Àwọn èèyàn máa ń sọ pé mo jọ bàbá mi, jíjọ tí mo jọ bàbá mi sì ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà fún mi – Olamide, ọmọ Alao Akala

Àkọlé fídíò, "Ọpọlọpọ anfani ni mo ti jẹ nitori mo jọ baba mi"
Àwọn èèyàn máa ń sọ pé mo jọ bàbá mi, jíjọ tí mo jọ bàbá mi sì ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà fún mi – Olamide, ọmọ Alao Akala

Ọlamide Alao-Akala ti o jẹ ọkan lara awọn ọmọ Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ti sọrọ nipa awọn ọkanojọkan anfani ti o n jẹ nitori pe o jọ baba rẹ bi imumu.

Ninu ọrọ ti o ba BBC News Yoruba sọ, Ọlamide ni lati kekere ni awọn eeyan ti maa n sọ wi pe oun jọ Ọtunba Alao-Akala, ṣugbọn oun ko gbagbọ titi di asiko ti baba oun jade laye.

Arabinrin naa, to n ṣiṣẹ ọgbin niluu Ogbomọṣọ, ṣe alaye siwaju sii pe awọn ọfiisi ijọba kan wa ti oun n wọ ni irọrun bayii nitori pe lati okere ni awọn eeyan ti maa n da oun mọ wi pe ọmọ Akala lo n bọ yii.

Bakan naa lo ṣe alaye bi oun ṣe bẹrẹ iṣẹ ọgbin nipasẹ ileeṣẹ ohun ọgbin ti Oloogbe Alao-Akala da silẹ niluu Ogbomọṣọ ko ti di pe oun naa wa bẹrẹ ileeṣẹ tiẹ l'ọdun 2020.