ife lawọn ti ṣẹ wa lo le sọ pe ọmọ Oduduwa lawọn.

Oba Aladetoyinbo sọ pe idi niyii ti gbogbo eeyan fi gbọdọ maa bu ọla fun ẹnikẹni to ba wa lori itẹ Ooni Ile Ife tori oun ni baba iran Yoruba ati pe oun lo n ṣoju Oduduwa.

Deji Akure tun fikun ọrọ rẹ wi pe nitori itẹ Ooni lo n ṣoju itẹ Oduduwa, lo fi yẹ ki gbogbo ọba nilẹ Yoruba maa bu ọla fun Ooni.

Oba Aladetoyinbo ni Deji Akure lati ori awọn to ti wa lori itẹ naa lati igba iwasẹ titi di asiko toun yii ko kọ iyan Ooni Ile Ife kere rara.