'Àsìkò tó yẹ kí n máa jèrè wàhálà mi lórí ọmọ mi ni wọ́n pá níbi iṣẹ́'
Mọ̀lẹ́bí olóògbé Abiola Omitusin, òṣìṣẹ́ Amotekun nípìnlẹ̀ Osun tí ìròyìn sọ pé afurasí sọ́jà kan pa, ti bẹ ìjọba fún ìdájọ́ òdodo.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025 ni agbẹnusọ ẹ̀ṣọ́ Amotekun ìpínlẹ̀ Osun, Yusuf Idowu Abass, sọ nínú àtẹ̀jáde pé, ní agbègbè Ijeda ní ìlú Ijesa, ìpínlẹ̀ Osun ni ìkọlù náà ti wáyé.
Ọgbẹni Abass nínú àtẹ̀jáde náà fẹ̀sùn kan pé òṣìṣẹ́ ológun kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Opejobi Fiyinfoluwa, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ ológun ló ṣe ìkọlù sí Abiola ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ó ṣàlàyé pé afurasí ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ, wọ aṣọ ológun tó sì ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ Amotekun tó wà ní Ijebu-Jesa.
'Diẹ lo ku ki n gbe oogun pako-pako jẹ'

Ìyá olóògbé, Arábìnrin Toyin Omitusin, sọ fún BBC pé, láti ìgbà tí ọkọ òun ti kú lọ́dún 2019, ni Abiola ti n ṣe ọkọ fún òun.
"Ní ọjọ́ tí wọ́n pa á, mo retí rẹ̀ títí, mo pé fóònù rẹ̀ kò lọ, mó fi iná tọ́ọ̀ṣì rìn kiri gbogbo ìlú, kí àbúrò rẹ̀ tó mú ìròyìn tọ̀ mí wá ní nnkan bí aago méjì òrú, pé wọ́n kọlùú."
Ìyá nàá sọ pé ọmọ òun ma n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun pẹ̀lú iṣẹ́ oko, tó sì n tiraka láti jéèyàn.
Bákan nàá ni ọkọ àbúrò olóògbé. Arákùnrin Peter Joseph, sọ pé ìkọlù ni ikú rẹ̀ jẹ́ nítorí pé kìí ṣe pé ó múra ìjà lọ síbí tí wọ́n ti pa á.
Bawo gan-an ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?
Iléèṣẹ́ Amotekun ìpínlẹ̀ Osun fẹ̀sùn kàn pé Fiyinfoluwa sọ pé lára ìdí tí òun fi lọ darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ológun ni láti máa fi ìyà jẹ àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ Amotekun.
Omoyele nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé kò pẹ́ sígbà náà ni Fiyinfoluwa àtàwọn kan pàdé ẹ̀ṣọ́ Amotekun Tope lójú ọ̀nà tó ń gun ọ̀kadà lọ tí wọ́n sì da dúró.
"Wọ́n ṣe ìkọlù si.
Ohun tí a gbọ́ ni pé wọ́n la nǹkan mọ́ Tope lórí èyí tó jẹ́ kó ṣubú lulẹ̀ láti orí ọ̀kadà tó gùn.
Nǹkan bíi ogún ìṣẹ́jú ni ìkọlù náà fi wáyé láì sí ìrànlọ́wọ́ kankan, èyí tó mú kí Tope wà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀."
Bákan náà ló fi kun pé, ní kété tí òṣìṣẹ́ ológun wu ìwà láabi náà tán ni wọ́n na pápá bora pẹ̀lú ọ̀kadà.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé lẹ́yìn táwọn òṣìṣẹ́ Amotekun gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n sáré gbé Tope lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Bákan náà ló tún ní wọ́n lọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Ijebu-Jesa létí àti pé àwọn sọ fún ọ̀gágun Yunusa Isyaku tó wà ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun tó wà ní ìlú Ede nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀gá Àgbà Amotekun, Isaac Omoyele ní, gbogbo ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí Peter Tope ló já sí pàbó bí ó ṣe dágbére fáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Bákan nàá ló sọ pe iroyin ibanujẹ ni iku Abiola jẹ "nitori pe, oṣiṣẹ takuntakun ni.
Bakan naa lo ṣalaye pe gbogbo igbiyanju ajọ Amotekun ati ileeṣẹ ọlọpaa lati mu afurasi naa ti wọn lo jẹ ọmọ ogun Naijiria, ni ko ti i so eso rere.



