Èṣù ló ń dari awa olorin, torí ẹ̀ la ṣe máa ń mu nǹkan-9ice

9ice

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oju lasan ko ṣee ṣe were. Bẹẹ lo jọ pe Alexander Abolore Akande Adegbola tawọn eeyan mọ si 9ice lagbo orin taka-sufee n ṣalaye, nigba to ni Eṣu ni ọga agba to n dari awọn olorin.

Lori eto kan, 'Nancy Isime Show' ni 9ice ti ṣalaye laipẹ yii, pe bi Oluwa ṣe n dari aye ni Esu naa n dari orin.

O ni eyi lo fa a tawọn olorin fi maa n mu nnkan, ṣe oriṣiiriṣii nnkan bẹẹ ki wọn too maa kọrin.

Abolore ti awọn eeyan tun mọ si Ọmọ iya agba, sọ pe ẹni to ba fẹẹ wọle orin gbọdọ mọ ibi to fẹẹ wọ.

O ni nitori Esu ni alakooso orin, oun si ni angẹẹli to lagbara ju.

'Èmi kì í ṣe Musulumi, mi ò kí ń ṣe Kristẹni, Babaláwo ni mi'

9ice

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, 9ice sọ pe oun ko gbagbọ ninu ẹsin Islam ati ti Kristẹni.

"Emi o ki n ṣe Kristẹni, mi o dẹ ki n ṣe Musulumi, Babalawo ni mi'.

"Mo maa n sọ fawọn eeyan, wọn dẹ maa n sa fun mi. "Ọlọrun ti sọ fun wa ninu ọrọ rẹ pe oun ko ni i waa ba wa pẹlu ede miran to yatọ si ede wa.

"Mo ti wadii ọna mi, mo si ti n tọ ọ. Ọna kan ṣoṣo kọ lo mu ìyè wa, ka ṣaa ti debẹ pẹlu otitọ ni."

'Mo pọ ẹ̀jẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, nígbà náà ni mo gba Ifá'

Nigba to n dahun ibeere nipa pe ṣe o ti koju aye ri nidi iṣẹ orin to gbe dani, 9ice sọ pe:

''Laaarin 2009 si 2010 ni, mo bẹrẹ si i pọ ẹjẹ. Mo si pọ ẹjẹ naa fun oṣu mẹfa.

''Mo ni lati kuro nile mi nigba to ya ni.

''Ẹnikan lo waa sọ fun mi pe ki n lọọ gba Ifa, asiko yẹn ni mo gba Ifa.

''O wu mi ki n ti mọ Ifa tẹlẹ gan-an.''

O ni nigba ti Oloogbe Fela Anikulapo n ṣalaye nipa Ogun, to n bọ ọ, awọn eeyan fi n ṣe yẹyẹ, ṣugbọn ni bayii, o ye oun yeke.

9ice rọ awọn ọmọ ilẹ Africa lati ma ṣe gbagbe orisun wọn. O ni ilẹ Adulawọ naa ni awọn iranṣẹ ti Eledumare ran si wọn.

Ọwọ wọn lo ku si lati gba wọn bi ojiṣẹ.

Ta a ni 9ice?

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 1980 ni wọn bi Akande Abolore Adegbola, awọn mi-in si maa n pe e ni Ajifolajifaola.

Orukọ to sọ ọ di gbajumọ ni 9ice ti ọpọ eeyan mọ ọn si.

Bo si tilẹ jẹ pe ilu Ogbomoso, nipinlẹ Oyo ni wọn ti bi i, agbegbe Somolu/Bariga nipinlẹ Eko lo ti ṣe igba ewe rẹ.

Idile oniyawo marun-un ni 9ice ti wa, ọmọ mẹsan-an lo si wa lati idile naa.

Olorin ni 9ice, orin taka sufee to maa n sabaa fi ede Yoruba kọ lawọn eeyan mọ ọn fun.

O tilẹ figba kan sọ ọ ri pe Fuji loun fẹẹ maa kọ tẹlẹ, nigba ti wọn fi aye han oun loun yi i pada si taka-sufee.

Ọdun 1996 lo kọ orin "Risi de Alagbaja." 2000 lo gbe eyi to pe ni "Little Money" jade.

2008 ni 9ice gbe "Gọngọ a sọ" to fun un lokiki pupọ jade. Ọdun naa ni wọn si fun un lanfaani lati kọrin nibi ayẹyẹ ọjọọbi ọọdunrun ọdun (90 years) ajijagbara nni; Nelson Mandela.

Ami ẹyẹ mẹrin lo gba ni 2009 nitori orin Gọngọ a sọ naa.

9ice niyawo, o si ti bimọ.