Njẹ́ ẹ ti ri DJ tí kò ní ọ́wọ́ rí? Ẹ wo Deejay Bankyroy tó ń ṣe iṣẹ́ DJ láì ní ọwọ́ méjèéjì

Ọdọmọkunrin, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Bankole Ridwan Ishola, ẹni ti ọpọ mọ si Deejay Bankyroy lo padanu ọwọ rẹ mejeeji lẹyin ti ina mọnamọna gbe nibi to ti n ṣe iṣẹ POS rẹ.
O lo oṣu mẹfa lori ibusun ile iwosan, ti wọn si pada ge ọwọ rẹ mejeeji.
Nigba to n ṣalaye fun BBC News Pidgin ninu ifọrọwanilẹnuwo, o ni iṣẹlẹ naa waye ni owurọ ọjọ kan ninu oṣu Kẹsan an ọdun 2023.
"Nibi ti mo ti n to igba lati bẹrẹ iṣẹ lọjọ naa ni aburada ti mo n lo gba ina, ti ina ọhun si gbe mijunu, ti mo si laju si ile iwosan.
"Ọmọ obinrin to n ba mi sisẹ ko ta aburada ti a n lo daada, mo wa ni ki n tun ṣe, n ko mọ pe ina mọnamọna ti wa lara aburada naa, bi ina ṣe gbe mi niyẹn.
Deejay Bankyroy ni, oṣu mẹfa ni oun lo ni ile iwosan, to si jẹ pẹlu inira ni oun fi wa nibẹ.
O pinnu pe ki awọn dokita ge ọwọ naa ṣugbọn awọn obi rẹ yari lai mọ pe, ẹran nikan lo wa nibẹ, ko si egungun mọ. O ni wọn gbiyanju pe ki oun si ma lo ọwọ naa ṣugbọn inira naa pọ titi wọn fi ge.
Bankyrov ni ọpọ nnkan ni oun n lakọja lojojumọ lai si apa rẹ - lati fọ eyin, wọ asọ, jẹun- O ni oun lo ọrọ odi ti wọn sọ si oun lori ayelujara lati pinnu pe iṣẹ DJ ni oun fẹ ṣe.
O tẹsiwaju pe igboya lati duro niwaju ọpọ eeyan ko kọkọ si fun oun ṣugbọn oun pada ṣawari rẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ ni amulumọla ni oun n ṣe, oun ko kọ bi ara si wọn, ti wọn si ṣe ohun to tọ lati mọ si nipa iṣẹ naa.
"N ko kọ iṣẹ DJ lati ibẹrẹ aye mi, POS ni mo n ṣe. Nigba ti mo bẹrẹ, awọn eeyan ni mo kan n po orin pọ ni.
"Ọpọ lo ma n sọ pe bawo ni ẹni ti ko ni apa ṣe ma ṣere fun wa?
Ibanujẹ ni eyi ma n jẹ nigbakugba ti wọn ba sọ fun mi pe mo kan po orin pọ lasan ni. Eyi is lo mu mi pinnu lati maa gbe orin mi si ori ayelujara."
Deejay Bankyroy ni oun si ni igbagbọ pe oun yoo ni ileeṣẹ orin ti t'oun, to si gbagbọ pe Ọlọrun ko ni fi oun silẹ.
"Nigba ti mo ni ọwọ, Ọlọrun lo n sọ mi, nigba ti ko si ọwọ mọ, Ọlọrun si n ma sọ mi lọ. N ko le ma ni ọwọ ki iya ma jẹ. Ọlọrun yoo lanaa, mo wa ni alaafia.
"N ko ni tọrọjẹ bi awọn yooku ti wọn ko ni apa, iyẹn ko si lọkan mi rara, mo gbagbọ pe Ọlọrun yoo lana fun mi," o ṣalaye.















