'Ara igi ni mo sá sí láti móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn lẹ́yìn tí ọta ìbọn mi tán'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abubakar Maccido
- Role, Reporter
- Reporting from, Kano
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn agbébọn kan lọ ṣe ìkọlù sáwọn ológun àtàwọn fijilanté ni agbègbè Dogon Ruwa lẹ́kùn Bashar ní ìjọba ìbílẹ̀ Wase ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Àwọn ológun méjì àti fijilanté méjì ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà.
Bákan náà ni àwọn agbébọn kan tún jáde láyé níbi ìkọlù náà.
Níṣe ni àwọn èèyàn tó ń gbé ní agbègbè náà wà ní inú fu àyà fu pé ìkọlù míì tún lè wáyé ní agbègbè náà.
Èèyàn kan láti ìlú náà sọ pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ni, àwọn ológun tí wọ́n gbọ́ ìròyìn pé àwọn agbébọn kan ti yawọ agbègbè náà, wọ ìlú náà láti wá kojú àwọn agbébọn náà.
'Àwọn agbébọn pa fijilanté méjì, ológun méjì, bọ́ aṣọ wọn lọ, jó ọ̀kadà wa mẹ́ta níná'
Ọ̀kan lára àwọn fijilanté tó móríbọ́ níbi ìkọlù náà, Dauda Sallamu sọ fún BBC News Pidgin bí ìkọlù náà ṣe wáyé.
Ó sọ pé nǹkan bíi aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìkọlù náà wáyé.
Sallamu ní àwọn agbébọn tí wọ́n dẹ dẹ̀dẹ̀ fún àwọn ológun náà jẹ́ mọ́kànlélógún níye, tó sì jẹ́ pé àwọn ológun tó fẹ́ lọ kojú wọn kò ju mọ́kànlá lọ.
"A gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ṣe àwárí àwọn agbébọn kan ní agbègbè náà ní òwúrọ̀.
"Èyí ló mú wa kó àwọn fijilanté méje àti àwọn sójà mẹ́rin láti lọ kojú àwọn agbébọn náà.
"Àwa ò mọ̀ pé àwọn agbébọn ọ̀hún ti sápamọ́ sínú igbó fún wa, bí wọ́n ṣe ri wá ni wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, tí wọ́n sì pa fijilanté méjì àtàwọn ológun méjì."
Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn náà ni wọ́n dáná sun ọ̀kadà àwọn mẹ́ta, tí wọ́n sì bọ́ aṣọ àwọn ológun tí wọ́n pa náà.
"Lẹ́yìn tí wọ́n pa àwọn ológun náà, wọ́n bọ́ aṣọ wọn, jó ọ̀kadà wa mẹ́ta níná. Orí ló kó mi yọ nítorí ara igi kan ni mo sápamọ́ nígbà tí ọta ìbọn mi tán," Sallamu sọ.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí àwọn rí àwọn ológun míì kúnra ni àwọn padà síbi tí ìkọlù náà ti wáyé láti lọ gbé òkú àwọn akẹgbẹ́ wọn ni àwọn ri pé àwọn ti pa mẹ́fà nínú àwọn agbébọn náà.
"Nígbà tí a padà débẹ̀ ni a ri pé mẹ́fà nínú àwọn agbébọn náà ló kú àmọ́ wọ́n tib a gbogbo ojú wọn jẹ́ nítorí wọn kò fẹ́ kí a dá ojú wọn mọ̀."
'Ìkọlù àwọn agbébọn ní gbogbo ìgbà ti sú wa, à ń fẹ́ ojútùú sí ìṣòro yìí'
Olórí agbègbè kan níbẹ̀, Abdullahi Yakubu náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC News Pidgin, bó ṣe sọ pé inú ìbẹ̀rù ni àwọn èèyàn ń gbé ní agbègbè náà báyìí.
"A gbọ́ pé àwọn agbébọn fẹ́ ṣe ìkọlù sí Dogon Ruwa ló jẹ́ káwọn ológun àti fijilanté tètè sáré lọ kojú wọn.
"Ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ pé àwọn agbébọn náà ti lọ lúgọ dè wọ́n nínú igbó, tí wọ́n sì pa ológun méjì àti fijilanté méjì."
Yakubu ní ìkọlù ọ̀hún ti ń mú kí àwọn èèyàn máa gbé nínú ìbẹ̀rù.
"Bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ìkọlù náà ti dá ìfòyà sílẹ̀ fáwọn aráàlú àmọ́ wọ́n ti kó àwọn ológun wá sit í nǹkan sì ti ń padà sípò."
Bákan náà ló tún rọ ìjọba láti wá ọ̀nà bí àlááfíà yóò ṣe tún jọba ní agbègbè náà, tí kò ní máa sí ìkọlù àwọn agbébọn mọ́ rárá.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, agbẹnusọ ikọ̀ ológun Operation Safe Haven, Ọ̀gágun Samson Zhakom kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ tí akọ̀ròyìn wa fi ránṣẹ́ si lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn ìlú ní ìjọba ìbílẹ̀ Wase àtàwọn ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn ní ìpínlẹ̀ Plateau ló ń kojú ìkọlù láti ọwọ́ àwọn agbébọn èyí tó ti mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ.











