''Mo kábàmọ́ọ̀ pé mo fi ọdún 35 ayé mi ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá, N1.4m ni mo rí gbà fún owó ìfẹ̀yìntì''

Aworan awọn ọlọpaa to n ṣe iwọde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn ọlọpaa to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ ṣe ifẹhonuhan niluu Abuja lonii ọjọ Aje ọjọ kọkanlelogun oṣu Keje lori nnkan ti wọn pe ni owo ifẹyinti to kere.

Kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorilẹede Naijiria lawọn ọlọpaa-fẹyinti naa ti kora wọn jọ l'Abuja lati ṣe ifẹhonuhan ọhun.

Obinrin kan to ba BBC sọrọ ṣalaye pe oun duro fun ọdun meji lẹyin toun fẹyin ti tan loun to ri N1.4m gba gẹgẹ bii owo ifẹyinti oun.

Bakan naa lobinrin ọhun to fẹyin ti lẹnu iṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii insipẹkitọ sọ pe N22,000 lowo ifẹyinti toun n gba loṣooṣu.

''Mo kabamọọ wi pe mo darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa, mo si kabamọọ wi pe mo fi ọdun marundinlogoji ọjọ aye ṣiṣẹ ọlọpaa.''

Obinrin yii to ni oun ti le lọgọta ọdun ṣalaye pe ọkọ oun ti ku, oun nikan loun si n ran awọn ọmọ awọn lọ sile ẹkọ.

O ni abikẹyin oun si wa nile ẹko giga fasiti ti ko tii pari eto ẹkọ rẹ.

''N200,000 lowo ile ti ọmọ mi n san, bawo ni mo ṣe fẹ ko N22,000 owo ifẹyinti ti mo n gba loṣooṣu jọ ti yoo fi pe N200,000?'' Obinrin naa lo beere bẹẹ.

Aworan awọn ọlọpaa to n ṣe iwọde
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ọlọpaa to ti fẹyin ti naa, Ilyasu Yahaya Aliyu, sọ fun BBC Pidgin pe N2.5m loun gba gẹgẹ bi owo ifẹyinti, N40,000 loun si n gba loṣooṣu lẹyin toun ti ṣiṣẹ ọlọpaa fun ọdun marundinlogoji.

Ilyasu ni owo yii ko le ran nkankan ninu bukata oun pẹlu bi ọwọngogo nnkan ṣe gbode ni Najiria bayii.

Lara nnkan ti ẹgbẹ awọn ọlọpaa to ti fẹyinti naa n beere lọwọ ijọba ni pe awọn ko fẹẹ maa ba ilana owo ifẹyinti ti a mọ si Contributory Pension Scheme (CPS) lọ mọ.

Adari awọn ọlọpaa to ti fẹyinti naa sọ pe awọn ọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lati ori IGP, AIG, DIG to fi de CP ko lo ilana CPS fun owo ifẹyinti wọn.

Niwaju ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lawọn ọlọpaa fẹyinti ọhun ti kọkọ ko ara wọn jọ nibi ti wọn ti sọ fawọn aṣofin wi pe ki wọn bawọn ṣe ayipada ilana sisan owo ifẹyinti awọn.

Amọ, ko si ọmọ ile aṣofin kankan to bawọn sọrọ.

Lẹyin naa ni gbajugbaja ajafẹtọọ n ni, Omoyele Sowore darapọ mọ wọn ti wọn si jọ lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja.

Kí ló ń fa ìfẹ̀hónúhàn àwọn ọlọ́pàá-fẹ̀yìntì gan ní Nàìjíríà, àti wí pé, báwo ni ìfẹ̀hónúhàn náà ṣe ń lọ?

Aworan awọn ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Owurọ oni, ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje ọdun 2025 ni awọn ọlọpaa to ti fẹyinti, pinnu lati ṣe iwọde ifẹhonuhan nipa owo ifẹyinti wọn, bẹrẹ lati olu ilu Naijiria, Abuja.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, iya awọn ifẹhonuhan alalaafia, (Mother of all peaceful protests) ni wọn pe e .

Wọn fi kun alaye naa pe kaakiri ipinlẹ Naijiria ni awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọpaa to ti feyinti yoo ti da si ifẹhonuhan ọhun.

Kí ni àwọn ọlọ́pàá-fẹ̀yìntì ń bínú fún?

Alaye ẹgbẹ awọn ọlọpaa to ti fẹyinti naa ni pe awọn ko fẹẹ maa ba ilana owo ifẹyinti ti a mọ si Contributory Pension Scheme (CPS) lọ mọ.

Wọn ni ilana owo ifẹyinti naa n role apa kan, da apa kan si.

Bakan naa ni wọn ṣalaye pe awọn fẹ ki ijọba ko owo ajẹmọnu iṣẹ awọn pada fun awọn kia.

Awọn ọlọpaa-fẹyinti naa ti iroyin sọ pe wọn ti bẹrẹ ifẹhonuhan l'Abuja, sọ pe bi ijọba ko ṣe da si ọrọ awọn ti to gẹẹ.

Yatọ si kikuro ninu ilana CPS, awọn ọlọpaa-fẹyinti naa tun n beere fun igbaye-gbadun, kuro ninu iya ti wọn ni o n koju awọn lati igba pipẹ wa.

Ki ni Contributory Pension Scheme ?

Ilana owo ifẹyinti kan ti wọn fi n ba awọn oṣiṣẹ tọju owo ti wọn yoo gba bi iṣẹ ba tan ni Contributory Pension Scheme (CPS) lorilẹede Naijiria.

Ati ẹni to gba eeyan siṣẹ ati awọn oṣiṣẹ to gba ni wọn yoo jọ maa fi abala kan owo oṣu oṣiṣẹ naa pamọ si apo ikowosi ti a mọ si Retirement Savings Account (RSA).

Ẹka to n ri si owo ifẹyinti, Pension Fund Administrator (PFA) ni yoo si maa moju to o.

Ilana yii wa fun pe ki awọn oṣiṣẹ ni gbogbo ẹka, yala ti ijọba abi ti aladaani, maa ri owo ajẹmọnu wọn gba lasiko.

Ilana ifowopamọ CPS yii jẹ dandan fun awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn aladaani naa si n lo o pẹlu, bi wọn ba ti ni oṣiṣẹ, o kere tan, mẹta.

Nipa owo ti oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ fi n pamọ ni CPS, o le jẹ ida mẹwaa lati ọdọ ẹni to gba eeyan siṣẹ, yoo si jẹ ida mẹjọ lọdọ oṣiṣẹ to gba.

Ṣaaju ifẹyinti, oṣiṣẹ le mọ iye to ti ni nipamọ, nipasẹ nọmba ifowopamọ si rẹ.

Àlàyé ọ̀ga àgbà ọlọ́pàá Naijiria pata

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi, fi sita lorukọ oga agba ọlọpaa lorilẹede yii, Kayode Egbetokun, ni wọn ti ni awọn ọbayejẹ kan lo fẹẹ sọ iwọde naa di nnkan miran.

Atẹjade naa ṣaleye pe ohun ti awọn ọlọpaa fẹyinti yii n beere fun ki I ṣe tuntun.

Wọn ni o ti le lọdun mẹwaa ti awọn oṣiṣẹ ti n beere fun iyọkuro ninu ilana CPS yii.

Ẹtọ wọn ni wọn n beere fun gẹgẹ bi Egbetokun ṣe wi, ṣugbọn awọn eeyan kan to fẹran rogbodiyan ni wọn n gbe ohun to le tabuku iṣẹ ọlọpaa jade.

''Bo tilẹ jẹ pe awọn kọọkan jẹ otitọ ninu ohun ti wọn n gbe kiri naa, awọn kan wa nibẹ ti wọn n lo lati tabuku iṣẹ ọlọpaa ati ijọba.

'' Bo ba ṣe wu ko ri, a duro lori ododo ọrọ, eyi ti i ṣe pe awọn to ti jiya fun aabo orilẹede yii ri ni wọn n beere fun ẹtọ wọn.''

Ko rọrun fun ẹka ọlọpaa lati yọ kuro ni ilana CPS yii bi atẹjade naa ṣe wi, bi ko ṣe pe ọna ti yoo gba pọ gan-an ko too di ayọ.

Awọn kan tilẹ ti ni awọn ko ni I lọwọ si iwọde naa mọ gẹgẹ bi Egbetokun ṣe wi, ṣugbọn fun awọn ti wọn ṣi fẹẹ tẹsiwaju, ileeṣẹ ọlọpaa ni aabo yoo wa fun wọn.

Bo tilẹ jẹ pe Abuja ni eto ifẹhonuhan naa yoo ti gberasọ ju, BBC News Yoruba yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ.