Ṣe lóòótọ́ ni àjọ WAEC ti fagilé ìdańwò ọdun 2025?

Aworan awọn akẹkọọ to n ṣedanwo WAEC.

Oríṣun àwòrán, WAEC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awuyewuye ti n lọ lẹnu ọjọ mẹta yii, pe ajọ to n ri si idanwo oniwe mẹwaa, West African Examination Council (WAEC), ti fagile idanwo ti awọn akẹkọọ ṣe ni 2025 yii.

Ajọ WAEC ninu alaye rẹ, sọ pe oun ri awọn atẹjade kan to n yika ori ayelujara, ninu eyi ti wọn ti ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ ti fagile idanwo naa nitori aṣemaṣe.

Bakan naa ni WAEC sọ pe awọn atẹjade naa tun mẹnuba a, pe awọn ibeere kan ti lu sita ki awọn akẹkọọ too jokoo ṣe e.

Eyi ni iroyin naa sọ pe o fa a ti WAEC fi gbe igbesẹ ifagile idanwo ti awọn akẹkọọ ṣe naa.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu Karun-un ọdun yii ni awọn akẹkọọ ṣedanwo ede oyinbo, eyi ti wọn ṣe wọ alẹ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu naa.

Ọsan lo yẹ ki wọn ṣe idanwo ọhun, ṣugbọn o yi wọ alẹ pata ti wọn n tana ṣe.

Ǹjẹ́ àwọn nńkan yìí lè mú kí wọ́n fagilé èsì ìdánwò ?

Nigba ti won n tan imọlẹ si ibeere yii, ajọ WAEC ni oun ko fagile esi idanwo ọdun 2025.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ajọ naa loun ko mọ nnkan kan nipa atẹjade kan to jade lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje yii, eyi to kede pe WAEC fagile idanwo nitori magomago to waye.

Ọga agba lẹka ikede ni WAEC, Moyosola Adesina, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe atẹjade to kede fifagile idanwo naa ko wa lati ọdọ WAEC.

"A ko fagile idanwo 2025, bo tilẹ jẹ pe a ko mọ awọn to wa nidii iroyin naa.

"Wọn n gbe ahesọ kiri lati ba WAEC lorukọ jẹ ni."

Wọn fi kun un pe awọn to n gbe e kiri wulẹ fẹẹ ṣi awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa lọna ni.

Ìgbà wo ni WAEC yóò fi èsì ìdánwò oníwèé mẹ́wàá 2025 síta?

Bi WAEC ṣe ṣalaye, wọn ti bẹrẹ si i maaki awọn idanwo naa, wọn si ti pari rẹ.

Oṣu Kẹjọ ọdun 2025 ni ajọ WAEC loun yoo fi esi idanwo naa sita.

"Ko too to ọjọ Aje, ọjọ kerin oṣu Kẹjọ ọdun 2025, esi maa jade."

Bẹẹ ni agbẹnusọ WAEC wi.

Awọn eeyan to n sọ awọn akẹkọọ ninu idanwo ni wọn maa n maaki idanwo WAEC. O si jẹ awọn to mọ nipa ẹkọ ni yara ikawe daadaa.

WAEC yoo gbe igbimọ ti yoo fi ilana mimaaki silẹ, wọn yoo si fun awọn alayẹwo naa ni ilana ti wọn yoo gba maaki awọn idanwo yii.

Ilana yii ni wọn lo fun ti ọdun 2025 naa.

Ajọ naa gba ẹbi rẹ fun pipẹ ti wọn pẹ, ti awọn akẹkọọ fi ṣedanwo wọ alẹ ni 2025 yii.

Wọn sọ nigba naa pe awọn kudiẹ-kudiẹ kan lo koju awọn.

Awọn iwa ti WAEC ka si magomago ninu idanwo

*Ki akẹkọọ gbe iwe wọle lati ji wo.

*Ki akẹkọọ rin oluyẹwo idanwo fin.

*Ki akẹkọọ ṣe paṣipaarọ iwe ninu idanwo.

*Ki akẹkọọ ba ẹlomiran jokoo ṣedanwo.

*Ki akẹkọọ parapọ ji iwe wo ninu idanwo.

* Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn wo ni àjọ WAEC?

Ọdun 1952 ni wọn da ajọ WAEC silẹ.

Ọdọọdun ni idanwo oniwee mẹwaa maa n waye fun awọn akẹkọọ to wa ni ipele naa.

Awọn orilẹede to maa n ṣedanwo WAEC ni Gambia, Ghana, Liberia, Nigeria ati Sierra Leone.

WAEC jẹ ẹka idanwo ti ofin da mọ ni Iwọ-Oorun Africa.

Iṣẹ wọn ni lati ṣeto idanwo, ki wọn si fun akẹkọọ ni iwe ẹri to yẹ.