Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ n'Ibadan kéde Rashidi Ladoja bíi Olubadan Kẹrìnlélógójì

Ọba Rashidi Ladoja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kéde ṣáájú ní òwúrọ̀ òní, awọn Agba Oye ilẹ Ibadan, tí wọn tún jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olubadan, ṣe àkànṣe ìpàdé l'aafin Olubadan to n bẹ ni Oke-Arẹmọ l'owurọ oni.

Níbi ìpàdé náà ni igbimọ Olubadan ti kede Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Ọba Senatọ Raṣidi Adewọlu Ladọja gẹgẹ bii Olubadan ikẹrinlelogoji.

Balogun Olubadan, Ọba Tajudeen Ajibola, lo kọkọ darukọ Ọba Ladọja gẹgẹ bii ẹni ti oye Olubadan kan, ko to di pe Ọba Eddy Oyewole kin ọrọ Balogun lẹyin.

Ìrètí wà pé Ọba Rashidi Ladoja yóò gúnlẹ̀ sí Ibadan ní òpin ọ̀sẹ̀ fún ètò ìsìnkú Ọba Olakuleyin àti ìpalẹ̀mọ́ ìwúyè tí yóò tẹ̀le

Igbesẹ ti o kan bayii naa ni ki igbimọ Olubadan fi orukọ Ọba tuntun ṣọwọ si Gomina Ṣeyi Makinde ki akanṣe eto ifinijoye ati gbigba ọpa aṣẹ to bẹrẹ ni pẹrẹu.

Igbesẹ yii waye lẹyin ọjọ kọkanlelogun ti gbogbo ilẹ Ibadan ti n kẹdun ipapoda Olubadan ana, Oba Owolabi Olakulehin to re iwalẹ aṣa lọjọ keje oṣu keje ọdun yii.

Lati igba ti Ọba Ọlakulẹhin si ti waja ni Ọba Ladọja ti oye naa kan, ti n gba ọkanojọkan alejo ni ile rẹ to n bẹ niluu Eko.

Ireti wa wi pe Ọba tuntun yoo gunlẹ si ilẹ Ibadan l'opin ọsẹ yii.

Bakan naa ni Olubadan ana, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin yoo wọ ka ilẹ sun lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun yii lẹyin eto isinku ti yoo waye nile ijọsin 'Saint Peter's Cathedral,' to n bẹ ni Aremo, Ibadan.

Aworan aafin Olubadan ati opa asẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgbìmọ̀ Olubadan yóò jíròrò lórí ẹni tó kàn gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣáájú la tí mú ìròyìn wá fún yín pé oni ni ireti wa pe, igbimọ Olubadan ilẹ Ibadan yoo jiroro lori iyansipo Olubadan ikẹrinlelogoji.

Ipade naa ni yoo waye ni Aafin Olubadan, to wa ni agbegbe Oke Aremo niluu Ibadan.

Ọsẹ to kọja ni igbimọ ọhun ti fi iwe ransẹ si awọn ọmọ igbimọ naa, lati kede fun araalu pe ipo Olubadan ti sofo, ti wọn yoo si kede ẹni ti yoo gba ipo naa gẹgẹ bii aṣa ilẹ Ibadan.

Atẹjade ti Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibola fi ranṣẹ si awọn akọroyin tọka rẹ wi pe, aago mọkanla owurọ ni ipade naa yoo waye.

Ipade yii n waye lẹyin ti wọn ti fi ọjọ mọkanlelogun daro ipapoda Olubadan to waja, Ọba Owolabi Olakulehin.

Gbogbo awọn Oloye Agba nilẹ Ibadan ni ireti wa wi pe yoo o kopa nibi ipade naa.

Bakan naa si lo ṣeeṣe ki Olubadan tuntun, Ọba Rashidi Adewolu Ladọja naa kopa nibi ipade naa, bo tilẹ jẹ wi pe opin ọsẹ yii ni iroyin mii tọka rẹ wi pe Ọba Ladọja yoo pada si ilẹ Ibadan.

Lati igba ti Olubadan ana ti waja ni ẹni ti oye naa kan, Ọba Ladọja ti n gba oriṣiriṣi alejo ni ile rẹ to n bẹ niluu Eko, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n fi tilu-t'orin ṣe abẹwo si ile rẹ to n bẹ niluu Ibadan naa.

Ọjọ keje oṣu Keje ọdun 2025 ni wọn kede ipapoda Olubadan ana, saaju ọjọ naa si ni gbogbo eeyan ilu ti mọ wi pe Ọba Raṣhidi Ladọja ni oye naa kan nitori ilana bi wọn ṣe n jẹ oye Olubadan ko ruju rara.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ si ni eto isinku Ọba Olakulẹhin yoo waye nile ijọsin Saint Peter's Cathedral, to n bẹ ni Aremo, Ibadan.

Ifakalẹ ni yoo waye lati ọwọ igbimọ afọbajẹ ki wọn to fi orukọ ọhun ransẹ si ẹka ijọba to n risi ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Oyo.

Ladoja yoo di Olubadan ti ilẹ Ibadan kẹrinlelogoji, lẹyin ibuwọlu Gomina Seyi Makinde.

Aworan Aafin Olubadan tuntun

Oríṣun àwòrán, Others

Wo àwọn àkàsọ̀ tí ẹni tí yòó jẹ́ Olubadan yóò gùn kó tó dé ipò

Ilana yiyan Olubadan ilẹ̀ Ibadan ko ruju rara, bẹẹ ni kii fa ariwo.

Koda, ẹni ti yoo jẹ Olubadan ni aimọye ọdun si asiko yii ti mọ ara rẹ lai jẹ pe akoko ti to.

Mogaji agboole ni awọn to wa lori ila jijẹ Olubadan ti ma n bẹrẹ si ni to.

Lẹyin naa ni yoo bẹrẹ si ni sun gẹgẹ bi ilana ọba jijẹ ni Ibadan titi de ipo Jagun Balogun – Ajia – Bada – Aare Onibon – Gbonnka – Aare Egbe Omo-Oota – Lagunna – Aare Ago – Ayingun – Asaju – Ikolaba – Aare Alasa – Agba Akin – Ekefa – Maye – Abese – Ekaarun Balogun – Ekeerin Balogun – Ashipa Balogun – Osi Balogun – Otun Balogun, Balogun, ko to wa di Olubadan ti ilẹ Ibadan.